Jesu ati Ọ̀dọ́ Olùṣàkóso Kan Ti O Lọ́rọ̀
Orí 96
Jesu ati Ọ̀dọ́ Olùṣàkóso Kan Ti O Lọ́rọ̀
BI JESU ti ńlà àgbègbè Peria kọjá síhà Jerusalẹmu, ọkunrin ọ̀dọ́ kan sáré bá a ó sì wólẹ̀ lórí awọn eékún rẹ̀ niwaju rẹ̀. Ọkunrin naa ni a pè ní olùṣàkóso kan, o ṣeeṣe ki eyi tumọsi pe oun di ipò yíyọrí ọlá kan mú ninu sinagọgu àdúgbò naa tabi kódà pe oun jẹ́ mẹmba kan ninu Sanhẹdrin. Pẹlupẹlu, oun lọ́rọ̀ lọpọlọpọ. Ó beere pe, “Olukọni Rere, ki ni emi yoo ṣe tí emi yoo fi lè jogún ìyè ainipẹkun?”
“Eeṣe tí iwọ fi ńpè mi ní ẹni rere?” ni Jesu fèsì. “Ẹni rere kan kò sí bikoṣe ẹnikan, eyiini ni Ọlọrun.” Ó jọ bí ẹnipe ọkunrin ọ̀dọ́ naa lò “rere” gẹgẹ bi orúkọ oyè kan, nitori naa Jesu jẹ́ kí ó mọ̀ pe irúfẹ́ orúkọ oyè bẹẹ jẹ́ ti Ọlọrun nikanṣoṣo.
Jesu nbaa lọ pe, ‘Ṣugbọn bí iwọ bá ńfẹ́ wọ ibi ìyè, pa awọn òfin-àṣẹ mọ́ títílọ.’
‘Awọn wo ni?’ ni ọkunrin naa beere.
Ní títọ́kasí márùn-ún ninu Awọn Òfin Mẹ́wàá, Jesu dáhùn pe: “Iwọ kò gbọdọ pànìyàn; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jalè; Iwọ kò gbọdọ jẹ́rìí èké; Bọ̀wọ̀ fun baba ati iya rẹ.” Ati ní fífi òfin-àṣẹ tí ó tilẹ ṣe pàtàkì jù kún un, Jesu wipe: “Kí iwọ fẹ́ aládùúgbò rẹ bí araàrẹ.”
“Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati ìgbà èwe mi wá,” ni ọkunrin naa dáhùn pẹlu gbogbo òtítọ́ inú. “Ki ni ó kù mi kù?”
Ní fífetísílẹ̀ sí ibeere onitara ati onifọkansi tí ọkunrin naa beere, Jesu nímọ̀lára ìfẹ́ fun un. Ṣugbọn Jesu wòye ìsomọ́ ọkunrin naa pẹlu awọn nǹkan ìní ti ara ati nitori naa ó fi àìní rẹ̀ hàn: “Ohun kan ni ó kù ọ́ kù: lọ ta ohunkohun tí o ní kí o sì fifún awọn tálákà, iwọ yoo sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, . . . kí o sì maa tọ̀ mí lẹhin.”
Jesu ńwò, láìsí iyèméjì pẹlu ìkáàánú, bí ọkunrin naa ti dìde tí ó sì kuro pẹlu ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀. Ọlà rẹ̀ fọ́ ọ lójú sì ìṣúra iyebíye tootọ. Jesu dárò pe, “Yoo ti ṣòro tó fun awọn tí o ní ọrọ̀ lati wọ ijọba Ọlọrun!”
Awọn ọ̀rọ̀ Jesu ṣe awọn ọmọ-ẹhin naa ní kayefi. Ṣugbọn ẹnu yà wọn pupọ sii pàápàá nigba ti oun nbaa lọ lati sọ òfin ìdiwọ̀n gbogbogboo kan: “Ó rọrùn fun ìbákasíẹ lati wọ ojú-abẹ́rẹ́, jù fun ọlọ́rọ̀ lati wọ ijọba Ọlọrun lọ.”
“Njẹ ta ni ó ha lè là?” ni awọn ọmọ-ẹhin fẹ́ lati mọ̀.
Ní wíwò wọn tààràtà, Jesu fèsì pe: “Eniyan ni eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣíṣe.”
