Jesu Bá Awọn Farisi Wi Lọna Lilekoko
Orí 42
Jesu Bá Awọn Farisi Wi Lọna Lilekoko
BÍ Ó bá jẹ́ nipasẹ agbára Satani ni oun fi ńlé awọn ẹ̀mí èṣù jáde, Jesu jiyàn pe, nigba naa Satani lòdìsí araarẹ̀. “Yálà kí ẹyin ènìyàn sọ igi di rere kí èso rẹ̀ sì di rere,” ni ó nbaa lọ, “tabi sọ igi di alárùn kí èso rẹ̀ sì di alárùn; nitori nipa èso rẹ̀ ni a fi ńmọ igi.”
Ó jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lati fẹ̀sùn sùn pe èso rere ti lílé awọn ẹ̀mí èṣù jáde jẹ́ nitori pe Jesu ńṣiṣẹ́sìn Satani. Bí èso naa bá jẹ́ rere, igi naa kò lè jẹ́ alárùn. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, èso alárùn awọn Farisi ti awọn ẹ̀sùn tí kò lọ́gbọ́nninu ati àtakò aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ sí Jesu jẹ́ ẹ̀rí pe awọn fúnraawọn jẹ́ alárùn. “Ẹyin ìran-ọmọ awọn paramọ́lẹ̀,” ni Jesu ṣalaye, “bawo ni ẹyin ṣe lè sọ̀rọ̀ awọn nǹkan daradara, nigba tí ẹyin jẹ́ ènìyàn buruku? Nitori lati inú ọpọlọpọ ohun tí nbẹ ninu ọkàn-àyà ni ẹnu ńsọ.”
Niwọn bi awọn ọ̀rọ̀ ti ńfi ipò ọkàn-àyà wa hàn, ohun tí a bá sọ pèsè ìpìlẹ̀ fun ìdájọ́. “Mo sọ fun yin,” ni Jesu wí, “pe olukuluku ọ̀rọ̀ aláìlérè tí awọn ènìyàn sọ ni wọn yoo jíhìn nipa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́; nitori nipa awọn ọ̀rọ̀ rẹ ni a ó fi kà ọ́ sí olódodo, ati nipa awọn ọ̀rọ̀ rẹ ni a ó fi dá ọ lẹ́bi.”
Láìka gbogbo awọn iṣẹ́ Jesu tí ó kún fun agbára sí, awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi beere pe: “Olùkọ́, awa fẹ́ lati rí àmì kan lati ọ̀dọ̀ rẹ.” Bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn ọkunrin wọnyi ní pàtàkì lati Jerusalẹmu lè má tíì fúnraawọn rí awọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, ẹ̀rí awọn ẹlẹ́rìí olùfojúrí tí kò ṣeéjá ní koro nbẹ nipa wọn. Nitori naa Jesu sọ fun awọn aṣaaju Juu naa pe: “Ìran-ènìyàn buruku ati panṣágà nbaa nìṣó ní wíwá àmì kiri, ṣugbọn a kì yoo fun un ní àmì kankan bikoṣe àmì Jona wolii.”
Ní ṣíṣàlàyé ohun tí oun ní lọ́kàn, Jesu nbaa lọ pe: “Nitori gan-an gẹgẹ bi Jona ti wà ninu ikun ẹja ńlá fun ọ̀sán mẹta ati òru mẹta, bẹẹ gẹ́gẹ́ ni Ọmọkunrin ènìyàn yoo wà ninu ilẹ̀-ayé fun ọ̀sán mẹta ati òru mẹta.” Lẹhin tí ẹja naa ti gbé e mì, Jona jáde wá bí ẹni pe a jí i dìde, Jesu nipa bayii ńsọtẹ́lẹ̀ pe oun yoo kú ati pe ní ọjọ́ kẹta a ó jí oun dìde láàyè. Sibẹ, awọn aṣaaju Juu, àní nigba ti a jí Jesu dìde lẹhin naa pàápàá, ṣá “àmì Jona” naa tì.
Nitori eyi Jesu sọ pe awọn ọkunrin Ninefe tí wọn ronúpìwàdà ní gbígbọ́ iwaasu Jona yoo dìde ninu ìdájọ́ lati dá awọn Juu tí wọn ṣá Jesu tì naa lẹ́bi. Bẹẹ gẹ́gẹ́, oun fa ìbáradọ́gba kan yọ pẹlu ọbabinrin Ṣẹba, tí ó ti òpin ilẹ̀-ayé wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni tí ẹnu sì yà á sí ohun tí oun rí ati eyi tí ó gbọ́. “Ṣugbọn, wòó!” ni Jesu wi, “ohun kan tí ó tóbi jù Solomoni wà níhìn-ín.”
Lẹhin naa ni Jesu fúnni ní àkàwé nipa ọkunrin kan lati inú ẹni tí ẹ̀mí àìmọ́ kan ti jáde. Ọkunrin naa, bí ó ti wù kí ó rí, kò fi awọn ohun rere kún ibi òfìfo naa, ati nitori bẹẹ awọn ẹ̀mí buburu meje miiran sí i sì kówọ inú rẹ̀. “Bẹẹ gẹgẹ ni yoo ri fun ìran-ènìyàn buruku yii pẹlu,” ni Jesu wí. Orílẹ̀-èdè Isirẹli ni a ti wẹ̀mọ́ tí o sì ti ní ìrírí àtúnṣe—gẹgẹ bi ìlọkúrò ẹ̀mí àìmọ́ kan fun ìgbà diẹ. Ṣugbọn ṣíṣá tí orílẹ̀-èdè naa ṣá awọn wolii Ọlọrun tì, tí ó dé òtéńté rẹ̀ ninu àtakò wọn sí Kristi fúnraarẹ̀ ṣípayá ipò buruku tí ó wà gẹgẹ bi eyi tí ó burú pupọpupọ jù bí ó ṣe ri ní ìbẹ̀rẹ̀ lọ.
Bí Jesu ti ńsọ̀rọ̀ lọwọ, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ dé tí wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ogunlọgọ naa. Nitori naa ẹnikan wipe: “Wòó! Iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ dúró lóde, wọn ńwá ọ̀nà lati bá ọ sọ̀rọ̀.”
“Ta ni iya mi, ta sì ni awọn arakunrin mi?” ni Jesu beere. Ní nína ọwọ́ rẹ̀ sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó wipe: “Wòó! Iya mi ati awọn arakunrin mi! Nitori ẹni yoowu tí ó bá ṣe ìfẹ́-inú Baba tí nbẹ ní ọ̀run, ẹni naa ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.” Ní ọ̀nà yii Jesu fihàn pe láìka bí ìdè tí ó dè é pọ̀ mọ́ awọn ìbátan rẹ̀ ti lè lókun tó, ìbátan rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣì lokun jù. Matiu 12:33-50; Maaku 3:31-35; Luuku 8:19-21.
▪ Bawo ni awọn Farisi ṣe kùnà lati sọ “igi” ati “èso” di rere?
▪ Ki ni “àmì Jona” jẹ́, bawo ni a sì ṣe ṣá a tì nigba tí ó yá?
▪ Bawo ni orílẹ̀-èdè Isirẹli ọ̀rúndún kìn-ínní ṣe dabi ọkunrin kan tí ẹ̀mí àìmọ́ kan jáde lati inu rẹ̀?
▪ Bawo ni Jesu ṣe tẹnumọ́ ìbátan tímọ́tímọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀?