Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Lógo

Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Lógo

Orí 5

Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Lógo

Ìran 1—Ìṣípayá 1:10–3:22

Ohun tó dá lé: Jésù ṣàyẹ̀wò Ísírẹ́lì tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé ó sì fún wọn níṣìírí tọ̀yàyàtọ̀yàyà

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Ẹ̀ka yìí ní ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ láti 1914 á sì máa bá a lọ títí di ìgbà tí èyí tó kẹ́yìn nínú àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró bá kú tó sì jí dìde

1. Ọ̀nà wo la gbà gbé ìran àkọ́kọ́ kalẹ̀, báwo sì ni Jòhánù ṣe fi àkókò ìfisílò rẹ̀ gan-an hàn?

 ÌRAN àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣípayá bẹ̀rẹ̀ ní orí kìíní, ẹsẹ kẹwàá. Bíi tàwọn ìran tó kù nínú ìwé Ìṣípayá, ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìran yìí ni pé òun gbọ́ tàbí pé òun rí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Ìṣípayá 1:10, 12; 4:1; 6:1) Ọ̀nà tá a gbà gbé ìran àkọ́kọ́ yìí kalẹ̀ jẹ́ ti ọ̀rúndún kìíní ó sì jẹ́ nípa iṣẹ́ tí a rán sí ìjọ méje nígbà ayé Jòhánù. Jòhánù fi àkókò ìfisílò rẹ̀ gan-an hàn, ó ní: “Nípa ìmísí, mo wá wà ní ọjọ́ Olúwa.” (Ìṣípayá 1:10a) Ìgbà wo ni “ọjọ́” yìí? Ǹjẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń wáyé lákòókò onírúkèrúdò tá a wà yìí ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí náà, ó yẹ ká fi iyè sí àsọtẹ́lẹ̀ náà gidigidi gẹ́gẹ́ bí èyí tó kan ìgbésí ayé wa, àní gẹ́gẹ́ bí èyí tó kan lílà á já wa.—1 Tẹsalóníkà 5:20, 21.

Ní Ọjọ́ Olúwa

2. Ìgbà wo ni ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni yóò sì dópin?

2 Àkókò wo ni èyí fi hàn pé Ìṣípayá yóò nímùúṣẹ? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ni ọjọ́ Olúwa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ọjọ́ Olúwa jẹ́ àkókò ìdájọ́ àti àkókò tí àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò nímùúṣẹ. (1 Kọ́ríńtì 1:8; 2 Kọ́ríńtì 1:14; Fílípì 1:6, 10; 2:16) Bí “ọjọ́” yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀, àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe ń fi ìṣẹ́gun lọ sí ìparí pátápátá láìdáwọ́dúró. “Ọjọ́” yẹn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dé Jésù ládé gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. Kódà lẹ́yìn tí Jésù bá ti múdàájọ́ ṣẹ sórí ayé Sátánì ṣẹ, ọjọ́ Olúwa á ṣì máa bá a lọ títí tí a ó fi mú Párádísè bọ̀ sípò tí a ó sì sọ aráyé di pípé, yóò tún máa bá a lọ di ìgbà tí Jésù á “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́” níkẹyìn.—1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Ìṣípayá 6:1, 2.

3. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa “ìgbà méje” ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìgbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo lórí ilẹ̀ ayé ló jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé ọdún 1914 ni ọjọ́ Olúwa ìbẹ̀rẹ̀?

3 Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìgbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe bí ìṣàkóso ní ìlà Ọba Dáfídì ṣe di èyí tí a gé lulẹ̀; lẹ́yìn “ìgbà méje” yóò di mímọ̀ pé “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.” (Dáníẹ́lì 4:23, 24, 31, 32) Ìmúṣẹ pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ìjọba Júdà pa run. Ẹ̀rí tá a rí nínú Bíbélì fi hàn pé ìparun náà ti parí nígbà tó fi máa di October ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Ìṣípayá 12:6, 14 fi hàn pé àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́; nípa bẹ́ẹ̀, ìgbà méje (tó jẹ́ ìlọ́po méjì iye yẹn) yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọjọ́. Tá a bá wá mú “ọjọ́ kan fún ọdún kan,” “ìgbà méje” yìí á jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún. (Ìsíkíẹ́lì 4:6) Nítorí náà, Kristi Jésù bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ ní ọ̀run nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún 1914 parí. Ìbẹ́sílẹ̀ Ogun Àgbáyé Kìíní ní ọdún yẹn ló jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà” tó ṣì ń bá a lọ láti pọ́n aráyé lójú. Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́wọ́ ṣe ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti 1914 jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé ọdún 1914 ni “ọjọ́” wíwàníhìn-ín Jésù bẹ̀rẹ̀!—Mátíù 24:3-14. a

4. (a) Kí ni ohun tí Ìṣípayá tìkára rẹ̀ fi hàn nípa àkókò ìmúṣẹ ìran àkọ́kọ́? (b) Ìgbà wo ni ìmúṣẹ ìran àkọ́kọ́ dópin?

