Awọn Ìṣù Burẹdi ati Ìwúkàrà
Orí 58
Awọn Ìṣù Burẹdi ati Ìwúkàrà
OGUNLỌGỌ nla eniyan ti wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu ní Dekapolisi. Ọpọlọpọ ni ó wá lati ọna jinjin sí ẹkùn-ilẹ̀ yii tí ó jẹ kiki awọn Keferi ni wọn ngbe ibẹ lati fetisilẹ sí i kí wọn sì rí ìmúláradá gbà kuro ninu awọn àìlera wọn. Wọn ti mú awọn apẹ̀rẹ̀ títóbi, tabi awọn agbọ̀n, wá pẹlu wọn, tí wọn ńlò gẹgẹ bi àṣà lati maa gbé awọn ìpèsè nigba ti wọn bá ńrìnrìn àjò la awọn àgbègbè Keferi kọja.
Nigba ti o ya, bí ó ti wù kí ó rí, Jesu pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ó sì wipe: “Mo kaaanu fun ogunlọgọ naa, nitori o ti di ọjọ mẹta nisinsinyi tí wọn ti wà nitosi mi wọn kò sì ní ohunkohun lati jẹ; bi mo sì nilati ran wọn lọ sí ile wọn ni gbigbaawẹ, wọn yoo dákú ni oju ọna. Nitootọ, awọn kan ninu wọn wá lati ọ̀nà jínjìn.”
“Lati ibo ni ẹnikẹni nihin-in ni ibi àdádó kan ti le fi awọn iṣu burẹdi bọ́ awọn eniyan wọnyi yó?” ni awọn ọmọ-ẹhin beere.
Jesu wádìí pe: “Awọn ìṣù burẹdi meloo ni ẹyin ní?”
“Méje,” ni wọn dáhùn, ‘pẹlu awọn ẹja kéékèèké diẹ.’
Ní fífún awọn eniyan naa ní ìtọ́ni lati rọ̀gbọ̀kú sori ilẹ, Jesu mú awọn ìṣù burẹdi naa ati awọn ẹja, ó gbàdúrà sí Ọlọrun, ó bù ú, ó sì bẹrẹsii fi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Awọn, lẹhin naa, pín in fun awọn eniyan naa, tí gbogbo wọn sì jẹun yó dáradára. Lẹhin eyi, nigba ti a kó awọn àjẹkù jọ, agbọ̀n ìpèsè meje tí ó kún bámúbámú ni a rí, bí ó tilẹ jẹ́ pe nǹkan bii 4,000 awọn géńdé ọkunrin, awọn obinrin ati awọn ọmọde bakan naa, ni wọn ti jẹun!
Jesu rán awọn ogunlọgọ naa lọ, ó wọ inú ọkọ̀ ojú-omi kan pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wọn sì sọdá sí èbúté ìwọ̀-oòrùn Òkun Galili. Nibi yii ni awọn Farisi, tí awọn mẹmba ẹ̀yà-ìsìn awọn Sadusi bá a rìn lọ́tẹ̀ yii, gbìyànjú lati dẹ Jesu wò nipa bibeere lọwọ rẹ̀ pe kí ó fi àmì kan hàn lati ọ̀run.
Ní mímọ ìsapá wọn lati dan an wò Jesu fèsì pe: “Nigba ti alẹ́ bá lẹ́ ó ti mọ yin lára lati wipe, ‘Ojú-ọjọ́ yoo dára, nitori ojú-ọ̀run pọ́n bí iná,’ ati ní òwúrọ̀, ‘Òtútù yoo mú, òjò yoo rọ̀ lonii, nitori ojú-ọ̀run pọ́n bí iná, ṣugbọn ó ṣúdùdù.’ Ẹyin mọ bí a ṣe ńtúmọ̀ ìrísí ojú-ọ̀run, ṣugbọn awọn àmì awọn àkókò ni ẹyin kò lè túmọ̀.”
