Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bawo Ni Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Ṣe Gbèrú?

Bawo Ni Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Ṣe Gbèrú?

Bawo Ni Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Ṣe Gbèrú?

NÍBI ti a de yii iwọ lè beere pe: ‘Bí Mẹtalọkan kìí bá ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli, bawo ni o ṣe di ẹ̀kọ́ Kristẹndọmu?’ Ọpọlọpọ ronu pe a gbé é kalẹ̀ ní Ajọ ìgbìmọ̀ Nicaea ní 325 C.E.

Iyẹn kii ṣe otitọ delẹdelẹ, bi o ti wu ki o ri. Àjọ ìgbìmọ̀ Nicaea tẹnumọ ọn niti gidi pe Kristi jẹ́ ẹni kan naa bí Ọlọrun, eyi tí ó fi ìpilẹ̀ naa lélẹ̀ fun ẹ̀kọ́ ìsìn Mẹtalọkan tí ó dé lẹhin naa. Ṣugbọn kò fìdí Mẹtalọkan múlẹ̀, nitori pe ní àjọ ìgbìmọ̀ yẹn a kò mẹnuba ẹ̀mí mímọ́ gẹgẹ bi ẹni kẹta lara Ọlọrun ẹlẹni mẹta ti mẹta-ninu-ọkan kan.

Ipa Ti Constantine Kó ní Nicaea

FUN ọpọlọpọ ọdun, ọpọlọpọ atako ti a gbe kari awọn ẹri Bibeli ni o wà sí èrò tí ńgbèrú naa pe Jesu ni Ọlọrun. Lati gbìyànjú lati wá ojútùú sí ariyanjiyan naa, olú ọba Roomu naa Constantine pè gbogbo awọn biṣọọbu jọ sí Nicaea. Nǹkan bii 300, tí ó jẹ́ ipin kereje ni ifiwera pẹlu àpapọ̀ gbogbo wọn, ni wọn wá síbẹ̀ niti gidi.

Constantine kìí ṣe Kristẹni. Ero naa ni pe, oun yípadà nigba ti ó yá ninu ìgbésí-ayé rẹ, ṣugbọn oun kò ṣe iribọmi títí di igba ti o fi nku lọ. Nipa rẹ̀, Henry Chadwick sọ ninu iwe naa The Early Church pe: “Constantine, gẹgẹ bi baba rẹ̀, jọsin Oòrùn Alaiṣeebori; . . . ìyípadà rẹ̀ ni a kò lè túmọ̀sí iriri àtinúwá ti oore-ọ̀fẹ́ . . . Ó jẹ́ ọ̀ràn ológun. Oye rẹ nipa ẹ̀kọ́ Kristẹni kò ṣe kedere gan-an nígbà kankan rí, ṣugbọn oun ni ìdánilójú pe ìjagunmólú loju ogun sinmi lori ẹ̀bùn Ọlọrun awọn Kristẹni.”

Ipa wo ni olú ọba alaiṣeribọmi yii kó ninu Àjọ ìgbìmọ̀ Nicaea? Iwe Encyclopædia Britannica rohin pe: “Constantine fúnraarẹ̀ ni o ṣalága, ní fifi aapọn ṣàmọ̀nà awọn ijiroro naa, tí oun fúnraarẹ̀ sì dabaa . . . ìlànà pàtàkì tí ńṣàlàyé ìbátan Kristi pẹlu Ọlọrun ninu ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí àjọ ìgbìmọ̀ naa tẹjade, ‘nipa jíjẹ́ ìpilẹ̀ kan pẹlu Baba’ . . . Awọn biṣọọbu naa, tí olú ọba naa ti mú ní ìbẹ̀rù jinnijinni tí ó kọja ààlà, fọwọ́sí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ naa àfi kìkì meji ninu wọn, eyi tí ó pọju ninu wọn si ṣe bẹẹ lodisi ìtẹ̀sí ọkan wọn.”