4 Nítorí náà, ìran àkọ́kọ́ yìí àti ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀ wà fún ọjọ́ Olúwa, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti 1914 tó sì ń bá a lọ báyìí. Ohun kan tó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìṣirò àkókò yìí tọ̀nà ni pé, nígbà tó yá, ìwé Ìṣípayá tún sọ bí Ọlọ́run á ṣe mú ìdájọ́ rẹ̀ tó jẹ́ òótọ́ tó sì jẹ́ òdodo wá sórí àwọn èèyàn, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí Jésù Olúwa yóò kó ipa pàtàkì nínú rẹ̀. (Ìṣípayá 11:18; 16:15; 17:1; 19:2, 11) Tó bá jẹ́ pé ọdún 1914 ni ìmúṣẹ ìran àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni yóò dópin? Àwọn iṣẹ́ tá a rán síni nínú ìran àkọ́kọ́ náà fi hàn pé ìjọ àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ni ẹgbẹ́ tí ọ̀rọ̀ náà wà fún. Nítorí náà, ìmúṣẹ ìran àkọ́kọ́ yìí yóò dópin nígbà tí olùṣòtítọ́ ìkẹyìn nínú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró bá kú tó sì jí dìde sí ìyè ti ọ̀run. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọjọ́ Olúwa yóò máa bá a lọ bí àwọn àgùntàn mìíràn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń rí ìbùkún, títí di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi.—Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 20:4, 5.

5. (a) Kí ni ohùn kan ké sí Jòhánù láti ṣe? (b) Èé ṣe tí ibi tí “ìjọ méje” náà wà fi rọrùn láti fi àkájọ ìwé ránṣẹ́ sí wọn?

5 Nínú ìran àkọ́kọ́ yìí, kí Jòhánù tó rí ohunkóhun, ó gbọ́ ohùn kan. Ó sọ pé: “Mo sì gbọ́ ohùn líle bí ti kàkàkí lẹ́yìn mi, tí ó wí pé: ‘Kọ ohun tí ìwọ rí sínú àkájọ ìwé, kí o sì fi í ránṣẹ́ sí ìjọ méje, ní Éfésù àti ní Símínà àti ní Págámù àti ní Tíátírà àti ní Sádísì àti ní Filadéfíà àti ní Laodíkíà.’” (Ìṣípayá 1:10b, 11) Bí ìgbà tí wọ́n bá fi ìpè kàkàkí pàṣẹ fúnni, ohùn kan ké sí Jòhánù láti kọ̀wé sí “ìjọ méje.” Wọ́n á fi iṣẹ́ tó pọ̀ rán an, á sì kọ àwọn ohun tó bá rí tó sì gbọ́. Ṣàkíyèsí pé àwọn ìjọ tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn wà lóòótọ́ nígbà ayé Jòhánù. Gbogbo wọn wà ní Éṣíà Kékeré. Ìsọdá òkun ni wọ́n wà téèyàn bá lọ síbẹ̀ láti Pátímọ́sì. Ká sọ pé ońṣẹ́ kan ló ń gbé àkájọ ìwé náà lọ láti ìjọ kan sí èkejì, kò ní ṣòro fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àwọn ọ̀nà tó dára gan-an táwọn ará Róòmù là, èyí tó mú kó rọrùn láti ti ìjọ kan dé èkejì, wà ní àgbègbè náà. Ìjọ méjèèje wọ̀nyí fara jọ ìpín kan nínú àyíká àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní.

6. (a) Kí ni “àwọn ohun tí ó wà” túmọ̀ sí? (b) Èé ṣe tó fi dá wa lójú pé àwọn ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí gbọ́dọ̀ jọ àwọn ohun tá à ń béèrè nígbà ayé Jòhánù?

