Awọn Kristian ati Orukọ Naa
Awọn Kristian ati Orukọ Naa
KÒ SI ẹnikan tí ó le sọ daju niti pato igba tí awọn Jew ara ila-oorun dẹkun pipe orukọ Ọlọrun soke ketekete tí wọn si fi awọn ọrọ Hebrew fun Ọlọrun ati Oluwa Ọba Alaṣẹ ṣe arọpo. Awọn kan gbagbọ pe a ti ṣiwọ lilo orukọ Ọlọrun tipẹtipẹ ṣaaju akoko Jesu. Ṣugbọn ẹri-ami alagbara wà pe olori alufaa nbá a niṣo lati maa pè é nibi awọn ààtò isin ninu temple—paapaa ní ọjọ Etutu—ní taarata titi di igba tí a pa temple naa run ní 70 C.E. Fun idi yii, nigba ti Jesu wà lori ilẹ-aye pipe orukọ naa ni a mọ̀, bi o tilẹ dabi ẹnipe lilo rẹ̀ kii ṣe eyi tí ó tankalẹ.
Eeṣe tí awọn Jew fi dẹkun pipe orukọ Ọlọrun? Àfàìmọ̀ ki ó má jẹ pe, ó keretan lapakan, nitori ṣiṣe aṣilo awọn ọrọ ofin-aṣẹ kẹta naa pe: “Iwọ kò gbọdọ pe orukọ [Jehofah] Ọlọrun rẹ lasan.” (Exodus 20:7) Dajudaju, ofin-aṣẹ yii kò ka ìlò orukọ Ọlọrun leewọ. Bi bẹẹ kọ, eeṣe tí awọn iranṣẹ Ọlọrun nigba laelae bii David ṣe lò ó fàlàlà tí wọn si nbá a lọ lati gbadun ibukun Jehofah? Ati pe eeṣe tí Ọlọrun fi pè é fun Moses tí ó sọ fun un lati ṣalaye fun awọn ọmọ Israel ẹni naa tí ó rán an?—Psalm 18:1-3, 6, 13; Exodus 6:2-8.
Ṣugbọn, lakoko Jesu itẹsi alagbara kan wà lati mú awọn ofin-aṣẹ Ọlọrun ọlọgbọn-ninu ki wọn si tumọ wọn lọna alailọgbọn-ninu lọna giga. Fun apẹẹrẹ, ẹkẹrin ninu awọn Ofin-aṣẹ Mẹwa sọ ọ di ẹru-iṣẹ aigbọdọmaṣe fun awọn Jew lati pa ọjọ keje ọsẹ kọọkan mọ́ gẹgẹ bi Ọjọ Isinmi. (Exodus 20:8-11) Awọn Jew ara ila-oorun ayé sọ ofin-aṣẹ nì di ohun ẹgan, nipa ṣiṣe ọpọlọpọ awọn ofin-idiwọn janrẹrẹ lati ṣakoso ani iṣe tí ó kere julọ paapaa tí a lè ṣe tabi ṣalaiṣe ní Ọjọ Isinmi. Kò si iyemeji nipa rẹ̀ pe ninu ẹmi kan naa wọn mú ofin-aṣẹ ọlọgbọn-ninu Ọlọrun, pe orukọ Ọlọrun ni a kò gbọdọ tabuku si dé gongo alailọgbọn-ninu julọ, nipa sisọ pe wọn kò tilẹ gbọdọ pe orukọ naa rara. *
Jesu ati Orukọ Naa
Njẹ Jesu yoo ha ti tẹle iru ẹkọ-atọwọdọwọ tí kò bá Iwe-mimọ mu bẹẹ bi? Rara! Ó daju pe oun kò fasẹhin kuro ninu ṣiṣe awọn iṣẹ iwosan ní Ọjọ Isinmi, ani bi o tilẹ jẹ pe eyi tumọsi rírú awọn ofin-idiwọn àdábọwọ-eniyan ti awọn Jew ati fifi iwalaaye rẹ̀ wewu. (Matthew 12:9-14) Niti tootọ, Jesu dá awọn Pharisee lẹbi ní pípè wọn ní alagabagebe nitori pe awọn ẹkọ-atọwọdọwọ wọn jinna-réré si Ọrọ onimisi Ọlọrun. (Matthew 15:5-9) Fun idi yii, kii ṣe ohun tí a lè reti pe oun yoo ti fasẹhin kuro ninu pipe orukọ Ọlọrun, ní pataki loju otitọ-iṣẹlẹ naa pe orukọ oun funraarẹ̀, Jesu, tumọsi “Jehofah ni Igbala.”