Pẹlu iyẹn, Jesu pè wọn ní ìran ènìyàn buruku ati panṣágà ó sì kìlọ̀ fun wọn, gẹgẹ bi oun ti ṣe fun awọn Farisi ṣaaju pe, kò sí àmì kankan tí a o fifún wọn àyàfi ti Jona. Ní lílọkúrò, oun ati awọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi kan wọn sì forílé ìhà Bẹtisaida ní èbúté àríwá ìlà-oòrùn Òkun Galili. Ní ojú-ọ̀nà ni awọn ọmọ-ẹ̀hìn ti ríi pe wọn ti gbàgbé lati mú burẹdi lọwọ, ìṣù kanṣoṣo ni ó wà láàárín wọn.
Níní ìkólójú rẹ̀ aipẹ yii pẹlu awọn Farisi ati awọn alátìlẹhìn Hẹrọdu tí wọn jẹ́ Sadusi lọ́kàn, Jesu fúnni ní ìṣílétí yii: “Ẹ maa ṣọ́ra gidigidi kí ẹ sì ṣọ́ra fun ìwúkàrà awọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.” Lọna tí ó hàn gbangba, ìmẹ́nukàn ìwúkàrà mú kí awọn ọmọ-ẹ̀hìn naa ronú pe Jesu ńtọ́kasí gbígbàgbé tí wọn gbàgbé lati mú burẹdi lọwọ, nitori naa wọn bẹrẹsii jiyàn lórí ọ̀ràn naa. Ní ṣíṣàkíyèsí àìlóye wọn, Jesu wipe: “Eeṣe tí ẹ fi ńjiyàn lórí pe ẹ kò ní burẹdi?”
Laipẹ yii, Jesu pèsè burẹdi lọna iṣẹ́-ìyanu fun ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ó mú iṣẹ́-ìyanu tí ó kẹhin yii ṣe boya ní ọjọ kan tabi meji sẹ́hìn. Ó yẹ kí wọn mọ̀ pe kò dàníyàn nipa àìsí awọn ìṣù burẹdi gidi. “Ẹyin kò ha ranti,” ni oun ran wọn létí, “nigba ti mo bù ìṣù burẹdi márùn-ún fun ẹgbẹrun márùn-ún awọn eniyan, awọn agbọ̀n àjẹkù meloo ni ẹ kójọ?”
“Mejila,” ni wọn fèsì.
“Nigba ti mo bù meje naa fun ẹgbẹrun mẹrin eniyan, awọn agbọ̀n ìpèsè awọn àjẹku meloo ni ẹ kójọ?”
“Meje,” ni wọn dáhùn.
“Ẹyin kò ha mọ̀ ìtumọ̀ naa sibẹsibẹ?” ni Jesu beere. “Bawo ni ó ti jẹ́ tí ẹ kò fi wòyemọ̀ pe emi kò sọ̀rọ̀ fun yin nipa awọn ìṣù burẹdi? Ṣugbọn ẹ ṣọ́ra fun ìwúkàrà awọn Farisi ati awọn Sadusi.”
Awọn ọmọ-ẹ̀hìn lóye kókó ọ̀rọ̀ naa nikẹhin. Ìwúkàrà, ohun pàtàkì kan tí ó maa ńṣokùnfà kí nǹkan wú tí ó sì maa ńmú kí burẹdi dìde, jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí wọn ńlò lati ṣapẹẹrẹ ìsọdìbàjẹ́. Nitori naa nisinsinyi awọn ọmọ-ẹ̀hìn lóye pe Jesu nlo ìṣàpẹẹrẹ kan, pe oun kìlọ̀ fun wọn lati wà lójúfò lòdìsí “ẹ̀kọ́ awọn Farisi ati Sadusi,” awọn tí ẹ̀kọ́ wọn maa ńní ìyọrísí iṣẹ́ ìsọdìbàjẹ́. Maaku 8:1-21; Matiu 15:32–16:12, NW.
▪ Eeṣe tí awọn eniyan fi ní awọn agbọ̀n ìpèsè títóbi pẹlu wọn?
▪ Lẹhin fífi Dekapolisi silẹ, awọn ìrìn àjò wo ni Jesu rìn pẹlu ọkọ̀ ojú-omi?
▪ Àṣìlóye wo ni awọn ọmọ-ẹ̀hìn ní nipa gbolohun Jesu nipa ìwúkàrà?
▪ Ki ni Jesu nílọ́kàn nipa ọrọ naa “ìwúkàrà awọn Farisi ati Sadusi?”