Awọn Àkàwé Ọgbà Àjàrà Tú Wọn Fó
Orí 106
Awọn Àkàwé Ọgbà Àjàrà Tú Wọn Fó
JESU wà ní tẹmpili. Oun ṣẹ̀ṣẹ̀ kó ìdààmú bá awọn aṣaaju-isin ti wọn nfi dandangbọ̀n béèrè nipa ọlá-àṣẹ ẹni ti oun fi ńṣe awọn nǹkan. Ṣaaju kí wọn tó bọ́ kuro ninú ìdàrúdàpọ̀ wọn, Jesu beere pe: “Ki ni ẹyin rò?” Ati pe lẹhin naa nipasẹ àkàwé kan, ó fihàn wọn irú eniyan tí wọn jẹ́ niti gidi.
“Ọkunrin kan ní ọmọ meji,” ni Jesu sọ. “Ní lílọ sọ́dọ̀ ekinni, ó wipe, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lonii ninu ọgbà àjàrà.’ Ní ìdáhùn eleyii wipe, ‘Emi yoo lọ, baba,’ ṣugbọn kò jade lọ. Ní títọ ekeji lọ, ó wí nǹkan kan naa. Ní ìfèsìpadà eleyii wipe, ‘Emi kì yoo lọ.’ Lẹhin ìgbà naa ó kábàámọ̀ ó sì jade lọ. Ewo ninu awọn mejeeji ni ó ṣe ìfẹ́-inú baba rẹ̀?” ni Jesu beere.
“Ekeji,” ni awọn alatako rẹ̀ dáhùn.
Nitori naa Jesu ṣàlàyé pe: “Lóòótọ́ ni mo wí fun yin pe awọn agbowó-orí ati awọn aṣẹ́wó ńlọ ṣiwaju yin sínú ijọba Ọlọrun.” Awọn agbowó-orí ati awọn aṣẹ́wó niti tootọ, kọ̀ lati ṣiṣẹ́sìn Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀. Ṣugbọn lẹhin naa, gẹgẹ bi ọmọ keji, wọn ronúpìwàdà wọn sì ṣiṣẹ́sìn ín. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn aṣaaju isin, bi ọmọ àkọ́kọ́, jẹ́wọ́ pe awọn ńṣiṣẹ́sìn Ọlọrun, sibẹsibẹ, gẹgẹ bi Jesu ti sọ: “Johanu [Arinibọmi] wá sọ́dọ̀ yin ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹyin kò gbà á gbọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn agbowó-orí ati awọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́, ati ẹyin, bí ó tilẹ jẹ́ pe ẹyin rí eyi, kò kábàámọ̀ lẹhin ìgbà naa kí ẹ baa lè gbà á gbọ́.”
Tẹle eyi Jesu fihàn pe ìkùnà awọn aṣaaju-isin wọnyi kìí wulẹ ṣe ṣíṣàì fẹ́ ṣiṣẹ́sìn Ọlọrun. Bẹẹkọ, ṣugbọn wọn jẹ́ olubi niti tootọ, awọn eniyan buruku. “Ọkunrin kan wà, baálé ilé kan,” ni Jesu sọ, “ẹni tí ó gbìn ọgbà àjàrà kan tí ó sì sọ ọgbà yí i ká ó sì wá ilẹ̀ ìfúntí kan sínú rẹ̀ ó sì gbé ilé-ìṣọ́ kan nàró, ó sì fi i háyà fun awọn aroko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀. Nigba ti àsìkò awọn èso dé, ó rán awọn ẹrú rẹ̀ lọ kíákíá sọ́dọ̀ awọn aroko naa lati gba awọn èso rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn aroko naa mú awọn ẹrú rẹ̀, wọn sì lù ọ̀kan, wọn pa òmíràn, wọn sọ òmíràn lókùúta. Ó tún ran awọn ẹrú miiran lọ, tí wọn pọ̀ ju ti àkọ́kọ́, ṣugbọn wọn ṣe bakan naa sí awọn wọnyi.”
“Awọn ẹrú” naa ni awọn wolii tí “baálé ilé” naa, Jehofa Ọlọrun, rán sí “awọn aroko” “ọgbà àjàrà” rẹ̀. Awọn aroko wọnyi jẹ́ awọn aṣaaju aṣoju orílẹ̀-èdè Isirẹli, orílẹ̀-èdè tí Bibeli fihàn gẹgẹ bi “ọgbà àjàrà” Ọlọrun.