Ní akoko-iṣẹlẹ kan, Jesu dide duro ninu sinagogue kan, tí ó si ka apakan ninu àkájọ-iwe Isaiah. Apá ibi tí oun kà ni eyi tí a npè ní Isaiah 61:1, 2 lonii, nibi tí orukọ Ọlọrun ti farahan ní eyi tí ó ju igba kanṣoṣo lọ. (Luke 4:16-21) Oun yoo ha ti kọ̀ lati pe orukọ atọrunwa naa nibẹ, nipa fifi “Oluwa” tabi “Ọlọrun” ṣe arọpo bi? Dajudaju kò ri bẹẹ. Eyiini ìbá ti tumọsi titẹle ẹkọ-atọwọdọwọ awọn aṣaaju isin Jew tí kò bá Iwe-mimọ mu. Kaka bẹẹ, a kà pe: “Ó nkọ wọn bi ẹni tí ó ní aṣẹ, kii sii ṣe bi awọn akọwe.”—Matthew 7:29.
Niti tootọ, gẹgẹ bi a ti kẹkọọ rẹ̀ ní iṣaaju, oun kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura si Ọlọrun pe: “Ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́.” (Matthew 6:9, NW) Ati pe ninu adura rẹ̀ ní alẹ ọjọ tí ó ṣaaju iku rẹ̀, oun sọ fun Baba rẹ̀ pe: “Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn eniyan tí iwọ ti fi fun mi lati inu ayé wá . . . Baba mímọ́, pa awọn tí o fi fun mi mọ́, ní orukọ rẹ.”—John 17:6, 11.
Niti awọn itọka wọnyi lati ọwọ Jesu si orukọ Ọlọrun, iwe naa Der Name Gottes (Orukọ Ọlọrun) Ṣalaye, ní oju-ewe 76 pe: “A gbọdọ mọriri otitọ-iṣẹlẹ yiyanilẹnu naa pe òye Majẹmu Laelae alatọwọdọwọ naa nipa iṣipaya Ọlọrun ni pe ó jẹ iṣipaya orukọ rẹ̀ ati pe eyi ni a lò jálẹ̀jálẹ̀ titi dé awọn apá tí ó gbẹhin Majẹmu Laelae, bẹẹ ni, ó nbá a niṣo ani titi dé awọn apá tí ó kẹhin ninu Majẹmu Titun, nibi ti, fun apẹẹrẹ ninu John 17:6, a kà pe: ‘Mo ti sọ orukọ rẹ di mímọ̀.’”
Bẹẹ ni, yoo nilati jẹ iwa alailọgbọn-ninu julọ lati ronu pe Jesu fasẹhin kuro ninu lilo orukọ Ọlọrun, ní pataki nigba tí oun ṣe àyọlò wá lati inu awọn apá Iwe-mimọ Hebrew tí wọn ní orukọ Ọlọrun ninu.
Awọn Kristian Akọkọbeṛẹ
Njẹ awọn ọmọlẹhin Jesu ní ọgọrun ọdun kìn-ín-ní ha lo orukọ Ọlọrun bi? Jesu ti paṣẹ fun wọn lati sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin. (Matthew 28:19, 20) Ọpọ ninu awọn tí wọn yoo waasu fun ni kò ní imọ kankan nipa Ọlọrun naa tí ó ti ṣí ara rẹ̀ paya fun awọn Jew nipa orukọ naa Jehofah. Bawo ni awọn Kristian naa yoo ti fi Ọlọrun tootọ hàn wọn? Njẹ yoo ha tó lati pè é ní Ọlọrun tabi Oluwa bi? Rara o. Awọn orilẹ-ede naa ní awọn ọlọrun ati oluwa tiwọn funraawọn. (1 Corinth 8:5) Bawo ni awọn Kristian naa ìbá ti ṣe le fi iyatọ kedere hàn laarin Ọlọrun tootọ naa ati awọn wọnni tí wọn jẹ eke? Kiki nipa lilo orukọ Ọlọrun tootọ naa.
