Fífi Ilé Jairu Silẹ ati Pípadà Ṣèbẹ̀wò sí Nasarẹti
Orí 48
Fífi Ilé Jairu Silẹ ati Pípadà Ṣèbẹ̀wò sí Nasarẹti
ỌJỌ́ naa ti kún fọ́fọ́ fun Jesu—ìrìn àjò ojú-omi lati Dekapolisi, mímú obinrin naa tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láradá, ati jíjí ọmọbinrin Jairu dìde. Ṣugbọn ọjọ́ naa kò tíì parí. Ó hàn kedere pe bí Jesu ṣe fi ilé Jairu silẹ, awọn ọkunrin afọ́jú meji ntẹle e lẹhin, tí wọn ńkígbe pe: “Ṣàánú fun wa, Ọmọkunrin Dafidi.”
Nipa pípe Jesu ní “Ọmọkunrin Dafidi,” awọn ọkunrin wọnyi tipa bayii nsọ ìgbàgbọ́ jáde pe Jesu ni àjògún sí ìtẹ́ Dafidi, nipa bayii pe oun ni Mesaya tí a ṣèlérí naa. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, jọ bí ẹni pe ó ṣàìfiyèsí igbe wọn fun ìrànlọ́wọ́, boya lati dán ìtẹpẹlẹmọ́ wọn wò. Ṣugbọn awọn ọkunrin naa kò juwọsilẹ. Wọn tẹle Jesu lọ sí ibi tí ó ńgbé, nigba ti ó sì wọ inú ilé naa, wọn tẹle e wọlé.
Nibẹ ni Jesu ti beere pe: “Ẹyin ha ní ìgbàgbọ́ pe mo lè ṣe eyi?”
“Bẹẹni, Oluwa,” ni wọn dá a lóhùn pẹlu ìgbọ́kànlé.
Nipa bẹẹ, ní fífi ọwọ́ kan ojú ìríran wọn, Jesu wipe: “Gẹgẹ bi ìgbàgbọ́ yin ni kí ó ṣẹlẹ̀ sí yin.” Lójijì ni wọn riran! Jesu lẹhin naa pàṣẹ fun wọn lọna lílekoko pe: “Kí ẹ ríi pe ẹnikẹni kò mọ̀ nipa rẹ̀.” Ṣugbọn bí wọn ti kún fun ayọ̀, wọn ṣàìfiyèsí àṣẹ Jesu tí wọn sì ńsọ̀rọ̀ nipa rẹ̀ jákèjádò gbogbo ìgbèríko naa.
Gẹ́lẹ́ bí awọn ọkunrin wọnyi ti lọ kúrò, awọn eniyan gbé ọkunrin ti o ni ẹ̀mí-èṣù kan wọlé ẹni tí ẹ̀mí-èṣù ti gba agbára ọ̀rọ̀-sísọ rẹ̀. Jesu lé ẹ̀mí-èṣù naa jáde, tí ọkunrin naa sì bẹrẹsii sọ̀rọ̀ lọ́gán. Awọn ogunlọgọ naa ni ẹnu yà sí awọn iṣẹ́-ìyanu wọnyi, ní wiwi pe: “A kò rí ohunkohun tí ó dabi eyi rí ní Isirẹli.”
Awọn Farisi wà níbẹ̀ pẹlu. Wọn kò lè sẹ awọn iṣẹ́-ìyanu naa, ṣugbọn ninu àìgbàgbọ́ wọn burukú wọn ṣe àtúnsọ ẹ̀sùn wọn nipa orísun awọn iṣẹ́ alagbara ti Jesu nṣe, ní wiwi pe: “Nipasẹ alákòóso awọn ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ńlé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde.”
Ní kété lẹhin awọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Jesu padà sí ìlú-ìbílẹ̀ rẹ̀ Nasarẹti, ní àkókò yii pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ní nǹkan bi ọdun kan ṣaaju, oun ti ṣe ìbẹ̀wò sí sinagọgu tí ó sì kọ́ni nibẹ. Bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn eniyan naa ni ẹnu kọ́kọ́ yà sí awọn ọ̀rọ̀ wíwuni rẹ̀, wọn fi ìbínú hàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹhin ìgbà naa tí wọn sì gbìyànjú lati pa á. Nisinsinyi, pẹlu àánú, Jesu ṣe ìgbìdánwò miiran lati ran awọn aládùúgbò rẹ̀ tẹlẹri lọwọ.
Nigba tí ó ṣe pé ní awọn ibòmíràn awọn eniyan ńṣùrùbo Jesu, ó hàn gbangba pe kò rí bẹẹ níhìn-ín. Nitori naa, ní Sabaati, o lọ sí sinagọgu lati kọ́ni. Ọ̀pọ̀ lára awọn tí wọn gbọ́ ọ ni háà ṣe. “Nibo ni ọkunrin yii ti rí ọgbọ́n yii gbà ati iṣẹ́ agbára wọnyi?” ni wọn beere. “Eyi ha kọ́ ni ọmọkunrin gbẹ́nàgbẹ́nà naa? Kìí ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ńpè ní Maria, ati awọn arakunrin rẹ̀ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi? Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹlu wa? Nibo, nigba naa, ni ọkunrin yii ti rí gbogbo nǹkan wọnyi gbà?”
‘Jesu wulẹ jẹ́ ènìyàn àdúgbò kan lásán bii tiwa ni,’ ni wọn ronú. ‘Ní ìṣojú wa ni ó ti dàgbà, tí a sì mọ idile rẹ̀. Bawo ni ó ṣe lè jẹ́ Mesaya naa?’ Nipa bẹẹ, láìka gbogbo ẹ̀rí naa sí—ọgbọ́n ńlá ati awọn iṣẹ́-ìyanu rẹ̀—wọn ṣá a tì. Àní awọn ìbátan tirẹ̀ fúnraarẹ̀ pàápàá, nitori wọn sunmọ ọn timọtimọ, kọsẹ̀ lára rẹ̀, tí ó mú kí Jesu parí rẹ̀ sí pé: “A kò ṣàìbọlá fún wolii àfi ní ìpínlẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀ ati ninu ilé tirẹ̀ fúnraarẹ̀.”
Nitootọ, Jesu ṣe kàyéfì nipa àìní ìgbàgbọ́ wọn. Nipa bẹẹ oun kò ṣe awọn iṣẹ́ ìyanu kankan nibẹ yàtọ̀ sí fífi ọwọ́ lé awọn eniyan diẹ tí wọn jẹ́ aláìsàn kí ó sì mú wọn láradá. Matiu 9:27-34; 13:54-58; Maaku 6:1-6; Aisaya 9:7.
▪ Nipa pípe Jesu ní “Ọmọkunrin Dafidi,” ki ni awọn ọkunrin afọ́jú naa fihàn pe wọn gbàgbọ́?
▪ Àlàyé wo fun awọn iṣẹ́-ìyanu Jesu ni awọn Farisi fohùnṣọ̀kan lélórí?
▪ Eeṣe tí ó fi jẹ́ ìwà àánú fun Jesu lati padà lọ ran awọn wọnni tí nbẹ ní Nasarẹti lọwọ?
▪ Irú ìtẹ́wọ́gbani wo ni Jesu rígbà ní Nasarẹti, eesitiṣe?