Wọn Kùnà Lati Fi Àṣẹ Ọba Mú Un
Orí 67
Wọn Kùnà Lati Fi Àṣẹ Ọba Mú Un
BÍ ÀJỌ-ÀRÍYÁ Awọn Àgọ́-ìsìn ti ńlọ lọwọ, awọn aṣaaju-isin rán awọn ọ̀gá ọlọ́pàá jade lati fi àṣẹ ọba mú Jesu. Oun kò gbìdánwò lati farapamọ́. Kaka bẹẹ, Jesu ńbá kíkọ́ni nìṣó ní gbangba, ní wiwi pe: “Niwọn ìgbà diẹ sí i ni emi wà pẹlu yin, emi yoo sì lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi. Ẹyin yoo wá mi, ẹyin kì yoo sì rí mi: ati ibi tí emi bá wà, ẹyin kì yoo lè wá.”
Awọn Juu kò lóye, ati nitori bẹẹ wọn beere láàárín araawọn: “Nibo ni ọkunrin yii yoo gbé lọ, tí awa kì yoo fi rí i? Yoo ha lọ sáàárín awọn Hellene [“Giriiki,” NW] tí wọn fọ́n káàkiri kí ó sì maa kọ́ awọn Hellene [“Giriiki,” NW] bí? Ọ̀rọ̀ ki ni eyi tí ó sọ yii, ‘Ẹyin yoo wá mi, ẹ kì yoo sì rí mi: ati ibi tí emi bá wà, ẹyin kì yoo lè wá’?” Dajudaju, Jesu ńsọ̀rọ̀ nipa ikú rẹ̀ tí ńsúnmọ́lé ati ajinde rẹ̀ sí iwalaaye ní ọ̀run, níbi tí awọn ọ̀tá rẹ̀ kò lè dé.
Ọjọ́ keje tí ó gbẹ̀hìn àjọ-àríyá naa dé. Ní òròòwúrọ̀ àjọ-àríyá naa, alufaa kan yoo tú omi jáde, eyi tí ó bù lati inú Adagun Siloamu, kí ó baa lè ṣànlọ sí ìdí pẹpẹ. Bí ó ti jọ pe ó ńrán awọn eniyan létí nipa ayẹyẹ ojoojumọ yii, Jesu kígbe jáde pe: “Bí òrùngbẹ bá ńgbẹ ẹnikẹni, kí ó tọ̀ mi wá, kí ó sì mu. Ẹnikẹni tí ó bá gbà mi gbọ́, gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wí, ‘lati inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yoo ti maa ṣàn jáde wá.’”
Niti tootọ, Jesu níhìn-ín ńsọ̀rọ̀ nipa awọn àbájáde atóbilọ́la nigba ti a o tú ẹ̀mí mímọ́ jáde. Ní ọdun tí ó tẹle e títú ẹ̀mí mímọ́ jáde yii ṣẹlẹ ní ọjọ́ Pẹntikọsti. Nibẹ, odò omi ìyè ṣàn jáde nigba ti 120 ọmọ-ẹhin bẹrẹsii ṣèránṣẹ́ fun awọn eniyan. Ṣugbọn títí di ìgbà naa, kò sí ẹ̀mí ni ero itumọ naa pe kò sí eyikeyii ninu awọn ọmọ-ẹhin Kristi tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn tí a sì pè sí ìyè ti ọ̀run.
Ní ìdáhùnpadà sí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jesu, awọn kan bẹrẹsii wipe: “Lóòótọ́, eyi ni Wolii naa,” ní kedere wọn ńtọ́kasí wolii títóbijù naa tí ó ju Mose lọ ẹni tí a ṣèlérí pe yoo dé. Awọn miiran sọ pe: “Eyi ni Kristi naa.” Ṣugbọn awọn miiran ṣatako pe: “Kínla, Kristi yoo ha ti Galili wá bí? Iwe Mimọ kò ha wipe, Kristi yoo ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, ati Bẹtilẹhẹmu ìlú tí Dafidi ti wá?”
Nitori naa ìyapa jẹyọ láàárín awọn ogunlọgọ naa. Awọn kan ńfẹ́ kí a fi àṣẹ ọba mú Jesu, ṣugbọn kò sí ẹni kankan tí ó nawọ́ mú un. Nigba ti awọn ọga ọlọ́pàá padà láìmú Jesu, awọn olórí alufaa ati awọn Farisi beere pe: “Eeṣe tí ẹyin kò fi mú un wá?”
“Kò sí ẹni tí ó tíì sọ̀rọ̀ bíi ọkunrin yii rí,” ni awọn ìjòyè òṣìṣẹ́ naa fèsìpadà.
Bí wọn ti kún fun ìbínú, awọn aṣaaju-isin naa fi araawọn wọ́lẹ̀ lati pẹ̀gàn, lati parọ́, ati lati bú èébú. Wọn ṣe yẹ̀yẹ́: “A ha ti tàn yin jẹ pẹlu bí? O ha si ẹnikan ninu awọn ìjòyè, tabi awọn Farisi tí ó gbà á gbọ́? Ṣugbọn ijọ eniyan yii, tí kò mọ Òfin, di ẹni ìfibú.”
Ní gbígbọ́ eyi, Nikodemu, tí ó jẹ́ Farisi ati olùṣàkóso awọn Juu (eyiini ni, mẹmba Sanhẹdrin), fi igboya sọ̀rọ̀ nititori Jesu. Iwọ lè rántí pe ni ọdun meji aabọ ṣaaju ìgbà naa, Nikodemu tọ Jesu wá ní òru tí ó sì fi ìgbàgbọ́ hàn ninu rẹ̀. Nisinsinyi Nikodemu wipe: “Òfin wa ha ńṣe ìdájọ́ eniyan kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, ati kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”
Awọn Farisi bínú gidigidi pe ọ̀kan lára wọn pàápàá nilati gbèjà Jesu. “Iwọ pẹlu ńṣe ará Galili ndan?” ni wọn sọ lọna kíkorò. “Wákiri, kí o sì wò: nitori kò sí wolii kan tí ó ti Galili jáde.”
Bí ó tilẹ jẹ́ pe Iwe Mimọ kò sọ ní tààràtà pe wolii kan yoo jáde lati Galili wá, wọn nàka niti gidi sí Kristi gẹgẹ bi ẹni tí ó wá lati ibẹ̀, ní sísọ pe “ìmọ́lẹ̀ ńlá” ni a o rí ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ yii. Siwaju sii pẹlu, Jesu ni a bí ní Bẹtilẹhẹmu, ó sì jẹ́ ọmọ-inú Dafidi. Bí ó ti ṣeeṣe kí awọn Farisi mọ̀ eyi, ó ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn ni wọn ṣokùnfà títan oju iwoye òdì tí awọn eniyan ní nipa Jesu kalẹ̀. Johanu 7:32-52; Aisaya 9:1, 2; Matiu 4:13-17.
▪ Ki ni ńṣẹlẹ̀ ní gbogbo òròòwúrọ̀ ọjọ́-àríyá naa, bawo sì ni Jesu ṣe lè maa pe àfiyèsí sí eyi?
▪ Eeṣe tí awọn ìjòyè òṣìṣẹ́ naa fi kùnà lati fi àṣẹ ọba mú Jesu, bawo sì ni awọn aṣaaju isin naa ṣe dáhùnpadà?
▪ Ta ni Nikodemu, ki ni ẹ̀mí-ìrònú rẹ̀ síhà Jesu, bawo sì ni awọn Farisi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe hùwà sí i?
▪ Ẹ̀rí wo ni ó wà pe Kristi naa yoo jáde wá lati Galili?