Orukọ Ọlọrun—Itumọ ati Pípè Rẹ̀
Orukọ Ọlọrun—Itumọ ati Pípè Rẹ̀
Ọ̀KAN lara awọn onkọwe Bibeli beere pe: “Tani ó ti goke lọ si ọrun, tí ó si ti sọkalẹ wá? Tani ó kó afẹfẹ jọ ní ọwọ rẹ̀? Tani ó di omi sinu aṣọ; tani ó fi gbogbo opin ayé lelẹ? Orukọ rẹ̀ tii jẹ́, ati orukọ ọmọ rẹ̀ tii jẹ́, bi iwọ bá lè mọ̀ ọ́n?” (Owe 30:4) Bawo ni awa ṣe le ṣe awari ohun tí orukọ Ọlọrun jẹ? Ibeere pataki ni eyi jẹ. Iṣẹda jẹ ami-ẹri alagbara kan pe Ọlọrun gbọdọ wà, ṣugbọn iṣẹda kò sọ orukọ rẹ̀ fun wa. (Rome 1:20) Niti tootọ, awa kò le mọ orukọ Ọlọrun lae ayafi bi Ẹlẹdaa funraarẹ̀ bá sọ fun wa. Oun si ti ṣe eyi ninu Iwe oun tikaraarẹ̀, Bibeli Mimọ.
Ní akoko-iṣẹlẹ olokiki kan, Ọlọrun pe orukọ ara rẹ̀, ní sisọ asọtunsọ rẹ̀ si etigbọ Moses. Moses kọ akọsilẹ iṣẹlẹ yẹn tí a ti fi pamọ sinu Bibeli titi di ọjọ tiwa. (Exodus 34:5) Ani Ọlọrun paapaa tilẹ fi “ìka” rẹ̀ kọ orukọ ara rẹ̀. Nigba tí ó ti fun Moses ní ohun tí a npè ní Ofin Mẹwa lonii, Ọlọrun kọ wọn silẹ lọna iṣẹ iyanu. Akọsilẹ naa wipe: “Ó si fi wàláà ẹri meji, wálàá okuta, tí a fi ìka Ọlọrun kọ.” (Exodus 31:18) Orukọ Ọlọrun farahan ní igba mẹjọ ninu Ofin Mẹwa ti ipilẹṣẹ. (Exodus 20:1-17) Nipa bayii Ọlọrun funraarẹ̀ ti ṣe iṣipaya orukọ rẹ̀ fun eniyan nipa sisọ ọ lẹnu ati kikọ ọ́ silẹ. Nigba naa, kinni orukọ yẹn?
Lede Hebrew bi a ṣe nkọ ọ́ niyii יהוה. Awọn lẹta mẹrẹẹrin wọnyi, tí a npè ní Tetragrammaton, ni a nkà lati apá ọtun si apá osi lede Hebrew, a sì lè kọ ọ́ silẹ ní ọpọ awọn ede ode-oni gẹgẹ bi YHWH tabi JHVH. Orukọ Ọlọrun, tí a fi awọn konsonant mẹrin wọnyi ṣoju fun, farahan ní eyi tí ó fẹrẹẹ tó nkan bii 7,000 igba ninu “Majẹmu Laelae,” ti ipilẹṣẹ, tabi Iwe-mimọ Hebrew.
Orukọ naa jẹ ọ̀kan lara awọn ọrọ-iṣe lede Hebrew ha·wahʹ (הוה) tí ó tumọsi “lati dà,” ati pe niti gasikia ó tumọsi pe “Ó Nmú Ki Ó Wà.” * Nipa bayii orukọ Ọlọrun fi i hàn gẹgẹ bi Ẹni naa tí nmú awọn ileri rẹ̀ ṣẹ lọna itẹsiwaju tí kii si bàá tì ninu ṣiṣe aṣeyọri awọn ete rẹ̀. Kiki Ọlọrun tootọ nikanṣoṣo ni ó le jẹ iru orukọ onitumọ bẹẹ.
