Ìrìn Àjò Bòókẹ́lẹ́ kan sí Jerusalẹmu
Orí 65
Ìrìn Àjò Bòókẹ́lẹ́ kan sí Jerusalẹmu
ÓJẸ́ ìgbà ìkórè 32 C.E., Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn sì sunmọtosi. Jesu ti fi pupọ julọ ninu ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ sí Galili lati ìgbà Irekọja 31 C.E., nigba ti awọn Juu gbìyànjú lati pa á. Ó jọ bí ẹni pe, lati ìgbà naa Jesu bẹ Jerusalẹmu wò kìkì lati pésẹ̀ sí awọn àjọ-àríyá mẹta ọdọọdun ti awọn Juu.
Awọn arakunrin Jesu nisinsinyi rọ̀ ọ́ pe: “Lọ kúrò níhìn-ín kí o sì lọ sí Judia.” Jerusalẹmu ni lájorí ìlú-ńlá Judia ati ìkòríta ìsìn fun gbogbo orilẹ-ede naa. Awọn arakunrin rẹ̀ ronú pe: “Kò sí ẹnikẹni tí ńṣe ohunkohun níkọ̀kọ̀, tí oun tikaraarẹ sì ńfẹ́ kí a mọ̀ ọ́n ní gbangba.”
Bí ó tilẹ jẹ́ pe Jakọbu, Simoni, Josẹfu, ati Judasi kò gbàgbọ́ pe arakunrin wọn àgbà, Jesu, ni Mesaya naa niti tòótọ́, wọn fẹ́ kí ó fi awọn agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn fun gbogbo awọn wọnni tí wọn pésẹ síbi àjọ-àríyá naa. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, mọ ewu naa lẹkun-unrẹrẹ. “Ayé kò lè kórìíra yin,” ni ó wí, “ṣugbọn emi ni ó kórìíra, nitori ti mo jẹ́rìí gbè é pe, iṣẹ́ rẹ̀ burú.” Nitori naa Jesu sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ pe: ‘Ẹyin ẹ gòkè lọ sí àjọ yii; emi kò tíì ni gòkè lọ sí àjọ yii.’
Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn jẹ́ àṣeyẹ ọlọ́jọ́ meje kan. A mú un wá sí ìparí pẹlu awọn ìgbòkègbodò aláyẹyẹ ìsìn ní ọjọ kẹjọ. Àjọ-àríyá naa sàmìsí òpin ọdun iṣẹ́ ọ̀gbìn tí ó sì jẹ́ àkókò ayọ̀ ati ọpẹ gidigidi. Awọn ọjọ melookan lẹhin tí awọn arakunrin Jesu ti lọ lati pésẹ̀ papọ̀ pẹlu ògìdìgbó awọn arìnrìn àjò naa, oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ ní bòókẹ́lẹ́, ní ṣíṣàì jẹ ki pupọ eniyan ri i. Wọn bá ọ̀nà tí ó gba àárín Samaria lọ, dípò eyi tí pupọ awọn eniyan ńgbà nítòsí Odò Jọdani.
Niwọn bi Jesu ati ẹgbẹ́ rẹ̀ yoo ti nílò ilé ìbùwọ̀ ní abúlé Samaria kan, oun rán awọn ońṣẹ́ ṣaaju lati ṣe awọn ìmúrasílẹ̀. Awọn eniyan naa, bí ó ti wù kí ó rí, kọ̀ lati ṣe ohunkohun fun Jesu lẹhin tí wọn ti gbọ́ pe oun forílé Jerusalẹmu. Pẹlu ibinu, Jakọbu ati Johanu beere pe: “Oluwa, iwọ ko jẹ kí awa pe iná lati ọ̀run wá, kí a sun wọn lúúlúú.” Jesu bá wọn wí lọna lílekoko fun dídámọ̀ràn irú ohun bẹẹ, wọn sì kọja lọ sí abúlé miiran.
Bí wọn ti ńrìn lọ ní ojú ọ̀nà, akọwe ofin kan sọ fun Jesu pe: “Oluwa, emi nfẹ lati maa tọ̀ ọ́ lẹhin níbikíbi tí iwọ ńlọ.”
“Awọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, awọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́,” ni Jesu fèsìpadà, “ṣugbọn Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] eniyan kò ní ibi tí yoo gbé fi orí rẹ̀ lé.” Jesu ńṣàlàyé pe akọwe ofin naa yoo ní ìrírí ìnira bí ó bá di ọmọlẹhin Oun. Ó sì jọ pe ohun tí ó dọ́gbọ́n túmọ̀sí ni pe akọwe ofin naa ti gbéraga jù lati tẹ́wọ́gbà irú ọ̀nà igbesi-aye yii.
Sí ọkunrin miiran, Jesu wipe: “Maa tọ̀ mi lẹ́hìn.”
“Jẹ́ kí emi kí ó kọ lọ sìnkú baba mi ná,” ni ọkunrin naa dáhùn.
“Jẹ́ kí awọn òkú kí ó maa sìnkú araawọn,” ni Jesu fèsìpadà, ‘ṣugbọn iwọ lọ kí o sì maa waasu ijọba Ọlọrun kaakiri.’ O han kedere pe baba ọkunrin naa kò tíì kú sibẹ, nitori pe bí ó bá ti ṣe bẹẹ ni, kì yoo ṣeeṣe fun ọmọkunrin rẹ̀ lati maa fetisilẹ sí Jesu nihin-in. Ọmọkunrin naa lọna híhàn gbangba nbeere fun àkókò lati dúró de ikú baba rẹ̀. Oun kò múratán lati fi Ijọba Ọlọrun si ipo akọkọ ninu igbesi-aye rẹ̀.
Bí wọn ti ntẹsiwaju lójú ọ̀nà lọ sí Jerusalẹmu, ọkunrin miiran sọ fun Jesu pe: “Oluwa, emi fẹ́ lati maa tọ̀ ọ́ lẹhin; ṣugbọn jẹ́ kí emi kí ó padà lọ dágbáre fun awọn ara ilé mi.”
Ní ìdáhùn Jesu wipe: “Kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èèlò ìtúlẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀hìn, tí ó yẹ fun ijọba Ọlọrun.” Awọn wọnni tí yoo jẹ́ awọn ọmọ-ẹhin Jesu gbọdọ jẹ́ kí ojú ìríran wọn kóríjọ sí ọ̀gangan iṣẹ́-ìsìn Ijọba. Gan-an gẹgẹ bi o ti ṣeeṣe ki aporo kan wọ́ bí atúlẹ̀ naa kò bá tẹjumọ ọ̀kánkán rẹ̀, bẹẹ naa ni ẹnikẹni tí ó bá ńbojúwẹ̀hìn wo ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ògbólógbòó yii ṣe lè kọsẹ̀ kuro lójú ọ̀nà tí ó nsinni lọ sí ìyè ainipẹkun. Johanu 7:2-10; Luuku 9:51-62; Matiu 8:19-22.
▪ Awọn wo ni arakunrin Jesu, bawo ni wọn sì ṣe nímọ̀lára nipa rẹ̀?
▪ Eeṣe tí awọn ara Samaria fi jẹ́ alárìífín tobẹẹ, kí sì ni ohun tí Jakọbu ati Johanu fẹ́ lati ṣe?
▪ Awọn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ mẹta wo ni Jesu ní lójú ọ̀nà, bawo ni oun sì ṣe tẹnumọ́ àìní naa fun iṣẹ́-ìsìn ìfara-ẹni rúbọ?