Mímú Ọkunrin kan Tí A Bí Ní Afọ́jú Láradá
Orí 70
Mímú Ọkunrin kan Tí A Bí Ní Afọ́jú Láradá
NIGBA ti awọn Juu gbìyànjú lati sọ Jesu lókùúta, oun kò fi Jerusalẹmu silẹ. Lẹhin naa, ní Sabaati, oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ńrìnlọ ninu ìlú-ńlá naa nigba ti wọn rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú lati ìgbà ìbí rẹ̀. Awọn ọmọ-ẹhin beere lọwọ Jesu pe: “Olùkọ́ni, ta ni dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yii tabi awọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”
Boya awọn ọmọ-ẹhin naa gbàgbọ́, gẹgẹ bi awọn rabi kan ti ṣe, pe ẹnikan lè dẹ́ṣẹ̀ ninu ilé-ọlẹ̀ iya rẹ̀. Ṣugbọn Jesu dáhùn pe: “Kii ṣe nitori tí ọkunrin yii dẹ́ṣẹ̀, tabi awọn òbí rẹ̀: ṣugbọn kí a lè fi iṣẹ́ Ọlọrun hàn lára rẹ̀.” Ìfọ́jú ọkunrin naa kii ṣe àbájáde ìṣìnà pàtó kan tabi ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkunrin naa tabi awọn òbí rẹ̀ ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ọkunrin àkọ́kọ́ Adamu yọrísí àìpé gbogbo ẹ̀dá-ènìyàn, tí wọn sì tipa bẹẹ wà lábẹ́ irúfẹ́ ìkù-díẹ̀-káàtó bíi bíbíni ní afọ́jú. Ìkù-díẹ̀-káàtó yii ninu ọkunrin naa pèsè àǹfààní kan fun Jesu lati fi iṣẹ́ Ọlọrun hàn.
Jesu tẹnumọ́ kánjúkánjú kan ninu ṣíṣe iṣẹ́ yii. “Emi kò lè ṣe aláìṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, nigba tí ó ṣe ọ̀sán,” ni oun wí. “Òru ńbọ̀wá nigba ti ẹnikan kì yoo lè ṣe iṣẹ́. Niwọn ìgbà tí mo wà ní ayé, emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Láìpẹ́ ikú Jesu yoo gbé e sọ sínú òkùnkùn ibojì níbi tí kì yoo ti lè ṣe ohunkohun mọ́. Kí ó tó tó àkókò yẹn, oun ni orísun ìlàlóye fun ayé.
Lẹhin tí ó ti sọ awọn nǹkan wọnyi, Jesu tutọ́ sílẹ̀, tí ó sì lo itọ́ lati ṣe amọ̀ diẹ. Ó fi eyi sí ojú ọkunrin afọ́jú naa ó sì wipe: “Lọ, wẹ̀ ninu adágún Siloamu.” Ọkunrin naa ṣègbọràn. Nigba ti ó sì ṣe bẹẹ, oun lè ríran! Wo bí inu rẹ̀ ti dùn tó nigba ti o npadabọ, tí ó ríran fun ìgbà àkọ́kọ́ ninu igbesi-aye rẹ̀!
Ẹnu ya awọn aládùúgbò ati awọn miiran tí wọn mọ̀ ọ́n. “Ẹni ti o ti njokoo ṣagbe kọ niyii?” ni wọn beere. “Oun ni,” ni awọn kan dáhùn. Ṣugbọn awọn miiran kò lè gbà á gbọ́: “Bẹẹkọ, ó jọ ọ́ ni.” Sibẹ ọkunrin naa wipe: “Emi ni.”
“Njẹ ojú rẹ ti ṣe là?” awọn eniyan naa fẹ́ lati mọ̀.
“Ọkunrin kan tí a ńpè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kùn mi ní ojú, ó sì wi fun mi pe, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀:’ Emi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”
“Oun ha dà?” ni wọn beere.
“Emi kò mọ̀,” ni ó dáhùn.
Awọn eniyan naa nisinsinyi mú ọkunrin afọ́jú tẹlẹri naa lọ sọ́dọ̀ awọn aṣaaju isin wọn, awọn Farisi. Awọn wọnyi pẹlu bẹ̀rẹ̀ sí beere lọwọ rẹ̀ bí oun ti ṣe ríran. “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, mo sì ríran,” ni ọkunrin naa ṣàlàyé.
Dajudaju, ó yẹ kí awọn Farisi naa yọ pẹlu alágbe tí a mú láradá naa! Ṣugbọn dípò rẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Jesu. “Ọkunrin yii kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá,” ni wọn sọ. Eeṣe tí wọn fi sọ eyi? “Nitori tí kò pa Ọjọ isinmi [“Sabaati,” NW] mọ́.” Ati sibẹ awọn Farisi miiran ṣe kàyéfì: “Ọkunrin tí ńṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yoo ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọnyi?” Nitori naa ìyapa wà láàárín wọn.
Nipa bẹẹ, wọn beere lọwọ ọkunrin naa: “Ki ni iwọ wí nitori rẹ̀, nitori tí ó là ọ́ lójú?”
“Wolii ni,” ni oun dáhùn.
Awọn Farisi naa kọ̀ lati gba eyi gbọ́. Wọn gbàgbọ́ pe ìfohùnṣọ̀kan ìkọ̀kọ̀ kan ti gbọdọ wà láàárín Jesu ati ọkunrin yii lati tan awọn eniyan jẹ. Nitori naa lati yanjú ọ̀ràn naa, wọn pe awọn òbí alágbe naa kí wọn baa lè beere ọrọ lọwọ wọn. Johanu 8:59; 9:1-18.
▪ Ki ni okùnfà ìfọ́jú ọkunrin naa, kí sì ni kii ṣe?
▪ Ki ni òru naa nigba ti ẹnikẹni kò lè ṣiṣẹ́?
▪ Nigba ti a mú ọkunrin naa láradá, ki ni ìhùwàpadà awọn wọnni tí wọn mọ̀ ọ́n?
▪ Bawo ni awọn Farisi ṣe pínyà lórí ìmúláradá ọkunrin naa?