Iwọ ha ranti awọn oniruuru ọna tí orukọ Ọlọrun gbà farahan ninu Psalm 83:18, gẹgẹ bi a ti fihan ní apá iṣaaju (oju-ewe 5) bi? Meji lara awọn itumọ wọnyẹn ní kiki awọn akọle (“OLUWA,” “Ayeraye”) gẹgẹ bi awọn adipo fun orukọ Ọlọrun. Ṣugbọn ninu meji lara wọn, Yahweh ati Jehofah, iwọ le rí awọn lẹta orukọ Ọlọrun mẹrẹẹrin naa. Bi o tiwu ki o ri, pípè rẹ̀ yatọ. Eeṣe?
Bawo Ni A Ṣe Npe Orukọ Ọlọrun?
Otitọ naa ni pe, kò si ẹnikan tí ó mọ̀ daju bi a ti ṣe npe orukọ Ọlọrun ní ibẹrẹ. Eeṣe tí kò fi si? Ede akọkọ naa tí a lò ninu kikọ Bibeli jẹ Hebrew, nigba tí a si ṣe akọsilẹ ede Hebrew, awọn onkọwe kọ kiki konsonant nikan—kii ṣe awọn fawẹli. Fun idi yii, nigba tí awọn onkọwe onimisi kọ orukọ Ọlọrun, wọn ṣe ohun kan naa lọna ti ẹda wọn si kọ kiki awọn konsonant nikan.
Nigba tí ó jẹ pe ede Hebrew atijọ jẹ ede tí a nsọ lojoojumọ, eyi kò dá iṣoro kankan silẹ. Pípe Orukọ naa jẹ ohun tí awọn ọmọ Israel mọ̀ daradara, nigba tí wọn si rí i tí a kọ ọ silẹ wọn fi awọn fawẹli fun un laisi rironu (gan-an gẹgẹ bi fun onkawe ede Gẹẹsi kan, igekuru naa “Ltd.” duro fun “Limited” ati “bldg.” duro fun “building”).
Ohun meji ṣẹlẹ lati yí ipo yii pada. Lakọkọ, ero tí ó kún fun igbagbọ-asan kan dide laarin awọn Jew pe ó jẹ ohun tí ó lodi lati pe orukọ atọrunwa naa soke; nitori naa nigba tí wọn bá kan ọrọ naa ninu Bibeli kika ọrọ Hebrew naa ’Adho·naiʹ (“Oluwa Ọba Alaṣẹ”) ni wọn maa npè. Siwaju si i, bi akoko ti nlọ, ede Hebrew naa funraarẹ̀ di eyi tí a dẹkun sisọ ninu ijumọsọrọpọ ojoojumọ, ati pe lọna yii ni pipe orukọ Ọlọrun lede Hebrew ipilẹṣẹ di eyi tí a gbagbe ní paripari rẹ̀.
Lati rí i daju pe pípè naa lede Hebrew lapapọ ni a kò nilati padanu, awọn ọmọwe Jew ti sáà akoko 500 si 1,000 C.E. humọ eto kan nipa awọn ami lati duro fun awọn fawẹli sisọnu naa, wọn si fi awọn wọnyi si ayika awọn konsonant naa ninu Bibeli ti ede Hebrew. Nipa bayii awọn fawẹli ati konsonant ni a kọsilẹ, ati pípè rẹ̀ gẹgẹ bi ó ti wà nigba yẹn ni a si pamọ.
Nigba tí ó kan orukọ Ọlọrun, dipo fifi awọn ojulowo ami fawẹli si ayika rẹ̀ ninu awọn ọran tí ó pọ̀ julọ wọn fi awọn ami fawẹli miiran sibẹ lati rán onkawe leti pe ó nilati sọ ’Adho·naiʹ. Lati inu eyi ni sípẹ́lì naa Iehouah ti wá, ati pe, ní paripari rẹ̀, Jehofah di pípè naa tí a tẹwọgba fun orukọ atọrunwa naa ní Yoruba. Eyi si di awọn ohun ipilẹ tí ó wà ninu orukọ Ọlọrun mú lati inu ede Hebrew ti ipilẹṣẹ.
Pípè Wo Ni Iwọ Yoo Lò?
