“Ki A Bọwọ fun Orukọ Rẹ”—Orukọ Wo?
“Ki A Bọwọ fun Orukọ Rẹ”—Orukọ Wo?
IWỌ ha jẹ onisin eniyan kan bi? Laisi iyemeji nigba naa, gẹgẹ bi ọpọ awọn ẹlomiran, iwọ gbagbọ ninu Ẹni Giga Julọ kan. Boya o sì ní ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun adura olokiki naa sí Ẹni yẹn, tí Jesu kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tí a si mọ̀ si Adura Oluwa, tabi Baba Wa Tí Nbẹ Ní Ọrun. Adura naa bẹrẹ bayii: “Baba wa tí nbẹ ní ọrun; ki a bọwọ fun orukọ rẹ.”—Matthew 6:9.
Iwọ ha ti fi igba kan rí ṣe kayefi idi tí Jesu fi fi ‘bibọwọ’ fun, tabi sisọ orukọ Ọlọrun di mímọ́ ṣaaju ninu adura yii? Lẹhin naa, ó mẹnukan awọn ohun miiran bii dídé Ijọba Ọlọrun, didi ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun lori ilẹ-aye ati didari ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wa. Imuṣẹ awọn ibeere-tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ miiran wọnyi ní paripari rẹ̀ yoo tumọsi alaafia tí kò lopin lori ilẹ-aye ati ìyè ainipẹkun fun araye. Iwọ ha le ronu nipa ohunkohun tí ó tún ṣe pataki ju eyiini lọ bi? Bi o tiwu ki o ri, Jesu sọ fun wa pe ki a gbadura ṣaaju ohunkohun fun isọdiimimọ orukọ Ọlọrun.
Kii ṣe nipa àkọsẹ̀bá lasan kan ni Jesu fi kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati fi orukọ Ọlọrun ṣaaju ninu adura wọn. Ó ṣe kedere pe orukọ yẹn ṣe pataki pupọ fun un, niwọn bi oun ti mẹnukan án lọna asọtunsọ ninu awọn adura rẹ̀. Ní akoko-iṣẹlẹ kan nigba tí ó ngbadura ní gbangba si Ọlọrun, a gbọ́ tí ó sọ pe: “Baba, ṣe orukọ rẹ logo!” Ati pe Ọlọrun tikaraarẹ̀ si dahun pe: “Emi ti ṣe e logo ná, emi o si tún ṣe e logo si i.”—John 12:28.
Ní irọlẹ ṣaaju ki Jesu tó kú, ó ngbadura si Ọlọrun ní etigbọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹẹkan si i wọn gbọ́ ọ nigba tí ó ntẹnumọ ijẹpataki orukọ Ọlọrun. Ó sọ pe: “Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn eniyan tí iwọ ti fi fun mi lati inu ayé wá.” Lẹhin naa, ó tún un sọ pe: “Mo ti sọ orukọ rẹ di mímọ̀ fun wọn, emi o si sọ ọ di mímọ̀.”—John 17:6, 26.
Kinni idi tí orukọ Ọlọrun fi ṣe pataki fun Jesu tobẹẹ? Eeṣe tí ó fi fihan pe ó ṣe pataki fun wa, pẹlupẹlu, nipa sisọ fun wa lati gbadura fun ìsọdimímọ́ rẹ̀? Lati loye eyi, a nilati mọ oju tí a fi nwo orukọ ní awọn akoko tí a kọ Bibeli.
Awọn Orukọ ní Akoko Tí A Kọ Bibeli
Ó hàn gbangba pe Jehofah Ọlọrun fi ifẹ-ọkan lati sọ awọn nkan lorukọ si inu eniyan. Ẹda-eniyan akọkọ ní orukọ, Adam. Ninu itan iṣẹda, ọ̀kan lara ohun tí a rohin pe Adam ṣe ṣaaju ni fifun awọn ẹranko lorukọ. Nigba tí Ọlọrun fun Adam ní iyawo, lẹsẹkẹsẹ Adam pè é ní “obinrin” (’Ish·shahʹ, lede Hebrew). Lẹhin naa, ó fun un ní orukọ naa Efa, tí ó tumọsi “Ẹni Alaaye,” nitori pe “oun ni yoo di iya alaaye gbogbo.” (Genesis 2:19, 23; 3:20) Ani lonii paapaa a ntẹle aṣa sisọ awọn eniyan lorukọ. Nitootọ, ó nira lati ronuwoye bi a ṣe le ṣe aṣeyọri laisi awọn orukọ.
