Ìgbìdánwò Siwaju Sii Lati Pa Jesu
Orí 81
Ìgbìdánwò Siwaju Sii Lati Pa Jesu
NIWỌN bi ó ti jẹ́ ìgbà òtútù, Jesu ńrìn ni àyíká tí ó ni òrùlé tí a mọ̀ sí ìloro Solomoni. Ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹmpili naa. Níhìn-ín ni awọn Juu ti yí i ká tí wọn sì bẹrẹsii sọ pe: “Iwọ yoo ti mú ọkàn wa wà ninu àìdánilójú pẹ́ tó? Bí iwọ bá ni Kristi naa, sọ fun wa ṣàkó.”
“Mo ti sọ fun yin,” ni Jesu fèsì padà, “sibẹ ẹyin kò sì gbàgbọ́.” Jesu kò sọ fun wọn ní tààràtà pe oun ni Kristi naa, gẹgẹ bi ó ti sọ fun obinrin ara Samaria naa ní ibi kàǹga. Sibẹ, niti tootọ, oun ti ṣí ẹni tí oun jẹ́ payá nigba ti ó ṣàlàyé fun wọn pe oun wá lati ilẹ̀ àkóso lókè ati pe oun ti wà ṣaaju Aburahamu.
Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, ńfẹ́ kí awọn ènìyàn dé ìparí èrò naa fúnraawọn pe oun ni Kristi nipa fífi awọn ìgbòkègbodò rẹ̀ wéra pẹlu ohun tí Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pe Kristi yoo ṣàṣeparí rẹ̀. Ìdí niyẹn tí oun fi pàṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣaaju lati maṣe sọ fun ẹnikẹni pe oun ni Kristi naa. Ìdí sì niyẹn tí oun nisinsinyi fi nbaa nìṣó lati sọ fun awọn Juu onínúfùfù wọnyi pe: “Awọn iṣẹ́ tí mo ńṣe ní orukọ Baba mi, iwọnyi ní ńjẹ́rìí nipa mi. Ṣugbọn ẹyin kò gbàgbọ́.”
Eeṣe tí wọn kò fi gbàgbọ́? Ó ha jẹ́ nitori àìsí ẹ̀rí pe Jesu jẹ́ Kristi naa ni bí? Bẹẹkọ, ṣugbọn nitori ìdí tí Jesu fifúnni nigba ti ó sọ fun wọn pe: “Ẹyin kò sí lára awọn àgùtàn mi. Awọn àgùtàn mi nfetisilẹ sí ohùn mi, emi sì mọ̀ wọn, wọn sì ńtọ̀ mi lẹhin. Emi sì fun wọn ní ìyè ainipẹkun, a kì yoo sì pa wọn run lọnakọna lae, kò sì sí ẹnikankan tí yoo já wọn gbà kuro ní ọwọ́ mi. Ohun tí Baba mi ti fun mi jẹ́ ohun tí ó tóbi ju gbogbo nǹkan miiran lọ, kò sì sí ẹnikankan tí ó lè já wọn gbà kuro ní ọwọ́ Baba.”
Jesu nigba naa ṣàpèjúwe ìbátan rẹ̀ tímọ́tímọ́ pẹlu Baba rẹ̀, ní ṣíṣàlàyé pe: “Ọ̀kan ni emi ati Baba jẹ́.” Niwọn bi Jesu ti wà lórí ilẹ̀-ayé tí Baba rẹ̀ sì wà ní ọ̀run, ní kedere kii ṣe pe ó ńsọ pe oun ati Baba rẹ̀ niti tootọ gan-an, tabi niti ara ìyára, jẹ́ ọ̀kan. Kàkà bẹẹ, ó ní in lọ́kàn pe wọn jẹ́ ọ̀kan ninu ète, pe wọn wà ní ìṣọ̀kan.
Bí inu ti bí wọn nipasẹ awọn ọ̀rọ̀ Jesu, awọn Juu he òkúta lati pa á, kódà gẹgẹ bi wọn ti ṣe ṣaaju, lakooko Àjọ-àríyá awọn Àgọ́-ìsìn, tabi Àtíbàbà. Pẹlu igboya Jesu dojúkọ awọn tí o fẹ́ lati ṣìkàpa á, o sì wipe: “Mo fi ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere lati ọ̀dọ̀ Baba hàn yin. Nitori ewo ninu iṣẹ́ wọnni ni ẹyin ṣe ńsọ mi ní òkúta?”