Nipa bayii, ipa ti Constantine kó jẹ́ eyi tí ó ṣe pàtàkì. Lẹhin ìjiyàn isin tí ó kún fun ìhónú fun oṣu meji, oṣelu oloriṣa yii dásí ọ̀ràn naa ó sì pinnu ní ìfaramọ́ awọn wọnni tí wọn sọ pe Jesu ni Ọlọrun. Ṣugbọn eeṣe? Dajudaju kìí ṣe nitori ìdálójú ìgbàgbọ́ eyikeyi tí ó bá Bibeli mú. “Niti tootọ Constantine kò lóye ohunkohun lara awọn ibeere tí a nbeere ninu ẹ̀kọ́ ìsìn Giriiki,” ni iwe naa A Short History of Christian Doctrine wi. Ohun tí oun lóye niti gidi ni pe ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ isin nhalẹ̀mọ́ ilẹ̀-ọba rẹ̀, oun sì fẹ́ lati tubọ mú ilẹ ọba rẹ̀ lágbára sii.

Kò sí ọ̀kankan lara awọn biṣọọbu naa ní Nicaea tí ó gbé Mẹtalọkan larugẹ, bi o ti wu ki o ri. Wọn pinnu kìkì iru ẹda tí Jesu jẹ ṣugbọn kìí ṣe ipa tí ẹ̀mí mímọ́ kó. Bí Mẹtalọkan bá ti jẹ́ otitọ Bibeli tí ó ṣe kedere, kìí ha íṣe ìgbà yẹn ni o ti yẹ kí wọn dabaa rẹ̀ bi?

Ìdàgbàsókè Siwaju Sii

LẸHIN Nicaea, awọn ìjiyàn lori ọ̀ràn naa nbaa lọ fun ọpọlọpọ ẹwadun lẹhin naa. Awọn wọnni tí wọn gbagbọ pe Jesu kò bá Ọlọrun dọ́gba tilẹ̀ pada wá di awọn tí a gba tiwọn fun akoko kan. Ṣugbọn nigba ti ó yá Olú ọba Theodosius pinnu lodisi wọn. Oun fìdí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ Àjọ ìgbìmọ̀ Nicaea múlẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀pá-ìdíwọ̀n fun ilẹ̀ àkóso rẹ̀ ó sì pè apejọpọ Àjọ ìgbìmọ̀ Constantinople ní 381 C.E. lati mú ìlànà naa ṣe kedere.

Àjọ ìgbìmọ̀ yẹn fohùnṣọ̀kan lati fi ẹ̀mí mímọ́ sori ipele kan naa pẹlu Ọlọrun ati Kristi. Fun ìgbà àkọ́kọ́, Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu bẹ̀rẹ̀síí wá sí ojutaye.

Síbẹ̀, kódà lẹhin Àjọ ìgbìmọ̀ Constantinople, Mẹtalọkan kò di ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí a tẹwọgba lọna gbígbòòrò. Ọpọlọpọ tako o tí wọn sì mú inunibini oniwa-ika wá sori araawọn. Kìkì ni awọn ọrundun lẹhin naa ni a gbé Mẹtalọkan kalẹ̀ gẹgẹ bi ijẹwọ igbagbọ ti a kọsilẹ. The Encyclopedia Americana ṣakiyesi pe: “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ idagbasoke igbagbọ ninu Mẹtalọkan ṣẹlẹ ní apá Iwọ-oorun, nipasẹ Ajọ igbokegbodo ti o pa ero ori pọ mọ igbagbọ atọwọdọwọ ti Aarin Ìgbà Ọ̀làjú, nigba ti a mú alàyé kan lò ní ìsopọ̀ pẹlu ẹkọ ìmọ̀-ọ̀ràn ati imọ ironu ẹda.”

Ìjẹ́wọ ìgbàgbọ́ Athanasius

MẸTALỌKAN ni a túmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ sii ninu Ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ Athanasius. Athanasius jẹ́ alufaa ṣọọṣi kan tí ó ti Constantine lẹhin ní Nicaea. Ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ naa tí ó gbé orukọ rẹ̀ rù polongo pe: “A njọsin Ọlọrun kan ninu Mẹtalọkan . . . Baba jẹ́ Ọlọrun, Ọmọkunrin jẹ́ Ọlọrun, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Ọlọrun; ṣugbọn síbẹ̀ wọn kìí ṣe ọlọrun mẹta, ṣugbọn Ọlọrun kan.”

Awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọn jẹ́ ògbógi ní ìmọ̀ dáadáa, bi o ti wu ki o ri, fohùnṣọ̀kan pe Athanasius kọ́ ni ó ronúkọ ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ yii jade. The New Encyclopædia Britannica ṣalaye pe: “Ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ naa ni a kò mọ̀ ni Ṣọọsi Ila-oorun títí di ọ̀rúndún kejila. Lati ọ̀rúndún kẹtadinlogun, awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ti fohùnsọ̀kan ní gbogbogboo pe Athanasius kọ́ ni ó kọ́ Ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ Athanasius (ó kú ní 373) ṣugbọn ó ṣeeṣe kí ó jẹ́ pe guusu France ni a ti ronú kọ ọ́ jáde ní ọ̀rúndún karun-un . . . Agbára ìdarí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ naa dabi ẹni pe ó ti wà ní guusu France ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ati ní Spain ní ọ̀rúndún kẹfa ati ekeje. Wọn lò ó ninu ìlànà ìjọsìn ṣọọṣi ní Germany ní ọ̀rúndún kẹsan-an ati nígbàkan lẹhin naa ní Roomu.”

Nitori naa ó gbà ọpọlọpọ ọ̀rùndún lati akoko Kristi kí Mẹtalọkan tó di eyi tí a tẹ́wọ́gbà lọna gbígbòòrò ninu Kristẹndọmu. Ati ninu gbogbo eyi, ki ni ó ṣamọna awọn ipinnu naa? Ó ha jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tabi awọn agbeyẹwo awujọ alufaa ati ti iṣelu? Ninu iwe naa Origin and Evolution of Religion, E. W. Hopkins dahun pe: “Ìtúmọ̀ ikẹhin ti mẹtalọkan tí gbogbogboo tẹwọgba ni pataki jẹ ọ̀ràn iṣelu ninu ṣọọṣi.”

Ìpẹ̀hìndà Ni A Sọtẹlẹ

ÌTÀN alainilaari ti Mẹtalọkan yii ba ohun tí Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ sọtẹlẹ pe yoo tẹ̀lé akoko wọn mu. Wọn sọ pe ìpẹ̀hìndà yoo wà, ìyapa, ìṣubú kúrò ninu ijọsin tootọ títí di ìgbà ìpadàbọ̀ Kristi, nigba ti a ó mú ijọsin tootọ padabọ̀sípò ṣaaju ọjọ́ iparun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Nipa “ọjọ́” yẹn, apọsiteli Pọọlu sọ pe: “Kì yoo dé àyàfi bí ìpẹ̀hìndà bá kọ́kọ́ dé tí a sì ṣí ọkunrin ailofin naa payá.” (2 Tẹsalonika 2:⁠3, 7, NW) Lẹhin naa, oun sọtẹlẹ pe: “Nigba ti mo ba ti lọ awọn ìkòokò rírorò yoo rọ́ wọ inú yin wọn kì yoo sì ní aanu sí agbo. Àní lati inu ẹgbẹ yin funraayin pàápàá ni awọn ọkunrin yoo wà tí wọn dide pẹlu àdàmọ̀dì òtítọ́ ní ètè wọn lati rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin lọ́kàn lati tẹ̀lé wọn.” (Iṣe 20:​29, 30, JB) Awọn ọmọ-ẹhin Jesu miiran pẹlu kọ̀wé nipa ìpẹ̀hìndà yii pẹlu ẹ̀gbẹ́ awujọ alufaa ‘aláìlófin’ rẹ̀.​—⁠Wo, fun apẹẹrẹ, 2 Peteru 2:⁠1; 1 Johanu 4:​1-⁠3; Juuda 3, 4.

Pọọlu kọ̀wé pẹlu pe: “Ó daju pe akoko naa yoo dé nigba ti, láìní ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn rárá pẹlu ẹ̀kọ́ yíyèkooro, awọn eniyan yoo yanhanhan fun ẹkọ àṣẹ̀ṣẹ̀jáde tí wọn yoo sì kó ọ̀wọ́ awọn olùkọ́ni jọ funraawọn ní ìbámu pẹlu ohun ti o dun mọ awọn funraawọn; ati lẹhin naa, dípò kí wọn fetisilẹ sí otitọ, wọn yoo yípadà sí awọn àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́.”​—⁠2 Timoti 4:​3, 4JB.

