Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2013
“Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.” Jóṣúà 1:9
Ní ọdún 1473 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ àwọn ọ̀tá tó lágbára wà níwájú wọn. Ni Ọlọ́run bá pàṣẹ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi.” Tí Jóṣúà bá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un, ó máa ṣàṣeyọrí. Jèhófà sọ fún un pé: “Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lóòótọ́, torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn láàárín ọdún mẹ́fà péré.—Jóṣ. 1:7-9.
Àwa Kristẹni tòótọ́ máa tó wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Bíi ti Jóṣúà, à ń kojú àwọn ọ̀tá alágbára tó ń wá ọ̀nà láti ba ìwà títọ́ wa jẹ́. Kì í ṣe ọ̀kọ̀ àti idà la fi ń wọ̀yá ìjà bí kò ṣe àwọn ohun ìjà ogun tẹ̀mí. Jèhófà sì ti kọ́ wa bá a ṣe lè lo àwọn ohun ìjà tẹ̀mí lọ́nà tó já fáfá. Ipò yòówù kó o bá ara rẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá jẹ́ onígboyà àti alágbára, tó o sì jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ, á sì sọ ẹ́ di aṣẹ́gun.