Ní akoko awọn ọmọ Israel, bi o tiwu ki o ri, awọn orukọ kii ṣe akọle kan lasan. Wọn tumọsi ohun kan. Fun apẹẹrẹ, orukọ Isaac, “Ẹ̀rín,” jẹ irannileti ẹ̀rín awọn obi rẹ̀ tí wọn ti darugbo nigba tí wọn kọ́kọ́ gbọ́ pe awọn yoo ní ọmọ kan. (Genesis 17:17, 19; 18:12) Orukọ Esau tumọsi “Onírun” tí ó nṣapejuwe ami tí a le fojuri kan. Orukọ rẹ̀ miiran, Edom, “Pupa,” tabi “Apọ́nbéporẹ́,” jẹ́ irannileti kan pe ó ta ogún-ìbí rẹ̀ fun àwo ìpẹ̀tẹ̀ pupa. (Genesis 25:25, 30-34; 27:11; 36:1) Jacob, bi o tilẹ jẹ pe ó fi kiki iwọnba diẹ kere si èjìrẹ́ arakunrin rẹ̀, Esau, ra ogun-ìbí naa lọwọ Esau ó si gba ibukun akọbi lati ọ̀dọ̀ baba rẹ̀.
Lati igba yii, itumọ orukọ Jacob ni “Dídi Gìgísẹ̀ Mú” tabi “Afèrúgbapò.” (Genesis 27:36) Bakan naa ni orukọ Solomon, ẹni tí Israel gbadun alaafia ati aasiki ní igba-ijọba rẹ̀, tumọsi “Alalaafia.”—1 Chronicles 22:9.
Nipa bayii, The Illustrated Bible Dictionary (Idipọ Kìn-ín-ní, oju-ewe 572) sọ ọrọ tí ó tẹle e yii: “Ayẹwo ọrọ naa ‘orukọ’ ninu Majẹmu Laelae ṣe iṣipaya bi ohun tí ó tumọsi ti pọ̀ tó lede Hebrew. Orukọ kii ṣe akọle kan lasan, ṣugbọn ó niiṣe pẹlu akopọ-animọ-iwa ẹni naa tí orukọ naa iṣe tirẹ̀ niti gidi.”
Otitọ-iṣẹlẹ naa pe Ọlọrun nwo orukọ gẹgẹ bi ohun tí ó ṣe pataki ni a rí niti pe, nipasẹ angeli kan, ó fun awọn obi ọjọ iwaju ti John Oniribọmi ati Jesu ní itọni nipa orukọ tí awọn ọmọkunrin wọn yoo nilati jẹ́. (Luke 1:13, 31) Ati pe ní awọn akoko kan oun yí awọn orukọ pada, tabi fun awọn eniyan ní afikun orukọ, lati fi ipa tí wọn yoo kó ninu ète rẹ̀ hàn. Fun apẹẹrẹ, nigba tí Ọlọrun sọtẹlẹ pe iranṣẹ rẹ̀ Abram (“Baba Ìgbéga”) yoo di baba fun ọpọ orilẹ-ede ni Oun yí orukọ rẹ̀ pada si Abraham (“Baba Awọn Ògìdìgbó”). Ó si tún yí orukọ iyawo Abraham pada, Sarai (“Oní-gbolohun-asọ̀”), si Sarah (“Ọmọ-alade-obinrin”), niwọn bi oun yoo nilati di iya iru-ọmọ Abraham.—Genesis 17:5, 15, 16; fiwe Genesis 32:28; 2 Samuel 12:24, 25.
Jesu, pẹlupẹlu, mọ ijẹpataki awọn orukọ ní àmọ̀dunjú, ó si tọkasi Peter nigba tí ó nfun un ní anfaani iṣẹ-isin kan. (Matthew 16:16-19) Ani awọn ẹda ẹmi paapaa ní orukọ. Awọn mejeeji tí a mẹnukan ninu Bibeli ni Gabriel ati Michael. (Luke 1:26; Jude 9) Ati pe nigba ti eniyan nfun awọn ohun alailẹmi bii awọn irawọ, planet, ilu, oke ati odò ní orukọ, ó wulẹ nṣe afarawe Ẹlẹdaa rẹ̀ ni. Fun apẹẹrẹ, Bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun npe gbogbo awọn irawọ ní orukọ.—Isaiah 40:26.
