Ki Ni Ohun Tí Ó Bófinmu ní Sabaati?
Orí 32
Ki Ni Ohun Tí Ó Bófinmu ní Sabaati?
ÓJẸ́ ní Sabaati miiran tí Jesu ṣe ìbẹ̀wò sí sinagọgu kan nítòsí Òkun Galili. Ọkunrin kan tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ rọ wà níbẹ̀. Awọn akọ̀wé ati awọn Farisi ńṣọ́ Jesu lójú méjèèjì lati rí boya yoo mú un láradá. Nikẹhin wọn beere pe: “Ó ha bófinmu lati ṣe ìwòsàn ní sabaati?”
Awọn aṣaaju ìsìn Juu gbàgbọ́ pe ṣiṣe iwosan bófinmu ní Sabaati kìkì bí iwalaaye bá wà ninu ewu. Wọn ńkọ́ni, fun apẹẹrẹ, pe ní Sabaati kò bófinmu lati to egungun kan tabi lati fi ọ̀já di ibìkan tí a firọ́. Nitori naa awọn akọ̀wé ati awọn Farisi ńbi Jesu ní ibeere ninu ìsapá lati rí ẹ̀sùn kan lòdìsí i.
Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, mọ̀ ìrònú wọn. Ní àkókò kan naa, oun mọ̀ pe ojú ìwòye lílégbákan, tí kò bá iwe mimọ mu ni wọn múlò niti ohun tí ó pilẹ̀ jẹ́ riru òfin ohun tí Sabaati beere tí ó kọ̀fún ẹnikan lati ṣiṣẹ́. Nipa bayii Jesu pese ipilẹ fun ìkonilójú amúnijígìrì kan nipa sísọ fun ọkunrin naa tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pe: “Dìde kí o sì wá sí àárín.”
Nisinsinyi, ní yíyíjú sí awọn akọwe ati awọn Farisi, Jesu sọ pe: “Ta ni yoo jẹ́ ọkunrin naa láàárín yin tí ó ní àgùtàn kan, bí eyi bá sì ṣubú sínú kòtò, ní sabaati, tí kì yoo dì í mú kí ó sì gbé e jáde sókè?” Niwọn bi àgùtàn kan ti dúró fun ìdókòwò kan tí ńmú owó wọlé, wọn kì yoo fi i silẹ sínú kòtò títí di ọjọ́ keji, boya lati mú un ṣàìsàn kí ó sì fa àdánù ba wọn. Yatọ si eyi, Iwe Mimọ sọ pe: “Olódodo ènìyàn ńṣaájò ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀.”
Ní fífa ìbáradọ́gba kan yọ, Jesu nbaa lọ: “Ní gbígbé gbogbo rẹ̀ yẹ̀wò, meloomeloo ni ènìyàn fi níyelórí pupọ ju àgùtàn lọ! Nitori naa ó bófinmu lati ṣe nǹkan rere ní sabaati.” Kò ṣeeṣe fun awọn aṣaaju isin naa lati já irúfẹ́ ìrònú oníyọ̀ọ́nú ti o sì bọ́gbọ́nmu bẹẹ nírọ́, wọn sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.
Pẹlu ìkannú, ati ẹ̀dùn ọkàn fun ìwà dìndìnrìn olóríkunkun wọn, Jesu wò yíká. Lẹhin naa ó wí fun ọkunrin naa pe: “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó sì nà án jáde a sì mú ọwọ́ naa láradá.
Dípò kí wọn láyọ̀ pe ọwọ́ ọkunrin naa ni a mú padàbọ̀sípò, awọn Farisi naa jáde wọn sì di tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun lẹsẹkẹsẹ pẹlu awọn ọmọlẹhin ẹgbẹ́ Hẹrọdu lati pa Jesu. Ẹgbẹ́ òṣèlú yii lọna tí ó hàn gbangba ní ninu awọn mẹmba Sadusi onísìn. Bí ó ti saba maa ńjẹ́, ẹgbẹ́ òṣèlú yii ati awọn Farisi lòdìsí araawọn ní gbangba, ṣugbọn wọn sopọ̀ṣọ̀kan lọna lílágbara ninu atako wọn sí Jesu. Matiu 12:9-14; Maaku 3:1-6; Luuku 6:6-11; Owe 12:10; Ẹkisodu 20:8-10.
▪ Ki ni ipilẹ fun ìkòlójú amúnijígìrì láàárín Jesu ati awọn aṣaaju ìsìn Juu?
▪ Ki ni ohun tí awọn aṣaaju ìsìn Juu wọnyi gbàgbọ́ nipa ìmúniláradá ní Sabaati?
▪ Àkàwé wo ni Jesu lò lati fi já awọn ojú ìwòye òdì wọn nírọ́?