Ireti Ajinde
Orí 90
Ireti Ajinde
JESU dé níkẹhìn sí ẹ̀hìn-odi Bẹtani, abúlé kan tí ó jẹ́ nǹkan bíi ibùsọ̀ meji sí Jerusalẹmu. Iwọnba ọjọ́ diẹ ni ó ṣì jẹ́ lẹhin iku ati isinku Lasaru, Maria ati Mata tí wọn jẹ́ awọn arabinrin rẹ̀ ṣì ńṣọ̀fọ̀, ọpọlọpọ sì ti wá sí ilé wọn lati ṣìpẹ̀ fun wọn.
Bí wọn ti ńṣọ̀fọ̀ lọwọ, ẹnikan ta Mata lólobó pe Jesu ti ńbọ̀ lọ́nà. Nitori naa o lọ kuro ó sì kánjú lọ lati pade rẹ̀, láìsọ fun arabinrin rẹ̀ bí ó ti hàn kedere. Ní dídé ọ̀dọ̀ Jesu, Mata tún sọ ohun tí oun ati arabinrin rẹ̀ ti gbọdọ sọ ní ọpọlọpọ ìgbà láàárín ọjọ mẹrin tí ó ti kọja: “Bí iwọ bá ti wà níhìn-ín arakunrin mi kì bá ti kú.”
Mata, bí ó ti wù kí ó rí, fi ìrètí hàn sóde, ní sísọ pe Jesu ṣì lè ṣe ohun kan fun arakunrin rẹ̀. “Emi mọ̀ pe ohunkohun tí iwọ bá beere fun lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yoo fun ọ,” ni oun sọ.
“Arakunrin rẹ̀ yoo dìde,” ni Jesu ṣèlérí.
Mata lóye Jesu pe ó ńsọ nipa ajinde ọjọ́ iwájú kan ti ilẹ̀-ayé, eyi tí Aburahamu ati awọn iranṣẹ Ọlọrun miiran ńfojúsọ́nà fun pẹlu. Nitori naa o fèsì pe: “Mo mọ̀ pe yoo dìde ninu ajinde ní ọjọ́ ìkẹhìn.”
Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu fúnni ní ireti ìtura ẹsẹkẹsẹ, ní fífèsìpadà pe: “Emi ni ajinde ati ìyè.” Oun ńrán Mata létí pe Ọlọrun ti fun oun lágbára lórí ikú, ní sísọ pe: “Ẹni tí ó bá lò ìgbàgbọ́ ninu mi, àní bí ó tilẹ kú, yoo wá sí ìyè; ati olukuluku ẹni tí nbẹ láàyè tí ó sì lò ìgbàgbọ́ ninu mi kì yoo kú rárá láé.”
Jesu ko dámọ̀ràn fun Mata pe awọn ẹni olùṣòtítọ́ tí wọn walaaye nigba naa kì yoo kú laelae. Bẹẹkọ, ṣugbọn kókó tí ó mú jáde ni pe lílò ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ lè ṣamọ̀nà sí iye ainipẹkun. Irúfẹ́ iye bẹẹ ni awọn ènìyàn tí wọn pọ̀ jùlọ yoo gbádùn gẹgẹ bi ìyọrísí jíjí tí a jí wọn dìde ní ikẹhin ọjọ. Ṣugbọn awọn miiran tí wọn jẹ́ olùṣòtítọ́ yoo la òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii já lórí ilẹ̀-ayé, ati fun awọn wọnyi ni ọ̀rọ̀ Jesu yoo jẹ́ otitọ ní èrò ìtumọ̀ gidi gan-an. Wọn kì yoo kú rárá láé! Lẹhin gbólóhùn ọ̀rọ̀ pípẹtẹrí yii, Jesu beere lọwọ Mata pe, “Iwọ ha gba eyi gbọ́ bí?”
“Bẹẹni, Oluwa,” ni oun dáhùn. “Mo ti gbàgbọ́ pe iwọ ni Kristi naa Ọmọkunrin Ọlọrun, Ẹni naa tí ńbọ̀ wá sí ayé.”
Mata lẹhin naa sáré pada lọ lati lọ pe arabinrin rẹ̀ wá, ní sísọ fun un níkọ̀kọ̀ pe: “Olùkọ́ wà níhìn-ín ó sì ńpè ọ́.” Lẹsẹkẹsẹ Maria fi ilé naa silẹ. Nigba ti awọn yooku rí i tí ó ńlọ, wọn tẹle e, ní ríronú pe o ńlọ sí ibojì ìrántí naa.
Nigba tí ó dé ọ̀dọ̀ Jesu, Maria wólẹ̀ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì ńsunkún. “Oluwa, bí iwọ bá ti wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá ti kú,” ni oun wí. Imọlara Jesu ru sókè lọna jíjinlẹ̀ nigba ti ó ríi pe Maria ati ogunlọgọ nla awọn eniyan tí wọn tẹle e ńsunkún. “Nibo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” ni oun beere.
“Oluwa, wá wò ó,” ni wọn dáhùn.
Jesu pẹlu fàyègba omijé, tí ó mú kí awọn Juu sọ pe: “Wò ó, bí ìfẹ́ni tí ó ní fun un tẹlẹri ti pọ̀ tó!”
Awọn kan rántí pe Jesu, nígbà Àjọ Àríyá awọn Àgọ́-ìsìn ní iwọnba oṣu diẹ sẹhin, ti mú ọ̀dọ́ ọkunrin kan tí a bí ní afọ́jú láradá, wọn sì wipe: “Ọkunrin yii tí ó la ojú afọ́jú kò ha lè dena ẹni yii lati maṣe kú bí?” Johanu 5:21; 6:40; 9:1-7; 11:17-37.
▪ Nigba wo ni Jesu dé nikẹhin sí ìtòsí Bẹtani, kí sì ni ipò ti rí nibẹ?
▪ Ìdí wo ni Mata ní fun ìgbàgbọ́ ninu ajinde?
▪ Bawo ni ikú Lasaru ṣe nípa lórí Jesu?