Bẹẹ ni, orukọ ṣe pataki loju Ọlọrun, oun si ti fi ifẹ-ọkan naa sinu eniyan lati fi awọn orukọ ṣe ìdánimọ̀ awọn nkan. Idi rẹ̀ niyii tí awọn angeli, eniyan, ẹranko, ati awọn irawọ ati awọn ohun alailẹmi miiran fi ní orukọ. Eyi yoo ha wà ní iṣedeedee-ṣọkan délẹ̀ fun Ẹlẹdaa gbogbo awọn nkan wọnyi lati fi ara rẹ̀ silẹ lailorukọ bi? Ó daju pe eyiini kò rí bẹẹ, ní pataki loju awọn ọrọ onipsalm naa pe: “Ki gbogbo eniyan maa fi ibukun fun orukọ [Ọlọrun] mímọ́ lae, ati laelae.”—Psalm 145:21.
The New International Dictionary of New Testament Theology (Idipọ Keji, oju-ewe 649) sọ pe: “Ọ̀kan lara awọn ohun ipilẹ ati awọn apá pataki ninu iṣipaya Bibeli ni otitọ-iṣẹlẹ naa pe Ọlọrun kò ṣalai ní orukọ kan: ó ní orukọ ti ara-ẹni kan, nipa eyi tí a lè, tí a si gbọdọ fi pè é pẹlu ifọkansin ninu ibeere-tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.” Dajudaju Jesu ní orukọ naa lọkan nigba ti ó kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Baba wa tí nbẹ ninu awọn ọrun, ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́.”—Matthew 6:9, NW.
Loju gbogbo eyi, ó hàn gbangba-gbàngbà pe ó ṣe pataki fun wa lati mọ ohun tí orukọ Ọlọrun jẹ. Iwọ ha mọ orukọ ti ara-ẹni tí Ọlọrun njẹ́ bi?
Kinni Orukọ Ọlọrun?
Lọna yiyanilẹnu, àfàìmọ̀ ni kò jẹ́ eyi tí ó pọ̀ julọ ninu ọgọrọọrun araadọta ọkẹ awọn ọmọ-ẹgbẹ ṣọọṣi Kristendom ni yoo ní iṣoro ní didahun ibeere yii. Awọn miiran yoo wipe orukọ Ọlọrun ni Jesu Kristi. Sibẹ Jesu ngbadura si ẹnikan yatọ si ara rẹ̀ nigba tí ó sọ pe: “Mo ti sọ orukọ rẹ di mímọ̀ fun awọn eniyan tí iwọ ti fi fun mi lati inu ayé wá.” (John 17:6) Oun ngbadura si Ọlọrun ní ọrun, gẹgẹ bi ọmọkunrin kan tí nbá baba rẹ̀ sọrọ. (John 17:1) Orukọ Baba rẹ̀ ọrun ni a nilati “bọwọ fun,” tabi “sọ di mímọ́.”
Sibẹ ọpọlọpọ awọn Bibeli ode-oni ni kò ní orukọ naa ninu, lilo rẹ̀ si jẹ eyi tí ó ṣọ̀wọ́n ninu awọn ṣọọṣi. Fun idi yii, jinna patapata si jíjẹ́ eyi tí a “bọwọ fun,” araadọta ọkẹ awọn olùka Bibeli ti padanu rẹ̀. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ ọna kan tí awọn atumọ Bibeli ti gbà huwa si orukọ Ọlọrun, ṣayẹwo kiki ẹsẹ kanṣoṣo pere nibi tí ó ti farahan: Psalm 83:18. Nihin yii ni a rí bi a ti ṣe tumọ ẹsẹ iwe-mimọ yii ninu oriṣi Bibeli mẹrin:
“Jẹ ki wọn mọ̀ pe iwọ nikanṣoṣo, ẹni tí orukọ rẹ̀ njẹ́ OLUWA, ni Ọga Ogo lori gbogbo ilẹ-aye.” (Revised Standard Version ti 1952)
“Lati kọ́ wọn pe iwọ, Óò Ayeraye, iwọ ni Ọlọrun Ọga Ogo lori gbogbo ayé.” (A New Translation of the Bible, lati ọwọ James Moffatt, ti 1922)
“Jẹ ki wọn mọ eyi: iwọ nikan ni ó njẹ́ orukọn naa Yahweh, Ọga Ogo lori gbogbo ayé.” (Jerusalem Bible ti Catholic ti 1966)
“Ki awọn eniyan ki ó le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹnikanṣoṣo tí njẹ́ JEHOFAH, ni ọga ogo lori gbogbo ilẹ-aye.” (Authorized, tabi King James Version, ti 1611)
Eeṣe tí orukọ Ọlọrun fi yatọ sira tobẹẹ ninu awọn itumọ wọnyi? Orukọ rẹ̀ ha ni OLUWA, Ayeraye, Yahweh tabi Jehofah? Tabi gbogbo awọn wọnyi ha wà ní itẹwọgba bi?