“Awa ńsọ ọ ní òkúta, kii ṣe nitori iṣẹ́ rere,” ni wọn dáhùn, “bikoṣe nitori ọ̀rọ̀-òdì, àní pàápàá nitori, bí ó tilẹ jẹ́ pe ènìyàn ni ọ́, iwọ ńfi araàrẹ ṣe ọlọrun kan.” Niwọn bi Jesu kò ti sọ láé pe oun jẹ́ ọlọrun kan, eeṣe tí awọn Juu fi sọ eyi?
Lọna tí ó hàn gbangba ó jẹ́ nitori pe Jesu ka awọn agbára kan sí tirẹ̀ eyi tí wọn gbàgbọ́ pe wọn jẹ́ ti Ọlọrun nikanṣoṣo. Fun apẹẹrẹ, oun ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nipa “awọn àgùtàn,” “Emi sì fun wọn ní ìyè ainipẹkun,” ohun kan tí ẹ̀dá-ènìyàn eyikeyii kò lè ṣe. Awọn Juu, bí ó ti wù kí ó rí, gbójúfò òtítọ́ naa dá pe Jesu jẹ́wọ́ gbígba àṣẹ lati ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀.
Pe Jesu sọ pe oun kere sí Ọlọrun, ni oun fihàn lẹhin naa nipa bibeere pe: “A kò ha ti kọ ọ́ ninu Òfin yin [ní Saamu 82:6], ‘Mo wipe: “Awọn ọlọrun ni yin”’? Bí oun bá pe awọn wọnni ní ‘ọlọrun’ awọn ẹni tí ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá lòdìsí, . . . ẹyin ha wí fun mi ẹni tí Baba ti sọ di mímọ́ tí ó sì ti rán wá sínú ayé pe, ‘Iwọ ńsọ̀rọ̀ òdì,’ nitori mo wipe, Ọmọkunrin Ọlọrun ni mi?”
Niwọn bi Iwe Mimọ ti pe àní awọn ẹ̀dá-ènìyàn onídàájọ́ ti nlọ ẹjọ́ po pàápàá ní “awọn ọlọrun,” àríwísí wo ni awọn Juu wọnyi lè rí sí Jesu fun sísọ pe, “Ọmọkunrin Ọlọrun ni mi”? Jesu fikun un pe: “Bí emi kò bá ńṣe awọn iṣẹ́ Baba mi, ẹ maṣe gbà mi gbọ́. Ṣugbọn bí emi bá ńṣe wọn, àní bí ẹyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gba awọn iṣẹ́ naa gbọ́, kí ẹyin kí ó lè wá mọ̀ kí ẹ sì maa baa lọ ní mímọ̀ pe Baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu mi emi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Baba.”
Nigba ti Jesu sọ eyi, awọn Juu gbìyànjú lati fipá mú un. Ṣugbọn oun sá àsálà, gẹgẹ bi oun ti ṣe ṣaaju ní Àjọ-àríyá awọn Àgọ́-ìsìn. O fi Jerusalẹmu sílẹ̀ ó sì rin ìrìn àjò rékọjá Odò Jọdani lọ sí ibi tí Johanu ti bẹrẹsii baptisi ní eyi tí ó fẹrẹẹ tó ọdun mẹrin ṣaaju. Lọna ti o han gbangba ibi yii kò jìnnà sí ìhà-guusu etíkun Òkun Galili, nǹkan bíi ìrìn àjò ọjọ́ méjì lati Jerusalẹmu.
Ọpọlọpọ ènìyàn wá sọ́dọ̀ Jesu ní ibi yii wọn sì bẹrẹsii sọ pe: “Johanu, nitootọ, kò ṣe iṣẹ́-àmì ẹyọ kan, ṣugbọn gẹgẹ bi ohun tí Johanu sọ nipa ọkunrin yii ti pọ̀ tó òótọ́ ni gbogbo wọn.” Nipa bayii ọpọlọpọ ènìyàn fi ìgbàgbọ́ han ninu Jesu níhìn-ín. Johanu 10:22-42; 4:26; 8:23, 58; Matiu 16:20, NW.
▪ Ọ̀nà wo ni Jesu gba fẹ́ kí awọn ènìyàn mọ̀ oun gẹgẹ bi Kristi naa?
▪ Bawo ni Jesu ati Baba rẹ̀ ṣe jẹ́ ọ̀kan?
▪ Lọna tí ó hàn gbangba, eeṣe tí awọn Juu fi sọ pe Jesu ńfi araarẹ̀ ṣe ọlọrun kan?
▪ Bawo ni ọ̀rọ̀ tí Jesu fàyọ lati inú Saamu ṣe fihàn pe kò sọ pe oun bá Ọlọrun dọ́gba?