Sibẹsibẹ, nibo ni awọn pípè naa bii Yahweh ti wá? Awọn wọnyi ni a dabaa lati ọwọ awọn ọmọwe ode-oni tí wọn ngbiyanju lati ronu nipa pipe orukọ Ọlọrun ní ipilẹṣẹ. Awọn kan—bi ó tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo wọn—nimọlara gidigidi pe awọn ọmọ Israel ṣaaju akoko tí Jesu wà lori ilẹ-aye npe orukọ Ọlọrun ní Yahweh. Ṣugbọn kò si ẹni tí ó lè mọ̀ daju. Boya wọn pè é lọna yẹn, tabi bẹẹ kọ.
Ṣugbọn, ọpọlọpọ yan pípè naa Jehofah. Eeṣe? Nitori pe ó ní itankalẹ ati ìmọ̀dunjú tí Yahweh kò ní. Sibẹ, ki yoo ha sàn jù lati lo ọna tí ó tubọ sunmọ pípè ti ipilẹṣẹ bi? Kii ṣe bẹẹ niti gidi, nitori pe iyẹn kii ṣe aṣa naa pẹlu awọn orukọ Bibeli.
Lati mú apẹẹrẹ tí ó gbayì julọ, ronu nipa orukọ Jesu. Iwọ ha mọ bi awọn ara ile ati awọn ọ̀rẹ́ Jesu ṣe npè é ninu ibanisọrọpọ ojoojumọ nigba tí ó ngoke agba ní Nazareth? Otitọ naa ni pe, kò si ẹda-eniyan kan tí ó mọ̀ daju, bi o tilẹ jẹ pe ó ṣeeṣe ki ó jẹ ohun kan bii Yeshua (tabi boya Yehoshua). Lọna tí ó daniloju kii ṣe Jesu.
Bi o tiwu ki o ri, nigba tí a ṣe akọsilẹ igbesi-aye rẹ̀ lede Greek, awọn onkọwe onimisi naa kò gbiyanju lati pa pípè yẹn mọ́ lede Hebrew ti ipilẹṣẹ. Kaka bẹẹ, wọn kọ orukọ naa lede Greek, I·e·sousʹ. Lonii, ọna tí ó yatọ ni a ngbà kọ ọ́ ní ibamu pẹlu ede olùka Bibeli. Awọn olùka Bibeli lede Spain nbá Jesús pade (wọn npè é ní Hes·soosʹ). Sípẹ́lì ti awọn ara Italy ni Gesù (wọn npè é ní Djay·zooʹ). Sípẹ́lì awọn ara Germany ni Jesus (wọn npè é ní Yayʹsoos).
A ha gbọdọ dáwọ̀ lilo orukọ Jesu duro nitori pe ọpọlọpọ ninu wa, tabi gbogbo wa paapaa, kò mọ pípè rẹ̀ niti gidi ní ipilẹṣẹ? Titi di akoko yii, kò si atumọ kan tí ó tíì dabaa eyi. A fẹ́ lati lo orukọ naa, nitori pe ó fi ayanfẹ Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ẹjẹ-iwalaaye rẹ̀ fun wa hàn. Eyiini yoo ha jẹ fifi ọlá fun Jesu lati yọ mimẹnukan orukọ rẹ̀ kuro patapata ninu Bibeli ki a si fi kiki akọle kan bii “Olukọ,” tabi “Alarina” dipo rẹ̀ bi? Dajudaju kò rí bẹẹ! A le bá Jesu tan nigba tí a bá lo orukọ rẹ̀ lọna tí ó wọpọ tí a ngbà pè é lede wa.
Awọn alaye kan naa ni a le ṣe nipa gbogbo awọn orukọ tí a nkà ninu Bibeli. A npè wọn lede tiwa funraawa, a kò si gbiyanju lati ṣafarawe pípè ti ipilẹṣẹ naa. Nipa bayii a nsọ pe “Jeremiah,” kii ṣe Yir·meyaʹhu. Bakan naa ni a npe Isaiah, bi ó tilẹ jẹ pe lọjọ tirẹ̀ wolii yii ni ó ṣeeṣe ki a mọ̀ si Yeshae·yaʹhu. Ani awọn ọmọwe tí wọn mọ bi a ti npe awọn orukọ wọnyi ní ipilẹṣẹ paapaa nlo pípè ti ode-oni, kii ṣe ti igba laelae, nigba ti wọn bá nsọrọ nipa wọn.
