Kíkọ́ Nikodemu Lẹkọọ
Orí 17
Kíkọ́ Nikodemu Lẹkọọ
NIGBA ti o wà nibi Irekọja 30 C.E., Jesu ṣe awọn iṣẹ ami, tabi awọn iṣẹ iyanu yiyanilẹnu. Nitori eyi, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́. Nikodemu, mẹmba kan lara Sanhẹdrin, ile ẹjọ giga awọn Juu, ni a mú orí rẹ̀ yá tí ó sì fẹ́ lati mọ̀ sii. Nitori naa oun bẹ Jesu wò nigba òkùnkùn biribiri alẹ́, o ṣeeṣe ki oun ti bẹ̀rù pe ìfùsì oun yoo bajẹ lọdọ awọn aṣaaju Juu yooku bí wọn bá rí oun.
“Rabi,” ni oun wí, “awa mọ̀ pe olukọni lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni iwọ nṣe: nitori pe kò sí ẹni ti o lè ṣe iṣẹ ami wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣe pe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.” Ni fifesi, Jesu sọ fun Nikodemu pe lati lè wọ Ijọba Ọlọrun, ẹnikan ni a gbọdọ “túnbí.”
Sibẹ, bawo ni a ṣe lè tún ẹnikan bí? “O ha lè wọ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, kí ó sì bí i?” ni Nikodemu beere.
Rara, kii ṣe ohun ti jíjẹ́ ẹni ti a tunbi tumọsi niyẹn. “Bikoṣe pe a fi omi ati ẹmi bí eniyan,” ni Jesu ṣalaye, “oun kò lè wọ ijọba Ọlọrun.” Nigba ti a baptisi Jesu tí ẹmi mimọ sì sọkalẹ lé e lori, nipa bayii a fi “omi ati ẹmi” bí i. Pẹlu ipolongo lati ọrun wá ti o ṣẹlẹ nigba naa, “Eyi ni ọmọkunrin mi, aayo olufẹ, ẹni ti mo tẹwọgba,” Ọlọrun kede pe oun ti mú ọmọkunrin tẹmi kan jade ti o ní ireti wiwọ Ijọba ọrun. Lẹhin naa, ni Pẹntikọsi 33 C.E., awọn miiran ti a ti baptisi yoo gba ẹmi mimọ tí wọn yoo sì tún tipa bayii di ẹni ti a tunbi gẹgẹ bi awọn ọmọkunrin tẹmi fun Ọlọrun.
Ṣugbọn ipa ti akanṣe Ọmọkunrin ẹda eniyan ti Ọlọrun kó ṣe pataki gidi. “Bí Mose sì ti gbé ejò soke ni aginju,” ni Jesu sọ fun Nikodemu, “gẹgẹ bẹẹ naa ni a kò lè ṣe alaigbe Ọmọ eniyan soke pẹlu ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́, ki o ma baa ṣègbé, ṣugbọn ki o lè ní iye ainipẹkun.” Bẹẹni, gẹgẹ bi awọn ọmọ Isirẹli wọnni tí ejò olóró bùjẹ ti nilati wo ejò idẹ naa lati lè ní ìgbàlà, bẹẹ naa ni gbogbo ẹda eniyan nilati lò igbagbọ ninu Ọmọkunrin Ọlọrun lati lè rí ìgbàlà kuro ninu ipò kíkú.
Ni titẹnumọ ipa onifẹẹ ti Jehofa kó ninu eyi, Jesu sọ fun Nikodemu lẹhin naa pe: “Ọlọrun fẹ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ ma baa ṣègbé, ṣugbọn ki o lè ní iye ainipẹkun.” Nipa bẹẹ, nihin-in ni Jerusalẹmu ni kiki oṣu mẹfa lẹhin ibẹrẹ iṣẹ ojiṣẹ rẹ̀, Jesu mú un ṣe kedere pe oun ni Jehofa Ọlọrun yoo lò fun igbala iran eniyan.
Jesu tẹsiwaju lati ṣalaye fun Nikodemu pe: “Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ sí aye lati dá araye lẹjọ” iyẹn ni pe, kii ṣe lati ṣe idajọ rẹ̀ lọna ti o lekoko, tabi dá a lẹbi, nipa didajọ iparun fun iran eniyan. Dipo eyi, gẹgẹ bi Jesu ti wi, a rán an “kí a lè ti ipasẹ rẹ̀ gba araye là.”
Nikodemu ti fi ibẹru wá sọdọ Jesu labẹ iboju okunkun. Nitori naa o jẹ́ ohun ti o dunmọ wa ninu pe Jesu pari ibanisọrọpọ pẹlu rẹ̀ ni wiwi pe: “Eyi ni idajọ naa pe, imọlẹ [eyi ti Jesu sọ di ẹni gidi ninu igbesi aye ati awọn ẹkọ rẹ̀] wá sí aye, awọn eniyan sì fẹ́ okunkun ju imọlẹ lọ, nitori iṣẹ́ wọn buru. Nitori olukuluku ẹni ti o ba nhuwa buburu ní nkoriira imọlẹ, kii sii wá sí imọlẹ, ki a maṣe bá iṣẹ rẹ̀ wí. Ṣugbọn ẹni ti o ba nṣe otitọ ni nwa sí imọlẹ, kí iṣẹ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.” Johanu 2:23–3:21; Matiu 3:16, 17; Iṣe 2:1-4; Numeri 21:9.
▪ Ki ni o fa ibẹwo Nikodemu, eesitiṣe ti oun fi wá ni òru?
▪ Ki ni o tumọsi lati di ẹni tí a “túnbí”?
▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣe àkàwé ipa ti oun kó ninu igbala wa?
▪ Ki ni o tumọsi pe Jesu kò wá lati ṣedajọ aye?