Ìdáríjì
Ṣé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá lóòótọ́?
Tún wo 2Pe 3:9
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 78:40, 41; 106:36-46—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ba Jèhófà nínú jẹ́, léraléra ló dárí jì wọ́n
-
Lk 15:11-32—Jésù fi Jèhófà wé Bàbá aláàánú kan tí ọmọ ẹ̀ hùwà burúkú, àmọ́ tó dárí ji ọmọ náà nígbà tó ronú pìwà dà
-
Kí ni Jèhófà ṣe ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Heb 9:22-28—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé ẹbọ ìràpadà Jésù nìkan ló mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
-
Ifi 7:9, 10, 14, 15—Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” jì wọ́n torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù
-
Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí la gbọ́dọ̀ ṣe táwọn míì bá ṣẹ̀ wá?
Mt 6:14, 15; Mk 11:25; Lk 17:3, 4; Jem 2:13
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Job 42:7-10—Kó tó di pé Jèhófà wo Jóòbù sàn, tó sì bù kún un, ó ní kí Jóòbù gbàdúrà fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó sọ̀rọ̀ burúkú sí i
-
Mt 18:21-35—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa ká sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 32:1-5; 51:1, 2, 16, 17—Nígbà tí Ọba Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an ó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn
-
Jem 5:14-16—Jémíìsì sọ pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, ó yẹ ká sọ fáwọn alàgbà
-
Àwọn àyípadà wo la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Ọb 21:27-29; 2Kr 18:18-22, 33, 34; 19:1, 2—Nígbà tí Ọba Áhábù gbọ́ pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò ronú pìwà dà tọkàntọkàn torí náà Jèhófà ò dárí jì í
-
2Kr 33:1-16—Ọba Mánásè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó burú gan-an, àmọ́ Jèhófà dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Mánásè gbìyànjú láti fòpin sí ìbọ̀rìṣà, káwọn èèyàn lè máa jọ́sìn Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé ó yí pa dà lóòótọ́
-
Ṣé Jèhófà máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà pátápátá?
Sm 103:10-14; Ais 1:18; 38:17; Jer 31:34; Mik 7:19
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Sa 12:13; 24:1; 1Ọb 9:4, 5—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà. Nígbà tó sì yá, Jèhófà sọ pé Dáfídì rìn pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn
-
Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun máa ń dárí jini fàlàlà bíi ti Jèhófà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 26:36, 40, 41—Ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sún mọ́ ọn jù lọ sùn nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ wọn jù, àmọ́ kò bínú sí wọn torí pé ó mọ ibi tágbára wọn mọ
-
Mt 26:69-75; Lk 24:33, 34; Iṣe 2:37-41 —Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù, àmọ́ ó ronú pìwà dà Jésù sì dárí jì í. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó lọ bá Pétérù ó sì fún un níṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ
-
Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa dárí jì?
Mt 12:31; Heb 10:26, 27; 1Jo 5:16, 17
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 23:29-33—Jésù jẹ́ káwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí mọ̀ pé wọn ò ní bọ́ nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà, ìyẹn ìparun ráúráú
-
Jo 17:12; Mk 14:21—Jésù pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù ní “ọmọ ìparun,” ó sì sọ pé ì bá sàn ká ní wọn ò bí ọ̀dàlẹ̀ ọkùnrin yìí
-
Kí ló máa ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ ká lè máa dárí jini?