Lati dahun eyi, a nilati ranti pe kii ṣe ede Gẹẹsi ni a fi kọ Bibeli ní ipilẹṣẹ. Awọn onkọwe Bibeli jẹ awọn ara Hebrew, wọn si fi awọn ede Hebrew ati Greek ti igba ayé wọn kọ eyi tí ó pọ̀ julọ ninu rẹ̀. Pupọ ninu wa ni kò le sọ awọn ede atijọ wọnni. Ṣugbọn a ti tumọ Bibeli si ọpọlọpọ ede ode-oni, a si le lo awọn itumọ wọnyi nigba tí a bá fẹ́ lati ka Ọrọ Ọlọrun.
Awọn Kristian ní ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ fun Bibeli wọn si gbagbọ lọna rere pe “gbogbo Iwe-mimọ ni ó ní imisi Ọlọrun.” (2 Timothy 3:16) Fun idi yii, ẹru-iṣẹ wiwuwo kan ni titumọ Bibeli jẹ. Bi ẹnikan bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe iyipada tabi fi apakan ninu awọn ọrọ inu Bibeli silẹ, onitọhun ntojubọ Ọrọ onimisi naa laini ọla-aṣẹ. Si iru ẹni bẹẹ ni ikilọ naa tí ó wà ninu Iwe-mimọ nbawi pe: “Bi ẹnikẹni bá fikun wọn, Ọlọrun yoo fikun awọn arun tí a kọ sinu iwe yii fun un. Bi ẹnikẹni bá si mú kuro ninu ọrọ iwe isọtẹlẹ yii, Ọlọrun yoo si mú ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìyè.”—Ifihan 22:18, 19; tún wo Deuteronomy 4:2.
Laisi iyemeji pupọ ninu awọn atumọ Bibeli bọwọ fun Bibeli wọn si fi pẹlu otitọ-inu nifẹẹ si mímú un di eyi tí ó ṣee loye ní sanmanni ode-oni. Ṣugbọn awọn atumọ kò si labẹ imisi. Pupọ ninu wọn ní awọn ero alagbara, pẹlupẹlu, lori awọn ọran isin, ó si ṣeeṣe ki awọn ero-ọkan ati iwa-yíyan-nkan-ṣaaju ti ara-ẹni ní ipa lori wọn. Pẹlupẹlu wọn lè, gẹgẹ bi ẹda-eniyan, ṣina tabi ṣaṣiṣe ninu idajọ.
Fun idi yii, a ní ẹtọ lati beere awọn ibeere pataki diẹ: Kinni orukọ Ọlọrun gan-an? Ati pe eeṣe tí awọn oriṣiriṣi itumọ Bibeli fi ní orukọ ọtọọtọ fun Ọlọrun? Ní fifi idi idahun si awọn ibeere wọnyi mulẹ, a le ṣẹ́rípadà si iṣoro wa ti ipilẹṣẹ: Eeṣe tí ìsọdimímọ́ orukọ Ọlọrun fi ṣe pataki tobẹẹ?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Awọn angeli, eniyan, ẹranko, ati awọn irawọ ati awọn ohun alailẹmi miiran ní orukọ. Eyi yoo ha wà ní iṣedeedee-ṣọkan délẹ̀ fun Ẹlẹdaa gbogbo awọn nkan wọnyi lati jẹ alailorukọ bi?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ó ṣe kedere pe orukọ Ọlọrun ṣe pataki pupọ fun Jesu, niwọn bi ó ti mẹnukan án lọna asọtunsọ ninu awọn adura rẹ̀