Ohun kan naa si jẹ otitọ nipa orukọ Jehofah. Ani bi o tilẹ jẹ pe pipe Jehofah ní ode-oni le ṣalai rí bakan naa pẹlu bi a ti ṣe npè é ní ipilẹṣẹ, eyi lọnakọna kò dín ijẹpataki orukọ naa kù. Ó nfi Ẹlẹdaa naa hàn, Ọlọrun alaaye, Ọga Ogo ẹni tí Jesu sọ pe: “Baba wa tí nbẹ ninu awọn ọrun, ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́.”—Matthew 6:9, NW.
‘A Kò Lè Fi Èrú Gba Ipo Rẹ̀’
Niwọn bi pupọ awọn atumọ ti faramọ pípè naa Yahweh, New World Translation ati diẹ lara awọn itumọ miiran nbá a niṣo lati maa lo Jehofah nitori pe awọn eniyan ti mọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú fun ọpọ sanmanni. Siwaju si i, ó ní ninu awọn lẹta mẹrẹẹrin ti Tetragrammaton, YHWH tabi JHVH * gẹgẹ bi awọn iyoku ti ní in.
Ní iṣaaju, ọjọgbọn ara Germany naa Gustav Friedrich Oehler ṣe iru ipinnu kan naa fun idi kan naa yii. Oun jiroro awọn oniruuru pípè tí ó si wá si ipari-ero naa pe: “Lati ori koko yii lọ mo lo ọrọ naa Jehofah, nitori pe niti gasikia, orukọ yii kò ṣajeji si wa mọ́ ninu awọn ilo-ọrọ wa, a kò si le fi èrú gba ipo rẹ̀.”—Theologie des Alten Testaments (Ẹkọ-isin ti Majẹmu Laelae), itẹjade ẹlẹẹkeji, tí a tẹ̀ ní 1882, oju-ewe 143.
Bakan naa, ninu iwe rẹ̀ Grammaire de l’hébreu biblique (Grammar of Biblical Hebrew), itẹjade ti 1923, ninu alaye eti iwe ní oju-ewe 49, ọmọwe onisin Jesuit Paul Joüon sọ pe: “Ninu awọn itumọ tiwa, dipo orukọ (àbámodá) naa Yahweh, awa ti lo Jéhovah . . . eyi tí gbogbo awọn tí wọn mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà fohunṣọkan pẹlu ninu ede French.” Ninu ọpọlọpọ awọn ede miiran awọn atumọ Bibeli lo iru kan naa tí ó farajọ awọn tí a tọkafihan ninu apoti tí ó wà ní oju-ewe 8.
Njẹ, nigba naa, ó ha buru lati lo orukọ naa Yahweh bi? Rara o. Ó kàn wulẹ jẹ pe a nireti pe orukọ naa Jehofah yoo ṣe alabapade iṣarasihuwa kiakia lati ọ̀dọ̀ onkawe naa nitori pe ó jẹ eyi tí “a tẹwọgba” sinu ọpọlọpọ awọn ede. Ohun tí ó ṣe pataki ni pe ki a maa lo orukọ naa ki a si maa kede rẹ̀ fun awọn ẹlomiran. “Ẹ fi ọpẹ fun Jehofah, ẹyin eniyan! Ẹ kepe orukọ rẹ̀. Ẹ sọ awọn ibalo rẹ̀ di mímọ̀ laarin awọn eniyan. Ẹ mẹnukan án pe orukọ rẹ̀ ni a gbega.”—Isaiah 12:4, NW.
Ẹ jẹ ki a wo bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ti huwa ní ibamu pẹlu aṣẹ yẹn jalẹ awọn ọgọrọọrun ọdun.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Wo Appendix 1A ninu New World Translation of the Holy Scriptures, itẹjade 1984.
