Obinrin Naa Fọwọ́kàn Ẹ̀wù Rẹ̀
Orí 46
Obinrin Naa Fọwọ́kàn Ẹ̀wù Rẹ̀
ÌRÒHÌN nipa ìpadàbọ̀ Jesu lati Dekapolisi dé Kapanaomu, tí ogunlọgọ ńlá kan sì péjọ sí ẹ̀bá òkun lati kí i káàbọ̀ pada. Láìṣiyèméjì wọn ti gbọ́ pe oun mú ìjì parọ́rọ́ tí oun sì mú awọn ọkunrin ẹlẹ́mìí èṣù láradá. Nisinsinyi, bí oun ṣe gbẹ́sẹ̀lé èbúté, wọn kórajọ yí i ká, wọn sì kún fun ìháragàgà ati ìfojúsọ́nà.
Ọ̀kan ninu awọn tí wọn ńṣàníyàn lati rí Jesu ni Jairu, òṣìṣẹ́ olóyè olùṣalága ní sinagọgu. Ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu tí ó sì ńbẹ̀ ẹ́ léraléra pe: “Ọmọbinrin mi kekere wà loju iku: mo bẹ ọ ki o wa fi ọwọ rẹ lé e, ki a lè mú un larada: oun yoo sì yè.” Niwọn bi ó ti jẹ́ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo tí ó sì jẹ́ ọmọ ọdun 12 péré, ọmọbinrin naa ṣe iyebíye niti gidi fun Jairu.
Jesu dáhùnpadà, o sì forílé ilé Jairu pẹlu àwùjọ tí ó bá a rìn. Awa lè foju inu wòye ìrusókè ìmọ̀lára awọn eniyan naa bí wọn ti ńfojúsọ́nà fun iṣẹ́ ìyanu miiran. Ṣugbọn afiyesi obinrin kan ninu awujọ naa wà lórí ìṣòro lílekoko tirẹ̀ fúnraarẹ̀.
Fun odidi 12 ọdun, obinrin yii ti jìyà lọwọ ìsun ẹ̀jẹ̀. O ti lọ sọ́dọ̀ dokita kan tẹle òmíràn, ní níná gbogbo owó rẹ̀ sórí ìtọ́jú. Ṣugbọn oun kò tii rí iranlọwọ gbà; kàkà bẹẹ, ìṣòro rẹ̀ ti di eyi tí ó burú sí i.
Gẹgẹ bi ó ti ṣeeṣe kí o mọ̀, yàtọ̀ sí sísọ ọ́ di aláìlera lọpọlọpọ, òjòjò rẹ̀ tún jẹ́ eyi tí ńdójútini tí ó sì ńtẹ́nilógo. Ní gbogbogboo ẹnikan kìí sọ̀rọ̀ ní gbangba nipa irú ìpọ́njú bẹẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lábẹ́ Òfin Mose ìsun ẹ̀jẹ̀ maa ńsọ obinrin kan di aláìmọ́, tí a sì beere pe kí ẹnikẹni tí ó bá fọwọ́kàn án tabi fọwọ́kàn awọn ẹ̀wù rẹ̀ eléèérí ẹ̀jẹ̀ lọ wẹ̀ kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di àṣálẹ́.
Obinrin naa ti gbọ́ nipa awọn iṣẹ́ ìyanu Jesu tí ó sì ti wá a rí nisinsinyi. Lójú ìwòye àìmọ́ rẹ̀, ó wá ọ̀nà rẹ̀ la àárín àwùjọ ènìyàn naa já lọna tí awọn eniyan kò fi ni rí i bí ó bá ti lè ṣeeṣe tó, ní wiwi fun araarẹ̀ pe: “Bí mo bá saa lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yoo dá.” Nigba ti ó ṣe bẹẹ, lẹsẹkẹsẹ ó nímọ̀lára pe ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ lọ́gán!
“Ta ni fi ọwọ́ tọ́ mi?” Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu wọnni ti nilati mú obinrin naa gbọ̀nrìrì tó! Bawo ni oun ṣe lè mọ̀? ‘Olùkọ́ni,’ ni Peteru ṣàtakò, ‘awọn eniyan nha ọ ni àyè, wọn sì nbilu ọ, iwọ sì wipe, “Ta ni o fi ọwọ́ kàn mi?”’
Ní wíwò yíká fun obinrin naa, Jesu ṣàlàyé pe: “Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi, nitori emi mọ̀ pe àṣẹ jade lára mi.” Nitootọ, kii ṣe ìfọwọ́kàn lásán, nitori ìmúláradá tí ó yọrísí fà lara okun Jesu.
Ní ríríi pe oun kò lè yẹra fun akiyesi, obinrin naa wá ó sì wólẹ̀ niwaju Jesu, tí jìnnìjìnnì dàbò ó tí ó sì ńwárìrì. Niwaju gbogbo eniyan naa, obinrin naa sọ gbogbo otitọ nipa àmódi rẹ̀ ati ọ̀nà tí a ti gbà mú un láradá nisinsinyi.
Bí a ti sún un nipasẹ ìjẹ́wọ́ obinrin naa tí ó kúnrẹ́rẹ́, Jesu fi tìyọ́nú tìyọ́nú tù ú ninu bayii: “Ọmọbinrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; maa lọ ní alaafia, kí iwọ ki o sì sàn ninu arun rẹ.” Bawo ni ó ti dára tó lati mọ̀ pe Ẹni naa tí Ọlọrun ti yàn lati ṣàkóso ilẹ̀-ayé jẹ́ irúfẹ́ eniyan onífẹ̀ẹ́ ati oníyọ̀ọ́nú bẹẹ, tí ó maa ńṣe ìtọ́jú awọn eniyan tí ó sì ní agbára lati ràn wọn lọwọ! Matiu 9:18-22; Maaku 5:21-34; Luuku 8:40-48; Lefitiku 15:25-27.
▪ Ta ni Jairu, eesitiṣe tí oun fi wá sọ́dọ̀ Jesu?
▪ Ìṣòro wo ni obinrin kan ní, eesitiṣe tí wíwá sọ́dọ̀ Jesu fun iranlọwọ fi ṣòrò gidigidi fun un?
▪ Bawo ni a ṣe mú obinrin naa láradá, bawo sì ni Jesu ṣe tù ú nínú?