Àkàwé Nipa Mina
Orí 100
Àkàwé Nipa Mina
BOYA Jesu ṣì wà ní ilé Sakeu sibẹ, níbi tí oun ti dúró lójú ọ̀nà rẹ̀ sí Jerusalẹmu. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbàgbọ́ pe nigba ti awọn bá dé Jerusalẹmu, oun yoo polongo pe oun ni Mesaya naa yoo sì gbé Ijọba rẹ̀ kalẹ̀. Lati ṣàtúnṣe èrò ọkàn yii ati lati fihan pe Ijọba naa ṣì jìnnà, Jesu fúnni ní àkàwé kan.
Ó sọ pe, “Ọkunrin ọlọ́lá kan re ìlú okeere lọ gba ijọba fun araarẹ̀, kí ó sì pada.” Jesu ní “ọkunrin ọlọ́lá” naa, ọ̀run sì ni “ìlú okeere” naa. Nigba ti ó bá dé ibẹ, Baba rẹ̀ yoo fi agbára ọba fun un.
Ṣaaju lílọ rẹ̀, bí ó ti wù kí ó rí, ọkunrin ọlọ́lá naa késí awọn ẹrú mẹ́wàá ó sì fun ọkọọkan ninu wọn ní mina fàdákà kan, ní wiwi pe: “Ẹ maa ṣòwò títí emi yoo fi dé.” Awọn ẹrú mẹ́wàá naa ninu ìmúṣẹ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ dúró fun awọn ọmọ-ẹhin Jesu ìjímìjí. Ninu ìfisílò tí ó gbòòrò, wọn ṣàpẹẹrẹ gbogbo awọn tí wọn fojúsọ́nà lati di ajogún pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba ọrun naa.
Awọn mina fàdákà naa jẹ́ awọn ègé owó ṣíṣeyebíye, tí ọkọọkan ninu wọn tó nǹkan bii owó-ọ̀yà oṣu mẹta fun àgbẹ̀ kan. Ṣugbọn ki ni awọn mina naa dúró fun? Irú òwò wo ni awọn ẹrú naa sì gbọdọ fi wọn ṣe?
Awọn mina naa dúró fun awọn ọrọ̀-ìní tí awọn ọmọ-ẹhin àfẹ̀míbí naa lè lò ni mímú awọn àjògún Ijọba ọrun pupọ sii jade títí di ìgbà dídé Jesu gẹgẹ bi Ọba ninu Ijọba tí a ṣèlérí naa. Lẹhin ajinde ati ìfarahàn rẹ̀ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó fún wọn ní awọn mina afàmìṣàpẹẹrẹ naa fun mímú ọmọ-ẹhin pupọ sii jáde kí wọn sì tipa bayii fikún ẹgbẹ́ Ijọba ọ̀run.
Jesu nbaa lọ pe, “Ṣugbọn awọn ọlọ̀tọ̀ ìlú rẹ̀ kórìíra [ọkunrin ọlọ́lá naa], wọn sì rán ikọ̀ tẹle e, wipe, Awa kò fẹ́ kí ọkunrin yii jọba lórí wa.” Awọn ọlọ̀tọ̀ ìlú naa ni awọn ọmọ Isirẹli, tabi awọn Juu, láìní awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ninu. Lẹhin tí Jesu lọ sí ọrun, awọn Juu wọnyi sọ ọ́ di mímọ̀ pe awọn kò fẹ́ ẹ lati jẹ́ ọba wọn nipasẹ ṣíṣe inúnibíni sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ní ọ̀nà yii wọn ńhùwà gẹgẹ bi awọn ọlọ̀tọ̀ ìlú tí wọn rán ẹgbẹ́ awọn ikọ̀ naa jáde.
Bawo ni awọn ẹrú mẹ́wàá naa ṣe lò awọn mina wọn? Jesu ṣàlàyé pe: “Ó sì ṣe, nigba ti ó gba ijọba tán, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pe, kí a pe awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọnni wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí oun ti fi owó fun nitori kí ó lè mọ̀ iye èrè tí olukuluku fi ìṣòwò jẹ. Eyi ekinni sì wá, ó wipe, Oluwa, mina rẹ jèrè mina mẹ́wàá sii. Ó sì wí fun un pe, O ṣeun, iwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere: nitori tí iwọ ṣe olóòótọ́ ní ohun kíkinní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá. Eyi ekeji sì wá, ó wipe, Oluwa, mina rẹ jèrè mina márùn-ún. Ó sì wí fun un pẹlu pe, Iwọ joyè ìlú márùn-ún.”