^ ìpínrọ̀ 22 Wo Appendix 1A ninu New World Translation of the Holy Scriptures, itẹjade 1984.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Oniruuru awọn akẹkọọ ni wọn ní awọn oniruuru èrò nipa bi a ti npe orukọ naa YHWH ní ipilẹṣẹ.
Ninu The Mysterious Name of Y.H.W.H., oju-ewe 74, Dr. M. Reisel sọ pe “fifi ohùn sọ Tetragrammaton gbọdọ jẹ YeHūàH tabi YaHūàH ní ipilẹṣẹ.”
Canon D. D. Williams ti Cambridge sọ pe “ẹri-ami ntọkafihan pe Jāhwéh kii ṣe pípè tootọ naa fun Tetragrammaton . . . Orukọ Naa funraarẹ̀ ṣeeṣe ki ó jẹ JĀHÔH.”—Zeitschrift für die alttestamentliche Wissenschaft (Periodical for Old Testament Knowledge), 1936, Idipọ 54, oju-ewe 269.
Ninu iwe atumọ-ọrọ ti Revised Segond Version, oju-ewe 9, awọn alaye tí wọn tẹle e yii ni a ṣe: “Pípè naa Yahvé tí a lò ninu awọn itumọ ti lọọlọọ yii ni a gbeka ori awọn ẹri atijọ, ṣugbọn wọn kò ṣee gbarale. Bi ẹnikan bá ronu nipa awọn orukọ ti ara-ẹni tí wọn ní ninu orukọ atọrunwa naa, bii orukọ Hebrew naa fun wolii Elijah (Eliyahou) pípè naa le jẹ Yaho tabi Yahou.”
Ní 1749 ọmọwe Bibeli ara Germany naa Teller sọ nipa awọn oniruuru ọna diẹ tí a gba npe orukọ Ọlọrun tí oun ti kà: “Diodorus lati Sicily, Marcrobius, Clemens Alexandrinus, Saint Jerome ati Origenes kọ Jao; awọn ara Samaria, Epiphanius, Theodoretus, Jahe, tabi Jave; Ludwig Cappel npè é ní Javoh; Drusius, Jahve; Hottinger, Jehva; Mercerus, Jehovah; Castellio, Jovah; ati le Clerc, Jawoh, tabi Javoh.”
Nipa bayii ó hàn gbangba-gbàngbà pe pípè naa ti ipilẹṣẹ ni a kò mọ̀ mọ́. Kò si ṣe pataki. Bi ó bá jẹ bẹẹ, nigba naa Ọlọrun funraarẹ̀ ìbá ti rí i daju pe a pa á mọ́ fun wa lati lò. Ohun tí ó ṣe pataki ni lati lo orukọ Ọlọrun ní ibamu pẹlu pípè naa tí gbogbo eniyan tẹwọgba lede tiwa funraawa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Orukọ atọrunwa naa ní oniruuru awọn ede, ní titọkafihan pe gbogbo ayé ni ó tẹwọgba orukọ naa Jehofah
Awabakal - Yehóa
Bugotu - Jihova
Cantonese - Yehwowah
Danish - Jehova
Dutch - Jehovah
Efik - Jehovah
English - Jehovah
Fijian - Jiova
Finnish - Jehova
French - Jéhovah
Futuna - Ihova
German - Jehova
Hungarian - Jehova
Igbo - Jehova
Italian - Geova
Japanese - Ehoba
Maori - Ihowa
Motu - Iehova
Mwala-Malu - Jihova
Narrinyeri - Jehovah
Nembe - Jihova
Petats - Jihouva
Polish - Jehowa
Portuguese - Jeová
Romanian - Iehova
Samoan - Ieova
Sotho - Jehova
Spanish - Jehová
Swahili - Yehova
Swedish - Jehova
Tahitian - Iehova
Tagalog - Jehova
Tongan - Jihova
Venda - Yehova
Xhosa - uYehova
Yoruba - Jehofah
Zulu - uJehova
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
“Jehofah” ti di mímọ̀ jakejado ayé gẹgẹ bi orukọ Ọlọrun ani ninu awọn ayika-ọrọ tí kii ṣe ti Bibeli paapaa.