Niwọn bi “awọn aroko” naa ti fojú “awọn ẹrú” wọnyi gbolẹ̀ tí wọn sì pa wọn, Jesu ṣàlàyé pe: “Ni ìgbẹ̀hìn [ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà naa] rán ọmọkunrin rẹ̀ sí wọn kiakia, ní wiwi pe, ‘Wọn yoo bọ̀wọ̀ fun ọmọkunrin mi.’ Nigba tí wọn rí ọmọkunrin naa awọn aroko naa wí láàárín araawọn pe, ‘Eyi ni ajogún; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á kí a sì gba ogún rẹ̀!’ Nitori naa wọn mú un wọn sì sọ ọ́ sóde ọgbà àjàrà naa wọn sì pa á.”
Nisinsinyi, ní sísọ̀rọ̀ tààràtà sí awọn aṣaaju-isin naa, Jesu beere pe: “Nigba ti ẹni tí ó ní ọgbà àjàrà naa bá dé, ki ni yoo ṣe fun awọn aroko wọnni?”
“Nitori pe wọn jẹ́ olubi,” ni awọn aṣaaju isin wọnni dáhùn, “oun yoo mú ìparun ibi wá sórí wọn yoo sì fi ọgbà àjàrà naa háyà fun awọn aroko miiran, awọn tí yoo fun un ní awọn èso nigba ti àkókò wọn bá tó.”
Awọn aṣaaju-isin naa nipa bayii pòkìkí ìdájọ́ sórí araawọn láìmọ̀, niwọn bi wọn ti wà lára awọn ọmọ Isirẹli “aroko” orílẹ̀-èdè Jehofa, “ọgbà àjàra” ti Isirẹli. Èso tí Jehofa reti lati ọ̀dọ̀ awọn aroko naa ni ìgbàgbọ́ ninu Ọmọkunrin rẹ̀, Mesaya tootọ naa. Nitori ìkùnà wọn lati pèsè irúfẹ́ èso bẹẹ, Jesu kìlọ̀ pe: “Ẹyin kò ha kà ninu Iwe Mimọ [ní Saamu 118:22, 23] pe, ‘Òkúta tí awọn ọ̀mọ̀lé ṣátì ni eyi tí ó ti di pàtàkì òkúta igun ilé. Lati ọ̀dọ̀ Jehofa ni eyi ti ṣẹlẹ̀, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’? Eyi ni ìdí tí mo fi wí fun yin pe, A ó gba ijọba Ọlọrun lọwọ yin a ó sì fi i fun orílẹ̀-èdè kan tí yoo maa mú awọn èso rẹ̀ wá. Pẹlupẹlu, eniyan tí ó bá ṣubú lù òkúta yii ni a ó fọ́ túútúú. Ẹnikẹni tí ó bá sì ṣubú lù, yoo lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
Awọn akọwe ofin ati awọn olórí alufaa wá mọ̀ nisinsinyi pe Jesu ńsọ̀rọ̀ nipa wọn, wọn sì fẹ́ lati pa á, “àjogún” títọ̀nà naa. Nitori naa àǹfààní jíjẹ́ awọn olùṣàkóso ninu Ijọba Ọlọrun ni a ó gbà kuro lọwọ wọn gẹgẹ bi orílẹ̀-èdè kan, orílẹ̀-èdè ‘awọn aroko ọgbà àjàrà,’ titun kan, ọ̀kan tí yoo maa mú awọn èso yíyẹ jáde ni a o sì dá silẹ.
Nitori awọn aṣaaju-isin naa bẹ̀rù awọn ogunlọgọ, tí wọn ka Jesu sí wolii kan, wọn kò gbìyànjú lati pa á ní àkókò yii. Matiu 21:28-46, NW; Maaku 12:1-12; Luuku 20:9-19; Aisaya 5:1-7.
▪ Awọn wo ni awọn ọmọ meji naa ninu àkàwé àkọ́kọ́ Jesu naa dúró fun?
▪ Ninu akawe keji, ta ni “baálé ilé,” “ọgbà àjàrà,” “awọn aroko,” “awọn ẹrú,” ati “ajogún” naa dúró fún?
▪ Ki ni yoo ṣẹlẹ̀ sí ‘awọn aroko ọgbà àjàrà’ naa, awọn wo ni yoo sì rọ́pò wọn?