6 Ẹ̀yìn tí Jòhánù gbé ayé ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá yóò nímùúṣẹ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà tọ́ka sí “àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwọ̀nyí.” Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn tá a fún ìjọ méje náà dá lórí “àwọn ohun tí ó wà,” ìyẹn àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ méje náà lákòókò yẹn. Iṣẹ́ tí wọ́n rán sí àwọn ìjọ méje wọ̀nyẹn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fún àwọn alàgbà olùṣòtítọ́ tó wà nínú àwọn ìjọ náà, àtàwọn alàgbà nínú gbogbo ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti àkókò náà. b Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọjọ́ Olúwa ni ìfisílò pàtàkì ìran yìí wà fún, ohun tí Jésù sọ fi hàn pé irú àwọn ohun tá a béèrè lọ́wọ́ ìjọ méje náà là ń béèrè lọ́wọ́ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti àkókò tá a wà yìí.—Ìṣípayá 1:10, 19.

7. Ta ni Jòhánù rí nínú ìran àkọ́kọ́ yìí, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì tó sì fún wa láyọ̀ gan-an lónìí?

7 Nínú ìran àkọ́kọ́ yìí, Jòhánù rí Jésù Kristi Olúwa tó ń kọ mànà nínú ògo Rẹ̀ ní ọ̀run. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá jẹ́ nípa ọjọ́ ńlá Olúwa tí Ọlọ́run ọ̀run yàn, ǹjẹ́ ohun mìíràn tún wà tó máa bá ìwé náà mu ju ohun tí Jòhánù rí yìí? Ǹjẹ́ ohun kan sì wà tó lè ṣe pàtàkì sí wa ju èyí lọ, àwa tó jẹ́ pé ọjọ́ Olúwa náà la wà yìí ta a sì ń fara balẹ̀ fiyè sí gbogbo àṣẹ rẹ̀? Yàtọ̀ síyẹn, ohun kan tún wà tó mú ayọ̀ ńlá wá fún àwọn alátìlẹyìn Jèhófà nínú ọ̀ràn ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Ohun náà ni pé, ìwé Ìṣípayá mú un dá wọn lójú pé Mèsáyà Irú-Ọmọ náà wà láàyè báyìí ní ọ̀run, Ọlọ́run sì ti gbé agbára lé e lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Gbogbo èyí sì jẹ́ lẹ́yìn tí Irú-Ọmọ yìí ti fara da gbogbo ìdánwò àti inúnibíni tí Sátánì mú wá sórí rẹ̀ àti ikú oró tó kú nígbà tí Sátánì pa Á ní “gìgísẹ̀” ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

8. Kí ni Jésù ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti ṣe?

8 Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti ṣe ohun tó yẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́. Jèhófà ti yàn án gẹ́gẹ́ bí Olórí Amúdàájọ́ṣẹ láti mú ìdájọ́ Jèhófà tó kẹ́yìn wá sórí ètò àwọn nǹkan búburú tó ti di ògbólógbòó yìí àti wá sórí Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ètò ògbólógbòó náà. Jésù tún wà ní sẹpẹ́ láti ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ìjọ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ ńlá olùbákẹ́gbẹ́ wọn, àti láti ṣèdájọ́ ayé.—Ìṣípayá 7:4, 9; Ìṣe 17:31.

9. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo tó wà láàárín àwọn ọ̀pá fìtílà oníwúrà? (b) Kí ni bí ibi tí Jòhánù rí nínú ìran ṣe dà bíi tẹ́ńpìlì fi hàn, kí sì ni ẹ̀wù tí Jésù wọ̀ fi hàn? (d) Kí ni àmùrè wúrà rẹ̀ fi hàn?

9 Jòhánù kọjú síbi ìró ohùn tó ń dún rara náà, ó sì sọ ohun tó rí, ó ní: “Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀, bí mo sì ti yí padà, mo rí ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà.” (Ìṣípayá 1:12) Nígbà tó yá, Jòhánù mọ ohun tí ọ̀pá fìtílà méje náà ṣàpẹẹrẹ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń bẹ láàárín ọ̀pá fìtílà náà ló gba àfiyèsí rẹ̀. Ó ní: “Àti ní àárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnì kan tí ó dà bí ọmọ ènìyàn, tí a wọ̀ ní ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ẹsẹ̀, a sì fi àmùrè wúrà di igẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:13) Jésù tá a mọ̀ sí “ọmọ ènìyàn” fi ara rẹ̀ hàn fún Jòhánù tí jìnnìjìnnì ti bò gẹ́gẹ́ bí ẹni ológo tó ń kọ mànà. Ó fara hàn nínú ògo tó mọ́lẹ̀ yòò láàárín àwọn ọ̀pá fìtílà oníwúrà tí iná ń jó lala lórí wọn. Ìran ibi tó dà bíi tẹ́ńpìlì yìí tẹ̀ ẹ́ mọ́ Jòhánù lọ́kàn pé Jésù ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà títóbi ti Jèhófà, àti pé ó ní àṣẹ láti ṣèdájọ́. (Hébérù 4:14; 7:21-25) Ẹ̀wù rẹ̀ gígùn tó sì dára gan-an bá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà mu. Bíi tàwọn àlùfáà àgbà Júù láyé ọjọ́un, ó fi àmùrè wúrà kan di igẹ̀ rẹ̀ níbi tó ti bo àyà rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé yóò fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.—Ẹ́kísódù 28:8, 30; Hébérù 8:1, 2.