Jesu fúnraarẹ̀ ṣàlàyé ohun tí ó wà lẹhin ìṣubú kúrò ninu ijọsin tootọ yii. O sọ pe oun ti gbìn awọn irúgbìn dídára ṣugbọn pe ọ̀tá naa, Satani, yoo tún gbìn awọn epo sori pápá naa. Nitori naa papọ̀ pẹlu awọn ẹka ti o kọkọ hu jade, awọn èpò naa farahan pẹlu. Nipa bayii, ìyapa kuro ninu isin Kristẹni mímọ́gaara ni a gbọdọ fojúsọ́nà fun títí di ìgbà ìkórè, nigba ti Kristi yoo mú awọn ọ̀ràn tọ́. (Matiu 13:​24-43) The Encyclopedia Americana ṣàlàyé pe: “Igbagbọ Mẹtalọkan ti ọgọrun-un ọdun kẹrin kò fihàn lọna pípéye ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni ijimiji nipa iru ẹda Ọlọrun; ní odikeji gan-an, ó jẹ́ ìyapa kuro ninu ẹ̀kọ́ yii.” Nibo, nigba naa, ni ìyapa yii ti pilẹ̀ṣẹ̀?​—⁠1 Timoti 1:⁠6.

Ohun Tí Ó Lò Agbára Idarí Lori Rẹ̀

JÁLẸ̀JÁLẸ̀ ayé igbaani, padasẹhin sí Babiloni, ijọsin awọn ọlọrun olórìṣà tí a pín sí mẹta-mẹta, tabi mẹ́ta alapapọ jẹ ohun ti o wọ́pọ̀. Agbára ìdarí yẹn gbalẹ̀ pẹlu ní Ijibiti, Giriisi, ati Roomu ní awọn ọgọrun-un ọdun ṣaaju, nígbà, ati lẹhin Kristi. Lẹhin ikú awọn apọsiteli, iru awọn ìgbàgbọ́ olórìṣà bẹẹ bẹ̀rẹ̀síí rọ́ wọ inú isin Kristẹni.

Òpìtàn Will Durant ṣakiyesi pe: “Isin Kristẹni kò pa isin olórìṣà run; ó ṣamulo rẹ . . . Lati Ijibiti ni awọn èrò nipa mẹtalọkan àtọ̀runwá ti wá.” Ati ninu iwe naa Egyptian Religion, Siegfried Morenz ṣakiyesi pe: “Mẹtalọkan jẹ́ aniyan ṣíṣe pàtàkì tí ó gba awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Ijibiti lọ́kàn . . . Awọn ọlọrun mẹta ni wọn papọ̀ tí wọn sì ka si ẹda kanṣoṣo, tí wọn si ńsọ̀rọ̀ rẹ gẹgẹ bi ẹnikan. Ní ọ̀nà yii agbara isin Ijibiti nipa tẹ̀mí fi ìsopọ̀ tààràtà pẹlu ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni hàn.”

Nipa bayii, ní Alẹksandria, Ijibiti, awọn eniyan ṣọọṣi ìparí ọrundun kẹta ati ìbẹ̀rẹ̀ ọrundun kẹrin, iru bii Athanasius, ṣàfihàn agbára ìdarí yii bí wọn ṣe gbé awọn ironu tí ó ṣamọna lọ sí Mẹtalọkan kalẹ. Agbára ìdarí wọn tànkalẹ̀ tobẹẹ tí ó fi jẹ́ pe Morenz wo “ẹ̀kọ́-ìsìn Alẹksandria gẹgẹ bi alarina laaarin ohun ajogunba isin Ijibiti ati isin Kristẹni.”

Ninu ọ̀rọ̀ àkọṣáájú iwe naa History of Christianity, lati ọwọ́ Edward Gibbon, a kà pe: “Bí isin Kristẹni bá ṣẹ́gun ìsìn olórìṣà, ó jẹ́ otitọ bakan naa pe ìsìn olórìṣà ti sọ isin Kristẹni dìbàjẹ́. Igbagbọ ninu Ọlọrun kan ti awọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ . . . ni Ṣọọṣi Roomu yípadà, sí igbagbọ aláìjampata ti ko si ṣee loye ti mẹtalọkan. Ọpọlọpọ lara awọn ìlànà olórìṣà tí awọn ará Ijibiti hùmọ̀ jáde tí Plato si sọ di igbagbọ ero ori, ni wọn ṣì dìmú títí gẹgẹ bi ohun tí ó yẹ lati gbàgbọ́.”

