Iṣẹ Iyanu Akọkọ Ti Jesu Ṣe
Orí 15
Iṣẹ Iyanu Akọkọ Ti Jesu Ṣe
OWULẸ ti di ọjọ kan tabi meji ti Anderu, Peteru, Johanu, Filipi, Nataniẹli, ati boya Jakọbu di awọn ọmọ-ẹhin akọkọ fun Jesu. Awọn wọnyi nisinsinyi wà ni oju ọna wọn sí ilé ni agbegbe Galili, nibi ti gbogbo wọn ti wá. Ibi ti wọn nlọ ni Kana, ilu ibilẹ Nataniẹli, ti ó wà ni aarin awọn oke ti kò jinna pupọ si Nasarẹti, nibi ti Jesu fúnraarẹ̀ gbé dàgbà. A ti pè wọn sí apejẹ igbeyawo kan ni Kana.
Iya Jesu pẹlu wá si ayẹyẹ igbeyawo naa. Gẹgẹ bi ọrẹ idile awọn ti ngbeyawo naa, o dabi ẹni pe Maria kopa ninu pipese fun aini awọn alejo. Nitori naa oun tètè kiyesi aito kan, eyi ti o sọ fun Jesu pe: “Wọn kò ní waini.”
Nigba ti Maria ṣe eyi, oun nipa bayii, ndabaa pe ki Jesu ṣe ohun kan nipa aisi ọti waini naa, Jesu lọ́ra lakọọkọ. “Ki ni ṣe temi tìrẹ, obinrin yii?” ni o beere. Gẹgẹ bi Ọba ti Ọlọrun yansipo, oun kii ṣe ẹni tí a gbọdọ dari ninu igbokegbodo iṣẹ rẹ̀ nipasẹ idile tabi awọn ọ̀rẹ́. Nitori naa Maria fi pẹlu ọgbọ́n fi ọran naa lé ọmọkunrin rẹ̀ lọwọ, ni wiwulẹ sọ fun awọn ti nṣe iranṣẹ pe: “Ohunkohun ti o ba wi fun yin, ẹ ṣe é.”
O dara, awọn iṣà omi mẹfa titobi ti a fi okuta ṣe wà nibẹ, ọkọọkan eyi ti o lè gba ju jáálá mẹwaa lọ. Jesu paṣẹ fun awọn ti wọn nṣe iranṣẹ pe: “Ẹ pọn omi kún ikoko wọnni.” Awọn iranṣẹ onitọọju naa sì pọn omi kún wọn dẹ́múdẹ́mú. Lẹhin naa ni Jesu wipe: “Ẹ bù ú jade nisinsinyi, kí ẹ sì gbé e tọ olori àsè lọ.”
Didara ti ọti waini naa dára wú olori àsè naa lori, laimọ pe nipasẹ iṣẹ iyanu ni a fi pese rẹ̀. O pe ọkọ iyawo, o si wipe: “Olukuluku eniyan maa kọ́ gbe waini rere kalẹ, nigba ti awọn eniyan bá sì mu yó tan, nigba naa ni o nmu eyi tí kò dara tobẹẹ wá; ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yii mọ́ titi o fi di isinsinyi.”
Iṣẹ iyanu akọkọ ti Jesu ṣe niyii, nigba tí wọn sì rí i, igbagbọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ titun ni a fun lokun. Lẹhin naa, pẹlu iya rẹ̀ ati awọn iyèkan rẹ̀, wọn rin irin ajo lọ sí ilu Kapanaomu nitosi Òkun Galili. Johanu 2:1-12.
▪ Nigba wo lakooko iṣẹ-ojiṣẹ Jesu ni ayẹyẹ igbeyawo ni Kana ṣẹlẹ?
▪ Eeṣe ti Jesu fi lodisi idabaa iya rẹ̀?
▪ Iṣẹ iyanu wo ni Jesu ṣe, ipa wo ni ó sì ni lori awọn ẹlomiran?