10. (a) Kí ni irun Jésù tó funfun bí ìrì dídì àti ojú rẹ̀ tó dà bí iná fi hàn? (b) Kí ni ẹsẹ̀ Jésù tó dà bí bàbà tí ń tàn yòò rán wá létí rẹ̀?

10 Jòhánù ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí irun àgùntàn funfun, bí ìrì dídì, àti ojú rẹ̀ bí ọwọ́ iná ajófòfò.” (Ìṣípayá 1:14) Irun rẹ̀ tó funfun bí ìrì dídì fi hàn pé ó ní ọgbọ́n nítorí pé àgbàlagbà ọlọ́jọ́ orí ni. (Fi wé Òwe 16:31.) Ẹyinjú rẹ̀ tó dà bí iná tó ń jó fòfò sì fi hàn pé ó já fáfá àti pé ó wà lójúfò bó ṣe ń wádìí, tó ń dánni wò, tàbí bó ṣe ń fi ìbínú hàn. Àní ẹsẹ̀ Jésù pàápàá gba àfiyèsí Jòhánù. Ó ní: “Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí bàbà àtàtà nígbà tí ó bá pọ́n yòò nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi púpọ̀.” (Ìṣípayá 1:15) Nínú ìran náà, ẹsẹ̀ Jésù dà bí bàbà, tó pọ́n yòò, tó mọ́lẹ̀ yòò. Ó tọ́ kí ẹsẹ̀ ẹni tó ń fi ìtara rìn níwájú Jèhófà Ọlọ́run tó sì jẹ́ ẹni tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà rí bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì máa ń fi wúrà ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun tó jẹ́ ti ọ̀run, àmọ́ nígbà mìíràn, ó máa ń fi bàbà ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun tó jẹ́ ti ènìyàn. c Nítorí náà ẹsẹ̀ Jésù tí ń tàn yòò bí ojúlówó bàbà rán wa létí bí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti “dára rèǹtè-rente” tó nígbà tó ń rìn lórí ilẹ̀ ayé bó ṣe ń wàásù ìhìn rere.—Aísáyà 52:7; Róòmù 10:15.

11. (a) Kí ni ẹsẹ̀ Jésù tó lógo rán wa létí rẹ̀? (b) Kí ni ohùn Jésù tó “dà bí ìró omi púpọ̀” fi hàn?

11 Dájúdájú, nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé, ó ní ògo tó hàn gbangba sí àwọn áńgẹ́lì àti èèyàn. (Jòhánù 1:14) Bákan náà, ẹsẹ̀ rẹ̀ ológo rán wa létí pé ó ń tẹ ilẹ̀ mímọ́ nínú ètò Jèhófà, níbi tó ti jẹ́ Àlùfáà Àgbà. (Fi wé Ẹ́kísódù 3:5.) Yàtọ̀ síyẹn, ohùn Jésù dún rara bíi sísán ààrá, ó dà bí ariwo àgbáàràgbá omi tó ń ya wálẹ̀ látorí òkè gíga. Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni, ó sì bá a mu pé kó jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ nítorí pé Bíbélì pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tó wá “láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé ní òdodo.”—Ìṣe 17:31; Jòhánù 1:1.

12. Kí ni “idà gígùn olójú méjì mímú” fi hàn?

12 Jòhánù ń tẹ̀ síwájú láti sọ ohun tó rí, ó ní: “Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, idà gígùn olójú méjì mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn nígbà tí ó bá ń ràn nínú agbára rẹ̀. Nígbà tí mo sì rí i, mo ṣubú bí òkú lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:16, 17a) Jésù tìkára rẹ̀ ṣàlàyé ìtumọ̀ ìràwọ̀ méje náà kété lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí ohun tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde, ìyẹn “Idà gígùn olójú méjì mímú.” Ìrísí yìí bá a mu gan-an ni. Ìdí ni pé Jésù ni ẹni tí Jèhófà yàn pé kó kéde ìdájọ́ ìkẹyìn Òun lórí àwọn ọ̀tá Òun. Ọ̀rọ̀ àṣẹ tó ti ẹnu rẹ̀ jáde yóò yọrí sí fífi ikú pa gbogbo àwọn èèyàn búburú.—Ìṣípayá 19:13, 15.

