A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
Orí 34
A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
1. (a) Kí ló ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn, kí sì nìdí? (b) Kí ló ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀?
KÍ LÓ ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Tóò, ní títajúkán rí i, kàyéfì ńlá ṣe mí.” (Ìṣípayá 17:6b) Ẹ̀dá èèyàn ò lè dá ronú kan irú ohun abàmì bẹ́ẹ̀ rárá. Síbẹ̀, ohun abàmì yìí ṣẹlẹ̀ nínú aginjù lọ́hùn-ún. Aṣẹ́wó oníwàkiwà kan ń gun abàmì ẹranko ẹhànnà kan tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò! (Ìṣípayá 17:3) Kàyéfì ńlá ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní pẹ̀lú bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀. Ká ní àwọn èèyàn ayé lè rí i ni, wọn ì bá kígbe pé, ‘Èèmọ̀ rè é!,’ àwọn olùṣàkóso ayé ì bá sì sọ pé, ‘Áà, kí rèé!’ Ṣùgbọ́n ìran tó ṣeni ní kàyéfì yìí ń nímùúṣẹ lóòótọ́ lákòókò wa yìí. Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti kópa tó pọ̀ nínú ìmúṣẹ ìran náà, èyí sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ ìran náà yóò ní ìmúṣẹ rẹ̀ yíyanilẹ́nu tó kẹ́yìn.
2. (a) Nígbà tí áńgẹ́lì náà kíyè sí bí ẹnu ṣe ya Jòhánù, kí ló sọ fún Jòhánù? (b) Kí ni Ọlọ́run ti ṣí payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù, báwo ló sì ṣe ṣí i payá?
2 Áńgẹ́lì náà kíyè sí i pé ìyàlẹ́nu ni ìran náà jẹ́ fún Jòhánù. Ohun tí Jòhánù sì wí pé áńgẹ́lì náà sọ nìyí: “Nítorí náà, áńgẹ́lì náà wí fún mi pé: ‘Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe kàyéfì? Ó dájú pé èmi yóò sọ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ àti ti ẹranko ẹhànnà tí ń gbé e, tí ó sì ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.’” (Ìṣípayá 17:7) Ní báyìí, áńgẹ́lì náà yóò sọ ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ náà! Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé ohun tí onírúurú nǹkan tó wà nínú ìran náà túmọ̀ sí, ó sì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó máa tó ṣẹlẹ̀ fún Jòhánù tí ìyàlẹ́nu ti bá. Bákan náà, lóde òní Ọlọ́run ti ṣí ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù tó wà lójúfò bí ẹgbẹ́ náà ṣe ń sìn lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì. Jósẹ́fù olóòótọ́ béèrè pé, “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” Bíi ti Jósẹ́fù, a gbà pé ti Ọlọ́run ni ìtumọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 40:8; fi wé Dáníẹ́lì 2:29, 30.) Ńṣe ló dà bíi pé àwa èèyàn Ọlọ́run wà ní àárín méjì orí ìtàgé kan bí Jèhófà ṣe ń sọ ìtumọ̀ ìran náà àti ipa tó yẹ kó ní lórí ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 25:14) Ní àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́, ó jẹ́ ká rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà àti ẹranko ẹhànnà náà.—Sáàmù 32:8.
3, 4. (a) Àsọyé fún gbogbo ènìyàn wo ni N. H. Knorr sọ ní 1942, kí ló sì sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jẹ́? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù, èyí tí N. H. Knorr sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
3 Lákòókò tí Ogun Àgbáyé Kejì gbóná janjan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n pè ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, ní September 18 sí 20, 1942. Ìlú Cleveland ni wọ́n ti ṣe àpéjọ àgbègbè náà, wọ́n wá fi tẹlifóònù gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà sáfẹ́fẹ́ láwọn ìlú mìíràn tó lé ní àádọ́ta, tó fi jẹ́ pé iye àwọn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádóje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín kan [129,699]. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àpéjọ yìí jákèjádò ayé láwọn ibi tó ti ṣeé ṣe lákòókò ogun náà. Lákòókò yẹn, èrò ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà ni pé ńṣe ni ogun náà yóò máa le sí í títí tí yóò fi yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?,” ńṣe ni wọ́n ń hára gàgà láti gbọ́ àlàyé tó máa wáyé. Báwo ni ààrẹ tuntun fún Watch Tower Society, N. H. Knorr ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà nígbà tó jẹ́ pé òdìkejì rẹ̀ ló dà bíi pé àwọn orílẹ̀-èdè máa rí? a Ìdí ni pé ẹgbẹ́ Jòhánù ń “fún” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—Hébérù 2:1; 2 Pétérù 1:19.