Ẹrú tí ó ní mina mẹ́wàá naa ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́, tabi àwùjọ, awọn ọmọ-ẹhin lati Pẹntikọsi 33 C.E. títí di isinsinyi eyi ní awọn apọsiteli nínú. Ẹru tí ó jèrè mina márùn-ún pẹlu tún dúró fun àwùjọ kan láàárín àkókò kan naa tí, ní ìbámu pẹlu awọn anfaani ati agbára wọn, wọn mú ọrọ̀ ọba wọn pọ̀sí i lórí ilẹ̀-ayé. Awọn àwùjọ mejeeji fi taratara waasu ihinrere naa, ati gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, ọpọlọpọ awọn eniyan ọlọ́kàn títọ́ di Kristẹni. Mẹ́sàn-án ninu awọn ẹrú naa ṣe òwò tí ó yọrísírere tí wọn sì mú ìní wọn pọ̀sí i.
Jesu ńbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pe, “Ṣugbọn òmíràn sì wá, ó wipe, Oluwa, wò mina rẹ tí nbẹ ní ọwọ́ mi tí mo dì sínú gèlè: nitori mo bẹru rẹ, ati nitori tí iwọ ṣe òǹrorò eniyan: iwọ a maa mú eyi tí iwọ kò fi lélẹ̀, iwọ a sì maa ká eyi tí iwọ kò gbìn. Ó sì wí fun un pe, Ni Ẹnu araàrẹ naa ni emi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, iwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ buburu. Iwọ mọ̀ pe òǹrorò eniyan ni mí, pe, emi a maa mú eyi tí emi kò filélẹ̀ emi a sì maa ká eyi tí emi kò gbìn; èéhasìtiṣe tí iwọ kò fi owó mi sí ilé èlé, nigba tí mo bá dé, emi ìbá sì beere rẹ̀ ti oun ti èlé? Ó sì wí fun awọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pe, Ẹ gba mina naa lọwọ rẹ̀, kí ẹ sì fi i fun ẹni tí ó ni mina mẹ́wàá.”
Pípàdánù mina afàmìṣapẹẹrẹ naa tumọsi pipadanu ibikan ninu Ijọba ọrun fun ẹrú buburu naa. Bẹẹni, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe ó jẹ́, oun pàdánù àǹfààní ṣíṣàkóso lórí awọn ìlú mẹ́wàá tabi ìlú márùn-ún. Kiyesii, pẹlu, pe a kò pe ẹrú naa ní ẹni buruku fun ìwà buruku kankan tí ó hù ṣugbọn, kàkà bẹẹ, fun kíkùnà lati ṣiṣẹ́ fun ìbísí ọlà ijọba ọ̀gá rẹ̀.
Nigba ti a fi mina ẹrú buburu naa fun ẹrú àkọ́kọ́, àtakò yii ni a ṣe: “Oluwa, ó ní mina mẹ́wàá!” Sibẹ, Jesu dahun pe: “Ẹnikẹni tí ó ní, ni a o fifún; ati lọdọ ẹni tí kò ní, eyi naa tí oun ní ni a o gbà lọwọ rẹ̀. Ṣugbọn awọn ọ̀tá mi wọnni, tí kò fẹ́ kí emi kí ó jọba lórí wọn, ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọn niwaju mi.” Luuku 19:11-27; Matiu 28:19, 20.
▪ Ki ni ó ru àkàwé Jesu nipa awọn mina naa jáde?
▪ Ta ni ọkunrin ọlọ́lá naa, ilẹ̀ wo ni oun sì lọ?
▪ Ta ni awọn ẹrú naa, ki ni ohun tí awọn mina naa sì dúró fun?
▪ Ta ni awọn ọlọ̀tọ̀ ìlú naa, bawo ni wọn sì ṣe fi ìkórìíra wọn hàn?
▪ Eeṣe tí a fi pe ẹrú kan ní ẹni buburu, kí sì ni ìpàdánù mina rẹ̀ tumọsi?