A Dictionary of Religious Knowledge ṣakiyesi pe ọpọlọpọ ńsọ pe Mẹtalọkan jẹ “ìsọdìbàjẹ́ kan tí a yá lati inú awọn isin abọgibọ̀pẹ̀, tí a sì muwọ inu igbagbọ Kristẹni.” The Paganism in Our Christianity sì polongo pe: “Ìpilẹ̀ṣẹ̀ [Mẹtalọkan] jẹ́ ti olórìṣà patapata.”

Ìdí niyẹn ti James Hastings fi kọ̀wé, ninu Encyclopædia of Religion and Ethics pe: “Ninu isin India, fun apẹẹrẹ, a npade awujọ awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ mẹtalọkan ti Brahmā, Siva, ati Viṣṇu; ati ninu isin Ijibiti pẹlu awujọ ẹlẹ́kọ̀ọ́ mẹtalọkan ti Osiris, Isis, ati Horus . . . Bẹẹ sì ní kìí ṣe kìkì ninu awọn isin ti a ka ninu itan nìkan ni a ti ńri i tí awọn eniyan ńfojúwò Ọlọrun gẹgẹ bi Mẹtalọkan. Ẹnikan lè rántí ní pàtàkì ojú ìwòye Ẹ̀kọ́ àmúdọ̀tun Plato nipa otitọ Gigajulọ tabi Okodoro Otitọ,” tí a “fi Mẹtalọkan duro fun.” Ki ni ọ̀mọ̀ràn Giriiki naa Plato níí ṣe pẹlu Mẹtalọkan?

Ẹ̀kọ́ Igbàgbọ́ Plato

PLATO, ni a rò pe o gbé aye lati 428 sí 347 ṣaaju Kristi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe oun kò fi Mẹtalọkan kọ́ni gẹgẹ bi a ṣe mọ̀ ọ́n nisinsinyi, awọn ìmọ̀-ọ̀ràn rẹ̀ là ọ̀nà fun un. Nigba ti ó yá, awọn àjọ ìgbòkègbodò ìmọ̀-ọ̀ràn tí wọn ní awọn ìgbàgbọ́ Mẹtalọkan ńrú jáde wá, awọn wọnyi sì ní èrò Plato nipa Ọlọrun ati ohun adanida lo agbara idari le lori.

Iwe Nouveau Dictionnaire Universel lédè French (New Universal Dictionary) sọ nipa agbára ìdarí Plato pe: “Mẹtalọkan ti Plato, tí o wulẹ̀ jẹ́ atunto awọn mẹtalọkan ògbólógbòó tí ọjọ́ rẹ̀ lọ sẹ́hìn dé akoko awọn eniyan ijimiji, dabii ẹni pe oun ni o jẹ́ mẹtalọkan awọn animọ ti o ba ọgbọn ironu awọn onimọ nipa ọran aye ati iwalaaye mu ti o di ipilẹ fun awọn ẹni mẹta tabi awọn ẹda ọrun tí awọn ṣọọṣi fi ńkọ́ni . . . Ero ọ̀mọ̀ràn Giriiki yii nipa mẹtalọkan àtọ̀runwá . . . ni a lè rí ninu gbogbo ìsìn [olórìṣà] igbaani.”

Iwe naa The New Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge fi agbára ìdarí ìmọ̀-ọ̀ràn Giriiki yii hàn pe: “Awọn ẹ̀kọ́ Logos ati Mẹtalọkan rí ìrísí wọn gbà lati ọ̀dọ̀ awọn Aṣaaju isin Giriiki, awọn ẹni tí . . . ìmọ̀-ọ̀ràn Plato lò agbára ìdarí lé lórí, yálà ní tààràtà tabi láìṣe tààràtà . . . pe awọn ìṣìnà ati ìsọdìbàjẹ́ rápálá wọnú ṣọọṣi lati inu orísun yii ni a kò lè sẹ́.”