4 Báwo ni àsọyé náà “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?” ṣe ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà? Nínú àsọyé náà, N. H. Knorr fi hàn kedere pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó wà nínú Ìṣípayá 17:3. Lẹ́yìn náà, ó wá sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ò ṣe ní fararọ fún un, ó sì gbé ìyẹn ka ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì sọ fún Jòhánù, pé: “Ẹranko ẹhànnà tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò sì kọjá lọ sínú ìparun.”—Ìṣípayá 17:8a.
5. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀” àti lẹ́yìn náà tí “kò sí”? (b) Báwo ní N. H. Knorr ṣe dáhùn ìbéèrè náà, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?”
5 “Ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti wà tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti January 10, 1920. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] ló wà nínú ìmùlẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n, níkọ̀ọ̀kan, Japan, Jámánì, àti Ítálì yọwọ́yọsẹ̀, nígbà tó yá, wọ́n yọ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí kúrò nínú Ìmùlẹ̀ náà. Ní September 1939, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó jẹ́ olórí Ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì bẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì. b Nígbà tí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti kùnà láti mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé, ó rì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, kò lè ṣe nǹkan kan mọ́. Nígbà tó fi máa di 1942, ó ti dohun ìtàn. Àkókò oníyánpọnyánrin yẹn gan-an ni Jèhófà túmọ̀ ìran náà fáwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kò túmọ̀ rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn tàbí lẹ́yìn náà! Ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, N. H. Knorr polongo pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . kò sí” bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ. Lẹ́yìn náà ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?” Ó wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìṣípayá 17:8, ó sì dáhùn pé: “Àjọ àpapọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè náà yóò tún fara hàn.” Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn, èyí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kì í kùnà!
Bó Ṣe Jáde Látinú Ọ̀gbun Àìnísàlẹ̀
6. (a) Ìgbà wo ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, orúkọ tuntun wo sì ni wọ́n fún un? (b) Kí nìdí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jẹ́ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí?
6 Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ lóòótọ́. Ní June 26, 1945, afẹfẹyẹ̀yẹ̀ aláriwo ni àádọ́ta [50] orílẹ̀-èdè fi kéde ìbẹ̀rẹ̀ ìdìbò tí wọ́n fi fọwọ́ sí Ìwé Ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní San Francisco, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ní ojúṣe àjọ náà ni “láti rí i pé mìmì kan ò mi àlàáfíà àti ààbò àgbáyé.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Láwọn ọ̀nà kan, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní . . . Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n para pọ̀ dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ náà ló para pọ̀ dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìdí tí wọ́n fi dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ ni kó lè máa rí i pé àlàáfíà wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn ẹ̀ka pàtàkì-pàtàkì tí ń bẹ nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Nítorí náà, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nínú àjọ yìí jẹ́ nǹkan bí igba ó dín mẹ́wàá [190], èyí tó pọ̀ fíìfíì ju orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] tó wà nínú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè; yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó máa ṣe pọ̀ ju ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ.
7. (a) Ọ̀nà wo làwọn olùgbé ilẹ̀ ayé fi ṣe kàyéfì tí wọ́n sì kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí náà? (b) Kí ló jẹ́ àléèbá fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí sì ni akọ̀wé àgbà àjọ yẹn tẹ́lẹ̀ rí sọ nípa èyí?
