ÀFIKÚN
Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó
BÁWO ni wọ́n ṣe túmọ̀ Sáàmù 83 ẹsẹ18 nínú Bíbélì rẹ? Bí Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ rẹ̀ rèé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn pẹ̀lú túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó jọ èyí. Àmọ́, àwọn olùtumọ̀ kan kò fi orúkọ náà, Jèhófà síbẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ oyè bíi “Olúwa” tàbí “Ayérayé” ni wọ́n fi rọ́pò rẹ̀. Kí ló yẹ kó wà nínú ẹsẹ yìí? Ṣé orúkọ oyè ló yẹ kó wà níbẹ̀ ni àbí orúkọ náà, Jèhófà?
Orúkọ kan ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Orúkọ àrà ọ̀tọ̀ kan fara hàn nínú Sáàmù 83 ẹsẹ 18 yìí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi èdè Hébérù kọ. Sípẹ́lì rẹ̀ ni יהוה (YHWH) ní èdè Hébérù. “Jèhófà” là ń pè é ní èdè Yorùbá. Ṣé inú ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ní orúkọ náà ti fara hàn ni? Rárá o. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù!
Báwo ni orúkọ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó? Ìwọ wo àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù Kristi kọ́ni. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Nígbà tó yá, Jésù tún gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ọlọ́run sì dá a lóhùn látọ̀run pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” (Jòhánù 12:28) Èyí fi hàn gbangba pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Kí wá ni ohun tó mú àwọn olùtumọ̀ kan yọ orúkọ yìí kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn, tí wọ́n wá fi orúkọ oyè rọ́pò rẹ̀?
Ó dà bíi pé ohun méjì ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ ló sọ pé kò yẹ kéèyàn máa lo orúkọ náà nítorí pé kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Kò sí fáwẹ̀lì nínú èdè Hébérù tí wọ́n ń kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe YHWH gan-an lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àmọ́, ṣó wá yẹ kí èyí mú ká má lo orúkọ Ọlọ́run? Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Yéṣúà tàbí Yèhóṣúà ni wọ́n ń pe Jésù, kò sẹ́ni tó lè sọ bí
wọ́n ṣe ń pè é gan-an nígbà yẹn. Síbẹ̀, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń pe orúkọ Jésù bó ṣe rí lédè wọn lóde òní. Wọn ò sọ pé àwọn ò ní lo orúkọ Jésù nítorí àwọn ò mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ọ̀rúndún kìíní. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, tó o bá lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, wàá rí i pé bí wọ́n á ṣe máa pe orúkọ rẹ níbẹ̀ ṣeé ṣe kó yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìlú rẹ. Nítorí náà, kò yẹ ká tìtorí pé a ò mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ká wá sọ pé a ò ní lò ó mọ́.Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù kan tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n sábà máa ń sọ pé ó jẹ́ ìdí kejì tí wọ́n fi yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù wọ̀nyẹn sọ pé èèwọ̀ ni, èèyàn ò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Ọlọ́run. Òfin kan tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ṣì lóye tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀. Òfin náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.”—Ẹ́kísódù 20:7.
Òfin yìí sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run nílòkulò. Àmọ́, ǹjẹ́ ó kà á léèwọ̀ pé ká má lo orúkọ Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? Rárá, kò ní ká máà lò ó tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé) jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n pa Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un mọ́. Síbẹ̀, lemọ́lemọ́ ni wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ sáàmù tí ẹgbàágbèje olùjọsìn kọ lórin sí Ọlọ́run. Kódà, Jèhófà sọ pé káwọn olùjọsìn òun máa pe orúkọ òun, àwọn tó jẹ́ onígbọràn sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóẹ́lì 2:32; Ìṣe 2:21) Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni lónìí fi ń lo orúkọ Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bí Jésù náà ṣe lò ó tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—Jòhánù 17:26.
Àṣìṣe ńlá làwọn olùtumọ̀ Bíbélì ṣe bí wọ́n ṣe fi orúkọ oyè rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí Ọlọ́run dà bí ẹni tó jìnnà jù tí kì í sì í ṣe ẹni gidi kan, bẹ́ẹ̀ Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” (Sáàmù 25:14) Ìwọ ronú nípa ẹnì kan tó o pè ní ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ná. Ǹjẹ́ o lè sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ lẹnì kan tí o kò bá mọ orúkọ rẹ̀? Bákan náà, téèyàn ò bá mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, báwo ló ṣe lè sún mọ́ ọn ní gidi? Síwájú sí i, táwọn èèyàn kì í bá lo orúkọ Ọlọ́run, wọn ò lè mọ ìtumọ̀ pàtàkì tó ní. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run?
Fúnra Ọlọ́run ló sọ ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí fún Mósè tó jẹ́ Ẹ́kísódù 3:14) Bí ìtumọ̀ Bíbélì Rotherham ṣe túmọ̀ ẹsẹ náà ni pé: “Èmi yóò di ohunkóhun tí mo bá fẹ́.” Nítorí náà, Jèhófà lè di ohunkóhun láti lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe.
ìránṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́. Nígbà tí Mósè bi Ọlọ́run pé kí lorúkọ rẹ̀, Jèhófà dá a lóhùn pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ká sọ pé o lè di ohunkóhun tó o bá fẹ́, kí lò bá ṣe? Kí lò bá ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tí ìkan nínú wọn bá ń ṣàìsàn, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti di dókítà kó o sì tọ́jú rẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan nínú wọn wọko gbèsè, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti di olówó tó ń fowó ṣàánú tí wàá sì fowó rẹ gbà á sílẹ̀. Àmọ́ ká sòótọ́, ó lójú ohun tó o lè dà. Bó sì ṣe rí fún gbogbo wa náà nìyẹn. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹnu á yà ọ́ gan-an láti rí bí Jèhófà ṣe ń di ohunkóhun kó bàa lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó sì máa ń wù ú láti lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (2 Kíróníkà 16:9) Àmọ́ àwọn tí kò mọ orúkọ Ọlọ́run kò lè mọ nǹkan kan nípa oríṣiríṣi ànímọ́ rere tó ní, èyí tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ gbé yọ.
Kò sí àní-àní pé Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Tí a bá mọ ìtumọ̀ rẹ̀ tí a sì ń lò ó fàlàlà nínú ìjọsìn wa, á ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Bàbá wa ọ̀run. *
^ ìpínrọ̀ 2 Bó o bá ń fẹ́ àlàyé sí i nípa orúkọ Ọlọ́run, ìtumọ̀ rẹ̀ àti ìdí tó fi yẹ ká máa lò ó nínú ìjọsìn, ka ìwé pẹlẹbẹ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Tún wo Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,1.