Iwe naa The Church of the First Three Centuries sọ pe: “Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan jẹ́ ìsọfúnni tí ó dé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tí ó sì jẹ́ ti àìpẹ́ yii bí a bá fiwéra; . . . ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá lati inu orísun kan tí ó ṣàjòjì patapata sí ti Iwe Mimọ Kristẹni ati ti Juu; . . . ó dàgbà, a sì mú un wọnu isin Kristẹni lati ọwọ́ awọn Aṣaaju isin ẹlẹ́kọ̀ọ́ Plato.”

Nigba ti o fi maa di opin ọ̀rúndún kẹta Sanmani Tiwa, “Isin Kristẹni” ati awọn ìmọ̀-ọ̀ràn Plato titun di eyi tí ó sopọ̀ṣọ̀kan làíṣeé yàsọ́tọ̀. Gẹgẹ bi Adolf Harnack ṣe sọ ninu iwe naa Outlines of the History of Dogma, ẹ̀kọ́ ṣọọṣi di eyi tí ó “fi gbòǹgbò múlẹ̀ gbọnyingbọnyin lori ipilẹ ìgbàgbọ́ Heleni [ìrònú olórìṣà ti Giriiki]. Nipa bayii ó di ohun ìjìnlẹ̀ kan fún eyi tí ó pọ julọ lara awọn Kristẹni.”

Awọn ṣọọṣi kede pe awọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ titun ni oun gbékà orí Bibeli. Ṣugbọn Harnack sọ pe: “Níti gidi awọn ìméfò Heleni, awọn ojú ìwòye onígbàgbọ́ nínú ohun asán ati awọn àṣà ijọsin ohun ìjìnlẹ̀ olórìṣà ni oun ti fi aṣẹ sọ di otitọ laaarin ara rẹ̀.”

Ninu iwe naa A Statement of Reasons, Andrews Norton sọ nipa Mẹtalọkan pe: “A lè tọpa ìtàn ẹ̀kọ́ yii, kí a sì ṣàwárí orísun rẹ̀, kìí ṣe ninu ìṣípayá Kristẹni, bíkòṣe ìmọ̀-ọràn Plato . . . Mẹtalọkan kìí ṣe ẹ̀kọ́ Kristi ati awọn apọsiteli rẹ̀, ṣugbọn ó jẹ́ ìtàn-àròsọ ilé-ẹ̀kọ́ awọn ọmọlẹhin Plato nigba ti ó yá.”

Nipa bayii, ní ọrundun kẹrin Sanmanni Tiwa, ìpẹ̀hìndà tí Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ sọtẹlẹ di eyi tí ó wá gbèrú lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ìgbèrú Mẹtalọkan wulẹ jẹ́ ẹ̀rí kan lára iwọnyi. Awọn ṣọọṣi apẹ̀hìndà pẹlu bẹ̀rẹ̀síí tẹwọgba awọn èrò olórìṣà miiran, iru bii hell onina, àìlèkú ọkàn, ati ìbọ̀rìṣà. Ní sísọ̀rọ̀ nipa tẹ̀mí, Kristẹndọmu ti wọnu awọn sanmanni ojú dúdú rẹ̀ tí a sọtẹlẹ, tí ẹgbẹ́ awọn alufaa “ọkunrin ìwà-àìlófin” tí ńdàgbà sii jọba lé lórí.​—⁠2 Tẹsalonika 2:​3, 7NW.

Eeṣe Tí Awọn Wolii Ọlọrun Kò Ṣe Fi Kọ́ni?

EEṢE, fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, tí ọ̀kankan lara awọn wolii Ọlọrun kò fi Mẹtalọkan kọ́ awọn eniyan rẹ̀? Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jesu kì yoo ha lò itootun rẹ̀ gẹgẹ bi Olùkọ́ Nla lati mú Mẹtalọkan ṣe kedere sí awọn ọmọlẹhin rẹ̀? Ọlọrun yoo ha mísí ọgọrọọrun oju-iwe Iwe Mimọ ati síbẹ̀ kí ó má lò itọni rẹ̀ eyikeyii lati fi Mẹtalọkan kọ́ni bí ó bá jẹ́ “olori ẹ̀kọ́” ìgbàgbọ́?