Nipa bayii, ọmọ-ẹhin naa James sọrọ nipa ṣiṣalaye lasiko ipade awọn alagba ní Jerusalem pe: “Symeon ti rohin bi Ọlọrun ní àkọ́ṣe ti bojuwo awọn Keferi, lati yan eniyan ninu wọn fun orukọ rẹ̀. Ati eyi ni ọrọ awọn wolii bá ṣe deedee.” (Iṣe 15:14, 15) Apostle Peter, ninu ọrọ rẹ̀ tí a mọ̀ daradara naa ní ọjọ Pentecost, tọkajade si apá pataki kan ninu ìhìn-iṣẹ Kristian nigba tí ó ṣàyọlò awọn ọrọ wolii Joel pe: “Ẹnikẹni tí ó bá kepe orukọ [Jehofah], a o gbà á là.”—Joel 2:32; Iṣe 2:21.
Apostle Paul kò dá iyemeji silẹ nipa ijẹpataki orukọ Ọlọrun si ara rẹ̀. Ninu lẹta rẹ̀ si awọn ara Rome, oun ṣàyọlò awọn ọrọ kan naa lati ọwọ wolii Joel, ó si tẹsiwaju lati fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ ní iṣiri lati fi igbagbọ wọn hàn ninu gbolohun nì nipa jijade lọ lati waasu nipa orukọ Ọlọrun fun awọn ẹlomiran nitori ki awọn wọnyi, pẹlu, le rí igbala. (Rome 10:13-15) Lẹhin naa oun kọ ninu lẹta rẹ̀ si Timothy pe: “Ki olukuluku ẹni tí nkepe orukọ Jehofah kọ aiṣododo silẹ lákọ̀tán.” (2 Timothy 2:19, NW) Ní opin ọgọrun ọdun kìn-ín-ní, apostle John lo orukọ atọrunwa naa ninu awọn iwe rẹ̀. Ọrọ naa “Hallelujah,” tí ó tumọsi “Ẹ fi ìyìn fun Jah,” farahan leralera ninu iwe Ifihan.—Ifihan 19:1, 3, 4, 6.
Bi o tiwu ki o ri, Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ti sọtẹlẹ pe ipẹhinda kan yoo ṣẹlẹ ninu ijọ Kristian. Apostle Peter ti kọwe pe: “Awọn olukọni eke yoo wà laarin yin.” (2 Peter 2:1; tún wo Matthew 13:36-43; Iṣe 20:29, 30; 2 Thessalonica 2:3; 1 John 2:18, 19.) Awọn ikilọ wọnyi ni a muṣẹ. Abajade kan ni pe orukọ Ọlọrun di eyi tí a rọ́ sẹhin. Ani a tilẹ yọ ọ́ kuro ninu awọn ẹ̀dà ati awọn itumọ Bibeli paapaa! Ẹ jẹ ki a wo bi eyiini ṣe ṣẹlẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 4 Awọn kan dábàá idi miiran: Ó ṣeeṣe ki imọ-ọran Greek ti ní ipa lori awọn Jew. Fun apẹẹrẹ, Philo, olumọran Jew kan ní Alexandria tí ó fẹrẹẹ jẹ ojúgbà kan naa pẹlu Jesu, jẹ ẹni tí olumọran Greek naa Plato ní ipa lori rẹ̀ gidigidi, ẹni tí oun rò pè ó wà labẹ imisi atọrunwa. Lexikon des Judentums [Iwe-aṣọ̀rọ̀jọ-fun-itumọ Ẹkọ-isin Jew] labẹ “Philo,” sọ pe Philo ṣe isopọṣọkan ede ati awọn ero imọ-ọran Greek (Plato) pẹlu igbagbọ awọn Jew tí a gbagbọ pe a kọ́ araye ní taarata lati ọwọ Ọlọrun” ati pe lati ibẹrẹ ni oun ti ní “ipa tí ó ṣee fojuri lori awọn baba ṣọọṣi Kristian.” Philo kọnilẹkọọ pe Ọlọrun jẹ alaile ṣee tumọ ati pe, fun idi yii, ó jẹ alaile ṣee pè lorukọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Aworan olori alufaa Jew yii, pẹlu ami naa tí ó wà lara láwàní rẹ̀ lede Hebrew tí ó tumọsi “Ti Jehofah ni Ìjẹ́mímọ́,” ni a rí ní Vatican
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹgẹ bi itumọ Bibeli lede Germany ti ọdun 1805 yii ti ntọkafihan, nigba tí Jesu kà ninu sinagogue lati inu àkájọ-iwe Isaiah, ó pe orukọ Ọlọrun soke ketekete.—Luke 4:18, 19
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Peter ati Paul lo orukọ Ọlọrun nigba tí wọn ṣàyọlò lati inu asọtẹlẹ Joel.—Iṣe 2:21; Rome 10:13