Franz Schubert ṣe akojọ ohùn-orin fun awọn ọrọ-orin naa tí akọle rẹ̀ njẹ “Olodumare,” tí Johann Ladislav Pyrker kọ, ninu eyi tí orukọ Jehofah farahan lẹẹmeji. Wọn tún lò ó ní ipari iran tí ó kẹhin ere ori ìtàgé olorin naa ti “Nabucco.”
Ní afikun, akorinjọ ara France naa Arthur Honegger fun orukọ naa Jehofah ní ijẹpataki ninu orin rẹ̀ tí a npè ní “Ọba David,” ati pe ìjìmì onṣewe ara France naa Victor Hugo lò ó ninu eyi tí ó ju ọgbọ̀n lọ ninu awọn iṣẹ rẹ̀. Oun ati Lamartine kọ awọn ewì tí akọle rẹ̀ njẹ “Jehovah.”
Ninu iwe naa Deutsche Taler (The German Taler), tí a tẹjade ní 1967 lati ọwọ Ile Ifowopamọ Ijọba Apapọ Germany, aworan ọ̀kan lara awọn owó oniwura ni orukọ naa “Jehovah” wà lara rẹ̀, Reichstaler ti 1634 lati Duchy ti Silesia. Niti aworan naa tí ó wà ní odikeji owó oniwura naa, ó sọ pe: “Labẹ orukọ dídán naa JEHOVAH, apata alade kan pẹlu aworan-ami Silesian ndide duro laarin awọn awọsanma.”
Ninu ile awọn ohun iṣẹmbaye ní Rudolstadt, East Germany, iwọ le rí orukọ naa JEHOVAH tí a kọ gàdàgbà-gàdàgbà si ọrùn-ẹ̀wù ihamọra ogun tí Gustavus II Adoph, ọba Sweden ní ọgọrun ọdun kẹtadinlogun, ti fi igba kan rí wọ̀.
Nipa bayii, fun ọpọlọpọ awọn ọgọrọọrun ọdun ni Jehofah ti di ọna tí gbogbo ayé mọ̀ ní àmọ̀dunjú lati fi pe orukọ Ọlọrun, ati pe awọn eniyan tí ngbọ́ ọ lẹsẹkẹsẹ yoo mọ ẹni tí a nsọrọ nipa rẹ̀. Gẹgẹ bi Professor Oehler ti sọ, “Orukọ yii ti di eyi tí a tẹwọgba jù ninu ilo-ọrọ wa, ati pe a kò si le fi èrú gba ipo rẹ̀.”—Theologie des Alten Testaments (Ẹkọ-isin Majẹmu Laelae).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ẹkunrẹrẹ alaye angeli kan pẹlu orukọ Ọlọrun, tí a rí lori iboji Pope Clement Kẹtala ní St. Peter’s Basilica, Vatican
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọpọ awọn owó oniwura ni a ṣe pẹlu orukọ Ọlọrun. Ẹyọkan yii, ti ọdun 1661, wá lati Nuremberg, Germany. Ọrọ Latin naa kà pe: “Labẹ ojiji awọn ìyẹ́-apá rẹ”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Nigba laelae, orukọ Ọlọrun lọna Tetragrammaton ni a fi ṣe apakan ọ̀ṣọ́ ọpọlọpọ awọn ile isin
Fourvière Catholic Basilica, Lyons, France
Bourges Cathedral, France
Ṣọọṣi ní La Celle Dunoise, France
Ṣọọṣi ní Digne, guusu France
Ṣọọṣi ní São Paulo, Brazil
Strasbourg Cathedral, France
Saint Mark’s Cathedral, Venice, Italy
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Orukọ Jehofah gẹgẹ bi ó ti farahan nibi tí awọn ajẹjẹ anikandagbe wà ní Bordesholm, Germany;
bi ó ti wà lara owó oniwura ti Germany ní ọdun 1635;
bi ó ti wà lara ilẹkun ṣọọṣi kan ní Fehmarn, Germany;
ati bi ó ti wà lara okuta-sàréè ọdun 1845 kan ní Harmannschlag, Lower Austria