13. (a) Kí ni ojú Jésù tó mọ́lẹ̀ yòò tó sì ń kọ̀ mànà rán wa létí rẹ̀? (b) Kí ni ohun pàtàkì tí àpèjúwe tí Jòhánù ṣe nípa Jésù tẹ̀ mọ́ wa lọ́kàn?

13 Ojú Jésù tó mọ́lẹ̀ yòò tó sì ń kọ mànà rán wa létí pé ojú Mósè mú àwọn ìtànṣán tó ń kọ mànà jáde lẹ́yìn tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 34:29, 30) Tún rántí pé nígbà tí a pa Jésù lára dà lójú mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, “ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” (Mátíù 17:2) Bákan náà, nínú ìran tó ṣàpẹẹrẹ Jésù ní ọjọ́ Olúwa, ojú Jésù ń dán mànà ó sì ní ògo gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti wà lọ́dọ̀ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 3:18) Dájúdájú, ohun pàtàkì tí ìran Jòhánù tẹ̀ mọ́ wa lọ́kàn ni ògo tí ń dán yanran. Irun tó funfun bí òjò dídì, ẹyinjú tó dà bí iná tó ń jó fòfò, ojú tí ń kọ mànà àti ẹsẹ̀ tí ń ràn yòò, jẹ́ ìran tó dára gan-an nípa Ẹni tó ń gbé nísinsìnyí “nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́.” (1 Tímótì 6:16) Ó hàn gbangba pé ohun gidi ni ìran yìí! Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe nígbà tó rí ìran yìí tí jìnnìjìnnì sì bò ó ré kọjá ààlà? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo sì rí i, mo ṣubú bí òkú lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 1:17.

14. Kí ló yẹ kí kíkà tá à ń ka ìran Jòhánù nípa Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo sún wa ṣe?

14 Lónìí, àpèjúwe ẹlẹ́wà tí Jòhánù ṣe lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa ìran tó rí mú kí àwa èèyàn Jèhófà ní ìmọrírì àtọkànwá. Ní báyìí, ó ti ju àádọ́rùn-ún [90] ọdún lọ tí ọjọ́ Olúwa ti bẹ̀rẹ̀. Ìran náà sì ṣì ń bá a lọ láti ní ìmúṣẹ amóríyá ní ọjọ́ Olúwa tá a wà yìí. Àwa ò retí pé ọjọ́ iwájú ni Àkóso Ìjọba Jésù máa bẹ̀rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, a gbà pé Ìjọba náà ń ṣàkóso bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà, níwọ̀n bá a ti jẹ́ olóòótọ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà, ó yẹ ká túbọ̀ fi ìyàlẹ́nu wo ohun tí Jòhánù ṣàpèjúwe nínú ìràn àkọ́kọ́ yìí, ká fetí sílẹ̀ ká sì ṣègbọràn sí ohun tí Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo sọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo ojú ìwé 88 sí 92, 215 sí 218 nínú ìwé náà, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

b Ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí ìjọ kan bá gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ àpọ́sítélì kan, ó jẹ́ àṣà wọn láti fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ yí ká àwọn ìjọ tó kù kí gbogbo wọn bàa lè jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn náà.—Fi wé Kólósè 4:16.

c Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tàbí tí wọ́n fi bò wọ́n lára. Àmọ́ bàbà ni wọ́n lò fún àwọn ohun tó wà nínú àgbàlá.—1 Àwọn Ọba 6:19-23, 28-35; 7:15, 16, 27, 30, 38-50; 8:64.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwókù àwọn ìlú tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí níbi táwọn ìjọ méje náà wà fi hàn pé òótọ́ ni àkọsílẹ̀ Bíbélì. Ibẹ̀ ni àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ti gba iṣẹ́ tó ń fúnni níṣìírí tí Jésù rán sí wọn, èyí tó ń fún àwọn ìjọ níṣìírí jákèjádò ayé lónìí.

PÁGÁMÙ

SÍMÍNÀ

TÍÁTÍRÀ

SÁDÍSÌ

ÉFÉSÙ

FILADÉFÍÀ

LAODÍKÍÀ