Awọn Irin Ajo si Jerusalẹmu
Orí 10
Awọn Irin Ajo si Jerusalẹmu
ÌGBÀ ìrúwé ti dé. Akoko sì ti tó fun idile Josẹfu, papọ pẹlu awọn ọ̀rẹ́ ati awọn ibatan, lati rin irin ajo wọn ìgbà ìrúwé ọdọọdun lọ si Jerusalẹmu lati lọ ṣe ayẹyẹ Irekọja. Bi wọn ṣe bẹrẹ irin ajo ti o tó nǹkan bii 65 ibusọ, wọn kún fun idunnu bi o ti saba maa nri. Jesu nisinsinyi jẹ́ ọmọ ọdun 12, o sì fojusọna pẹlu ifẹ ara ọtọ fun ajọdun naa.
Fun Jesu ati idile rẹ̀, Irekọja naa kò wulẹ jẹ́ ọran ọjọ kan lasan. Wọn tun duro fun ajọdun Akara Alaiwu ọlọjọ meje ti o tẹle e, eyi ti wọn kà sí apakan asiko Irekọja. Nitori idi eyi, gbogbo irin ajo naa lati ile wọn ní Nasarẹti, titi kan iduro wọn ni Jerusalẹmu, gba nǹkan bii ọsẹ meji. Ṣugbọn ní ọdun yii, nitori ohun kan ti o kan Jesu, o gbà ju bẹẹ lọ.
Iṣoro naa wá sí ojutaye nigba irin ajo pada wale lati Jerusalẹmu. Josẹfu ati Maria rò pe Jesu wà laaarin awujọ awọn ibatan ati awọn ọ̀rẹ́ ti wọn jọ nrin irin ajo papọ. Sibẹ oun kò farahan nigba ti wọn duro fun òru naa, wọn sì bẹrẹsii wá a kiri laaarin awọn arinrin ajo ẹlẹgbẹ wọn. Wọn kò rí i nibikibi. Nitori naa Josẹfu ati Maria rin gbogbo ọna pada si Jerusalẹmu lati lọ wá a kiri.
Fun odindi ọjọ kan ni wọn fi ńwá a kiri laisi aṣeyọri. Ni ọjọ keji wọn kò ri i bakan naa. Nikẹhin, ni ọjọ kẹta, wọn lọ si tẹmpili. Nibẹ, ninu ọkan lara awọn gbọngan, wọn rí Jesu ti o jokoo laaarin awọn olukọni Juu, ti o nfetisilẹ si wọn ti o sì nbeere awọn ibeere.
“Ọmọ, eeṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹẹ?” ni Maria beere. “Sawoo, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri.”
Ẹnu ya Jesu pe wọn kò mọ ibi ti wọn ti lè rí oun. “Eeṣe ti ẹyin fi nwa mi kiri?” ni oun beere. “Ẹyin kò mọ̀ pe emi kò lè ṣaima wà ni ibi iṣẹ Baba mi?”
Jesu kò lè loye idi rẹ̀ tí awọn òbí rẹ̀ kò fi lè mọ eyi. Lori eyi, Jesu pada si ile pẹlu awọn òbí rẹ̀ ti o sì nbaa lọ lati maa tẹriba fun wọn. O ntẹsiwaju niṣo ninu ọgbọ́n ati ninu ìdàgbà ti ara ati nini ojurere pẹlu Ọlọrun ati eniyan. Bẹẹni, lati ìgbà ọmọde rẹ̀ lọ, Jesu fi apẹẹrẹ rere lelẹ kii ṣe kiki ninu lilepa awọn anfaani ire tẹmi nikan ṣugbọn pẹlu ninu fifi ọ̀wọ̀ hàn fun awọn òbí rẹ̀. Luuku 2:40-52; 22:7.
▪ Irin ajo ìgbà ìrúwé wo ni Jesu maa nṣe deedee pẹlu idile rẹ̀, bawo ni o sì ti maa npẹ tó?
▪ Ki ni o ṣẹlẹ laaarin irin ajo tí wọn ṣe nigba ti Jesu jẹ ọmọ ọdun 12?
▪ Apẹẹrẹ wo ni Jesu fi lelẹ fun awọn èwe lonii?