7 Nígbà tí wọ́n dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àwọn èèyàn sọ nǹkan ńláńlá tí wọ́n nírètí pé á gbé ṣe. Èyí mú ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ ṣẹ, pé: “Nígbà tí wọ́n bá sì rí bí ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tí yóò tún wà, àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe kàyéfì lọ́nà ìkansáárá, ṣùgbọ́n a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:8b) Àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kan sáárá sí àjọ ńlá tuntun yìí, tí wọ́n fi ilé gàgàrà gagara kan ṣe oríléeṣẹ́ rẹ̀ ní East River ní New York. Ṣùgbọ́n ohun àléèbá ni ojúlówó àlàáfíà àti ààbò jẹ́ fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè o. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ní ọ̀rúndún ogún, ìlànà ‘tó o bá ló o fẹ́ pa mí run, àá jọ para wa run ni’ [“mutual assured destruction” tí ìkékúrú rẹ̀ jẹ́ MAD] làwọn orílẹ̀-èdè alágbára fi ń halẹ̀ mọ́ ara wọn kí àlàáfíà lè wà láyé. Ìlànà MAD yìí ni pé bí orílẹ̀-èdè alágbára kan bá yin ohun ìjà runlé-rùnnà sí orílẹ̀-èdè kan, kí ó mọ̀ dájú pé àwọn ọ̀tà máa yin irú ẹ̀ padà sórílẹ̀-èdè tòun. Abájọ tí ṣíṣe ohun ìjà ogun fi ń pọ̀ sí i. Ní 1985, ìyẹn lẹ́yìn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] ọdún tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti ń gbìyànjú pé kí àlàáfíà wà láyé, Javier Pérez de Cuéllar tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ náà nígbà yẹn, dárò pé: “Àkókò tá a wà yìí jẹ́ sànmánì àwọn oníwà ẹhànnà bíi tàwọn ìgbà kan, a ò sì mọ nǹkan tá a lè ṣe sí i.”
8, 9. (a) Kí nìdí tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò fi lè fòpin sí ìṣòro ayé, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí i láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí a kò fi kọ orúkọ àwọn tó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i sínú “àkájọ ìwé ìyè” Ọlọ́run? (d) Kí ni Ìjọba Jèhófà yóò ṣe láṣeyọrí?
8 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò lè fòpin sí ìṣòro ayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni tó ṣẹ̀dá ọmọ aráyé kọ́ ló dá a sílẹ̀. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò ní wà pẹ́, nítorí àṣẹ Ọlọ́run ni pé ‘yóò kọjá lọ sínú ìparun.’ Orúkọ àwọn tó dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i kò sí nínú ìwé ìyè Ọlọ́run. Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, báwo làwọn èèyàn wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àtẹni kíkú, tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà, ṣe lè fi Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàṣeyọrí ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun á ṣe láìpẹ́, àmọ́ pé òun ò ní tipasẹ̀ èèyàn ṣe é bí kò ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Kristi Ọlọ́run?—Dáníẹ́lì 7:27; Ìṣípayá 11:15.
9 Ní tòdodo, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jẹ́ ayédèrú Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. Nǹkan àbùkù ló sì jẹ́ sí Jésù Kristi Ọmọ Aládé Àlàáfíà tí Ọlọ́run fi jẹ ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run yìí, tó jẹ́ pé ìjọba rẹ̀ ò ní dópin. (Aísáyà 9:6, 7) Bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bá tiẹ̀ ṣètò àlàáfíà onígbà díẹ̀, kò ní pẹ́ tí ogun á tún fi rú yọ. Àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ò lè ṣe kí wọ́n má jagun nítorí ó ti mọ́ wọn lára. Ìṣípayá sọ pé “a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ìjọba Jèhófà tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ yóò mú àlàáfíà tí ò lópin wá sórí ilẹ̀ ayé, kì í wá ṣe ìyẹn nìkan, yóò tún jí àwọn òkú dìde lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ìyẹn òkú àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo tí wọ́n wà ní ìrántí Ọlọ́run. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Lára àwọn tó máa ní àjíǹde yìí ni gbogbo àwọn tó dúró gbọn-in nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìfi àtakò tí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀ ṣe sí wọn pè, àtàwọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi hàn bóyá wọ́n á jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé orúkọ àwọn tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní kúrò nínú Bábílónì Ńlá tàbí orúkọ ẹnikẹ́ni tí ò bá yéé jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà kò ní wọ ìwé ìyè Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 32:33; Sáàmù 86:8-10; Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 16:2; 17:5.