Awọn Kristẹni ha nilati gbàgbọ́ pe ní ọpọlọpọ ọrundun lẹhin Kristi ati lẹhin mímísí awọn akọsilẹ Bibeli, Ọlọrun yoo ṣe itilẹhin fun igbekalẹ ẹ̀kọ́ kan tí awọn iranṣẹ rẹ kò mọ̀ fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹ́hìn, ọ̀kan tí ó jẹ́ “àdììtú ohun ìjìnlẹ̀” “tí ó rekọja ìmòye ìronú ẹ̀dá ènìyàn,” ọ̀kan tí a gbà pe ó ní ipilẹṣẹ olórìṣà tí ó sì jẹ́ “ọ̀ràn iṣelu ninu ṣọọṣi ni pataki”?

Ẹ̀rí ìtàn ṣe kedere: Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan jẹ́ ìyapa kúrò ninu otitọ, ìpẹ̀hìndà kuro ninu rẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

‘Ìgbàgbọ Mẹtalọkan ti ọrundun kẹrin jẹ́ ìyapa kúrò ninu ẹ̀kọ́ Kristẹni ijimiji.’​—⁠The Encyclopedia Americana

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

“Mẹ́ta Nínú Ọ̀kan Awọn Ọlọrun Ńlá”

Ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun ṣaaju akoko Kristi, mẹ́ta nínú ọ̀kan, tabi awọn mẹtalọkan, ti awọn ọlọrun ara Babiloni ati Asiria igbaani wà. Iwe naa lédè French, “Larousse Encyclopedia of Mythology” ṣakiyesi ọ̀kan lára irufẹ mẹ́ta nínú ọ̀kan bẹẹ ní àgbègbè Mesopotamia: “Àgbáyé ni a pín sí ẹkùn mẹta ti ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn di ilẹ̀ àkóso ọlọrun kan. Ìpín ti Anu ni òfúúrufú. Ilẹ̀-ayé ni wọn fifun Enlil. Ea di olùṣàkóso awọn omi. Lápapọ̀ wọn jẹ́ mẹ́ta nínú ọ̀kan awọn Ọlọrun Ńlá.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Mẹtalọkan ti Hindu

Iwe naa “The Symbolism of Hindu Gods and Rituals” sọ nipa mẹtalọkan Hindu kan tí ó wà ní ọ̀pọ̀ ọgọrun-un ọdun ṣaaju Kristi pe: “Siva jẹ́ ọ̀kan lára awọn ọlọrun Mẹtalọkan. Oun ni a sọ pe ó jẹ́ ọlọrun iparun. Awọn ọlọrun meji yooku ni Brahma, ọlọrun ìṣẹ̀dá ati Vishnu, ọlọrun olupamọ. . . . Lati fihan pe awọn ọ̀nà-ìṣiṣẹ́ mẹta wọnyi jẹ́ ọ̀kanṣoṣo tí wọn sì rí bakan naa awọn ọlọrun mẹta naa ni a papọ̀ gẹgẹ bi ọkanṣoṣo.”​—⁠A tẹ̀ ẹ́ jáde lati ọwọ́ A. Parthasarathy, Bombay.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

“Niti tootọ Constantine kò loye ohunkohun lara awọn ibeere tí a ńbéèrè ninu ẹ̀kọ́ ìsìn Giriiki.”​—⁠A Short History of Christian Doctrine

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

1. Ijibiti. Mẹta ninu ọkan ti Horus, Osiris, Isis, ẹgbẹrun ọdun keji B.C.E.

2. Babiloni. Mẹta ninu ọkan ti Ishtar, Sin, Shamash, ẹgbẹrun ọdun keji B.C.E.

3. Palmyra. Mẹta ninu ọkan ti ọlọrun òṣùpá, Oluwa awọn Ọ̀run, ọlọrun oòrùn, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E.

4. India. Mẹta ninu ọ̀kan ọlọrun olori mẹta ti Hindu, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun keje C.E.

5. Kampuchea. Mẹta ninu ọkan ọlọrun olori mẹta ti Buddha, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kejila C.E.

6. Norway. Mẹtalọkan (Baba, Ọmọkunrin, ẹ̀mí mímọ́), nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kẹtala C.E.

7. France. Mẹtalọkan, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kẹrinla C.E.

8. Italy. Mẹtalọkan, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kẹẹdogun C.E.

9. Germany. Mẹtalọkan, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun kọkandinlogun C.E.

10. Germany. Mẹtalọkan, nǹkan bii ọgọrun-un ọdun ogún C.E.