Ní ṣíṣàkíyèsí pe awọn ti ṣe yíyàn kan tí ó yàtọ̀ gan-an sí ti ọ̀dọ́ olùṣàkóso ti o lọ́rọ̀ naa, Peteru wipe: “Wòó, awa ti fi gbogbo nǹkan silẹ awa sì ńtọ̀ ọ́ lẹhin.” Nitori naa ó beere pe: “Njẹ ki ni awa ó ha ní?”
Jesu ṣèlérí pe, “Loootọ ni mo wi fun yin, pe ẹyin ti ẹ ntọ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigba ti Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] eniyan yoo jokoo lori ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹyin yoo si jókòó pẹlu lórí ìtẹ́ mejila, ẹyin yoo maa ṣe ìdájọ́ awọn ẹ̀yà Isirẹli mejila.” Bẹẹni, Jesu ńfihàn pe àtúnbí awọn ipò yoo wà lórí ilẹ̀-ayé kí awọn nǹkan baa lè wà gẹgẹ bi wọn ti wà ninu ọgbà Edeni. Peteru ati awọn ọmọ-ẹhin miiran yoo sì gbà èrè ṣíṣàkóso pẹlu Kristi lórí Paradise yii yíká ilẹ̀ ayé. Dajudaju, irú èrè títóbilọ́lá bẹẹ yẹ fun ìrúbọ eyikeyii!
Bí ó ti wù kí ó rí, kódà nisinsinyi awọn èrè nbẹ, gẹgẹ bi Jesu ti sọ pẹlu ifidimulẹgbọnyin pe: “Kò sí ẹni tí ó fi ilé silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, nitori mi, ati nitori ihinrere, ṣugbọn nisinsinyi ni aye yii oun yoo sì gbà ọgọrọọrun, ilé, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ̀, pẹlu inúnibíni, ati ní aye ti nbọ iye ainipẹkun.”
Gẹgẹ bi Jesu ti ṣèlérí, ibikibi tí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bá lọ ninu ayé, wọn ńgbádùn ìbátan kan pẹlu awọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn eyi tí ó ṣe tímọ́tímọ́ tí ó sì ṣe iyebíye ju eyi tí wọn ńgbádùn pẹlu awọn mẹmba idile àbínibí lọ. Ọ̀dọ́ olùṣàkóso ti o lọ́rọ̀ naa bí ó ti hàn gbangba padanu èrè yii ati ti iye ainipẹkun ninu Ijọba ọrun ti Ọlọrun.
Lẹhin eyiini Jesu fikun un pe: “Ṣugbọn ọ̀pọ̀ awọn tí ó ṣíwájú ni yoo kẹ́hìn; awọn tí ó kẹ́hìn ni yoo sì ṣíwájú.” Ki ni eyi tumọsi?
Ohun tí oun nílọ́kàn ni pe ọpọlọpọ tí wọn “ṣíwájú” ninu gbígbádùn awọn àǹfààní isin, irú bí ọ̀dọ́ olùṣàkóso ti o lọ́rọ̀ naa, kì yoo wọnú Ijọba naa. Wọn yoo “kẹ́hìn.” Ṣugbọn ọpọlọpọ, títíkan awọn ọmọ-ẹhin Jesu tí wọn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí awọn Farisi olódodo lójú araawọn ńfojú tẹ̀mọ́lẹ̀ gẹgẹ bi awọn ẹni ‘ìkẹhìn’—pe wọn jẹ́ awọn eniyan ilẹ̀-ayé, tabi ‛am ha·’aʹrets—yoo di awọn ẹni ‘ìṣáájú.’ Dídí ẹni ‘ìṣáájú’ wọn tumọsi pe wọn yoo gbà àǹfààní dídi alájùmọ̀ ṣàkóso pẹlu Kristi ninu Ijọba naa. Maaku 10:17-31; Matiu 19:16-30; Luuku 18:18-30.
▪ Bí ó ti hàn kedere, irú olùṣàkóso wo ni ọ̀dọ́ ọkunrin ti o lọ́rọ̀ naa jẹ́?
▪ Eeṣe tí Jesu fi takò jíjẹ́ ẹni tí a ńpè ní rere?
▪ Bawo ni ìrírí ọ̀dọ́ olùṣàkóso naa ṣe ṣàkàwé ewu jíjẹ́ ọlọ́rọ̀?
▪ Awọn èrè wo ni Jesu ṣèlérí fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀?
▪ Bawo ni awọn ẹni ìṣáájú ṣe di ẹni ìkẹhìn, bawo sì ni awọn ẹni ìkẹhìn ṣe di ẹni ìṣáájú?