Àlàáfíà àti Ààbò—Ìrètí Asán
10, 11. (a) Kí ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo ní 1986, kí sì làwọn orílẹ̀-èdè ṣe? (b) “Àwùjọ ìsìn” mélòó ló pé jọ sí Ásísì ní Ítálì láti gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà, ṣé Ọlọ́run sì máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ṣàlàyé.
10 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbìyànjú láti mú kó túbọ̀ dá àwọn èèyàn lójú pé ìrètí ń bẹ, ó polongo pé 1986 jẹ́ “Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé,” ohun tó sì fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìpolongo rẹ̀ ni, “A Fẹ́ Rí I Pé Mìmì Kan Ò Mi Àlàáfíà àti Ọjọ́ Ọ̀la Ọmọ Aráyé.” Wọ́n sọ fáwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun pé kí wọ́n dáwọ́ ogun dúró, ó kéré tán fún ọdún kan. Kí làwọn orílẹ̀-èdè náà wá ṣe? Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àlàáfíà Àgbáyé ròyìn pé ní 1986 nìkan, ó tó mílíọ̀nù márùn-ún [5,000,000] èèyàn tí ogun pa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe àkànṣe owó ẹyọ àti òǹtẹ̀ ìrántí ọdún àlàáfíà yìí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ò ṣe ohun tó máa mú kọ́wọ́ wọn tẹ àlàáfíà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọdún yẹn. Àmọ́, ńṣe làwọn ìsìn ayé bẹ̀rẹ̀ sí í polongo ọdún yẹn lóríṣiríṣi ọ̀nà, torí ohun táwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí kúkú ń wá ni bí àjọṣe á ṣe wà láàárín àwọn àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ní January 1, 1986, Póòpù John Paul Kejì gbóṣùbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé ó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́, ó sì wá ya ọdún tuntun náà sọ́tọ̀ pé ó jẹ́ ọdún àlàáfíà. Lẹ́yìn náà, ní October 27, ó pe àwọn aṣáájú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsìn ayé jọ sí Ásísì ní Ítálì, kí wọ́n lè gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà.
11 Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ó dáa, Ọlọ́run wo làwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn gbàdúrà sí? Bó o bá bi wọ́n léèrè, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan máa sọ. Ǹjẹ́ àgbájọ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọlọ́run kan wà tó lè gbọ́ onírúurú àdúrà tí wọ́n gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà kó sì dáhùn rẹ̀? Mẹ́talọ́kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbàdúrà náà ń jọ́sìn. c Àwọn onísìn Búdà, Híńdù, àtàwọn míì gba onírúurú àdúrà sí ọ̀kẹ́ àìmọye ọlọ́run. Lápapọ̀, “àwùjọ ìsìn” méjìlá ló pé jọ, àwọn to sì ṣojú fún wọn ni àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn bíi Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Áńgílíkà ní Canterbury, Dalai Lama onísìn Búdà, Bíṣọ́ọ̀bù kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ojúbọ Ṣintó ní Tokyo, àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, àtàwọn Àmẹ́ríńdíà méjì tí wọ́n dé ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi ìyẹ́ ṣe sórí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àpéjọ yẹn jojú ní gbèsè ó sì mú kí tẹlifíṣọ̀n rí ìròyìn tó fakíki gbé jáde. Ọ̀kan lára àwọn àwùjọ náà gbàdúrà láìdákẹ́ fún wákàtí méjìlá. (Fi wé Lúùkù 20:45-47.) Síbẹ̀, ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú ọ̀pọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà yẹn kọjá àwọsánmà? Rárá o. A óò rí ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ní ìpínrọ̀ tó kàn.
12. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dáhùn àdúrà àlàáfíà táwọn aṣáájú ìsìn ayé gbà?
12 Àwọn onísìn tí póòpù pè yẹn ò ṣe bíi tàwọn tó ń “rìn ní orúkọ Jèhófà,” ìkankan wọn ò gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè tí orúkọ rẹ̀ fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Míkà 4:5; Aísáyà 42:8, 12) d Wọn ò para pọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run lórúkọ Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ò tiẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. (Jòhánù 14:13; 15:16) Kò sí ọ̀kan nínú wọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe lákòókò wa yìí, ìyẹn ni pé ká máa pòkìkí jákèjádò ayé pé Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ ni ojúlówó ìrètí ayé, kì í ṣe pé ká máa pòkìkí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (Mátíù 7:21-23; 24:14; Máàkù 13:10) Àní àwọn ìsìn ayé yìí lọ́wọ́ sí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ogun ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀, tó fi mọ́ ogun àgbáyé méjèèjì tó jà ní ọ̀rúndún ogún. Ohun tí Ọlọ́run sì sọ fún irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ni pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Aísáyà 1:15; 59:1-3.
13. (a) Kí ni dídarapọ̀ táwọn aṣáájú ìsìn ayé dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà fi hàn? (b) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ni igbe fún àlàáfíà yóò jálẹ̀ sí?
13 Bákan náà, báwọn aṣáájú ìsìn ayé ṣe dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà lákòókò yìí fi nǹkan kan hàn. Àwọn aṣáájú ìsìn náà yóò fẹ́ láti darí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún àǹfààní ara wọn, pàápàá lóde òní tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ wọn ń pa ìsìn tì. Bíi tàwọn aláìṣòótọ́ aṣáájú Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, wọ́n ń kéde pé, “‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.” (Jeremáyà 6:14) Ó dájú pé igbe wọn fún àlàáfíà ò ní yéé dún, ńṣe ni yóò máa dún sókè sí i láti fi hàn pé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ yóò nímùúṣẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.
14. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” gbà dún, kí sì lẹnì kan lè ṣe tí ìyẹn ò fi ní tàn án jẹ?
14 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn olóṣèlú ti lo gbólóhùn náà, “àlàáfíà àti ààbò” láti fi ṣàpèjúwe oríṣiríṣi ohun tí àwọn ènìyàn ń gbèrò láti ṣe. Ǹjẹ́ akitiyan tí àwọn aṣáájú ayé ń ṣe yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmúṣẹ 1 Tẹsalóníkà 5:3? Àbí gbankọgbì ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa gbàfiyèsí gbogbo ayé ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lẹ́yìn tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bá ṣẹ tán tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ lọ́wọ́ la sábà máa ń lóye wọn ní kíkún, a ní láti ṣe sùúrù ká wo ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí. Àmọ́, ó dá àwọn Kristẹni lójú pé bí ayé tiẹ̀ ń sọ pé ọwọ́ àwọn tẹ àlàáfíà àti ààbò lọ́nà kan tàbí òmíràn, ohunkóhun ò ní yí padà. Ìdí ni pé, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìkórìíra, ìwà ọ̀daràn, fífọ́ tí ìdílé ń fọ́, ìṣekúṣe, àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú á ṣì máa ṣẹlẹ̀. Ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ kí igbe “àlàáfíà àti ààbò” kankan tan ìwọ jẹ tó o bá ń wà lójúfò láti mọ ìtumọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tó o sì ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Máàkù 13:32-37; Lúùkù 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a J. F. Rutherford kú ní January 8, 1942, N. H. Knorr sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Watch Tower Society.
b Ní November 20, 1940, Jámánì, Ítálì, Japan, àti Hungary fọwọ́ sí ìwé láti dá “Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tuntun” kan sílẹ̀. Ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, Vatican kéde ìsìn Máàsì àti àdúrà fún àlàáfíà ìsìn àti fún ètò àwọn nǹkan tuntun. Àmọ́ “Ìmùlẹ̀ tuntun” yẹn ò fìdí múlẹ̀.
c Ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan wá láti Bábílónì ayé ọjọ́un tí wọ́n ti ń jọ́sìn ọlọ́run mẹ́ta alápapọ̀, ìyẹn, Shamash ọlọ́run oòrùn, Sin ọlọ́run òṣùpá, àti Ishtar ọlọ́run ìràwọ̀. Báwọn ará Íjíbítì náà ṣe ṣe nìyẹn, wọ́n jọ́sìn ọlọ́run Osiris, Isis, àti Horus. Orí mẹ́ta ni wọ́n fi hàn pé Asshur tó jẹ́ olú ọlọ́run orílẹ̀-èdè Ásíríà ní. Ohun táwọn Kátólíìkì náà sì ṣe nìyẹn, wọ́n gbé àwọn àwòrán tó fi Ọlọ́run hàn bí olórí mẹ́ta sínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn.
d Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Third New International Dictionary ti ọdún 1993 sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni “ẹni tá a mọ̀ sí Ọlọ́run gíga jù lọ, òun sì ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jọ́sìn.”
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 250]
Òdì Kejì “Àlàáfíà”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1986 ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo pé ó jẹ́ Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé, ńṣe ni ìdíje àwọn ohun ìjà apanirun peléke sí i. Ìwé World Military and Social Expenditures 1986 pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó gbàrònú wọ̀nyí:
Ní 1986 àwọn ìnáwó ológun kárí ayé tó bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900,000,000,000] owó dọ́là.
Owó tí wọ́n ná sórí àwọn ológun kárí ayé ní wákàtí kan ṣoṣo ì bá ti tó láti fi pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára fún mílíọ̀nù mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500,000] tó ń kú lọ́dọọdún látàrí àrùn tí ń gbèèràn tí ì bá má ṣẹlẹ̀.
Kárí ayé, ẹnì kan nínú ẹni márùn-ún wà nínú ipò òṣì paraku. Gbogbo àwọn èèyàn tí ebi pa wọ̀nyẹn ni wọn ì bá ti fi owó tí ayé ná sórí àwọn ohun ìjà ní ọjọ́ méjì bọ́ fún ọdún kan.
Agbára ìbúgbàù tó wà nínú àpapọ̀ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tí ayé ní fi ìlọ́po ọgọ́jọ mílíọ̀nù [160,000,000] ju ti ìbúgbàù iléeṣẹ́ ẹ̀rọ Chernobyl lọ.
Bọ́ǹbù runlé-rùnnà kan ṣoṣo tó ní agbára ìbúgbàù tó fi ìlọ́po ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ìgbà lágbára ju ti bọ́ǹbù tá a jù sí ìlú Hiroshima ní 1945 lọ ń bẹ lọ́wọ́ ọmọ aráyé.
Àkójọ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tó wà lọ́wọ́ ní ohun tó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ irú àdó olóró tí wọ́n jù sí ìlú Hiroshima lọ. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ìgbà ni àpapọ̀ agbára ìbúgbàù wọn fi ju ti àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n jù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó pa mílíọ̀nù méjìdínlógójì [38] èèyàn.
Ogun ti túbọ̀ ń wáyé léraléra jù wọ́n sì ń gbẹ̀mí èèyàn jù. Díẹ̀ ni àròpọ̀ iye àwọn tí ogun pa fi dín ní mílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó sì fi díẹ̀ dín ní mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] láàárín ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún ogún. Láti ọ̀rúndún kejìdínlógún, àwọn tógun ń pa ti yára fi ìlọ́po mẹ́fà ju iye àwọn èèyàn tó wà láyé lọ. Ìlọ́po mẹ́wàá ni iye àwọn tí ń kú nínú ogun kọ̀ọ̀kan ní ọ̀rúndún yìí tá a bá fi wé ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 247]
Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ṣe sọ, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àmọ́ ó sọ jí padà gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 249]
Ní ìlú Ásísì lórílẹ̀-èdè Ítálì, àwọn aṣojú ìsìn ayé gba ọ̀pọ̀ àdúrà onídàrúdàpọ̀ láti ṣètìlẹyìn fún “Ọdún Àlàáfíà” àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àmọ́ kò sí ọ̀kan nínú wọn tó gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè