Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸTÀLÁ

Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀mí

Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀mí

1. Ta ló dá wa?

JÈHÓFÀ “ni Ọlọ́run alààyè.” (Jeremáyà 10:10) Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ló sì dá wa. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ lo dá ohun gbogbo, torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìfihàn 4:11) Èyí fi hàn pé ó wu Jèhófà ló fi dá wa, ẹ̀bùn iyebíye sì ni ẹ̀mí jẹ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀.​—Ka Sáàmù 36:9.

2. Kí ló yẹ ká ṣe kí ìgbésí ayé wa lè yọrí sí rere?

2 Ká bàa lè máa wà láàyè nìṣó, Jèhófà ti fún wa ní àwọn nǹkan bí oúnjẹ àti omi. (Ìṣe 17:28) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún fẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Ìṣe 14:15-17) Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa yọrí sí rere, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run.​—Àìsáyà 48:17, 18.

OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WO Ẹ̀MÍ

3. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Kéènì pa Ébẹ́lì?

3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí wa àti tàwọn míì ṣeyebíye lójú Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Kéènì tó jẹ́ ọmọ Ádámù àti Èfà bínú sí Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, Jèhófà kìlọ̀ fún un pé kó kápá ìbínú rẹ̀. Àmọ́ Kéènì ò gba ìkìlọ̀, inú sì bí i débi tó fi “lu Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, ó sì pa á.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8) Jèhófà fìyà jẹ Kéènì torí pé ó pa Ébẹ̀lì. (Jẹ́nẹ́sísì 4:9-11) Ìyẹn fi hàn pé, ìbínú àti ìkórìíra léwu gan-an, nítorí wọ́n lè mú ká hùwà ipá tàbí ká hùwà ìkà. Ẹni tó bá sì ní irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ka 1 Jòhánù 3:15.) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí wa, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn.​—1 Jòhánù 3:11, 12.

4. Kí ni ọ̀kan lára àwọn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ wa nípa ẹ̀mí èèyàn?

4 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà fi hàn pé ohun tó ṣeyebíye ni ẹ̀mí èèyàn jẹ́ nígbà tó fún Mosè ní Òfin Mẹ́wàá. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.” (Diutarónómì 5:17) Tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, wọ́n máa pa òun náà.

5. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún?

5 Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún? Ẹ̀mí ọmọ tí a kò tíì bí pàápàá ṣeyebíye lójú Jèhófà. Nínú òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ pé tí ẹnì kan bá ṣe aláboyún kan léṣe tí ọmọ inú rẹ̀ sì kú, ńṣe ni kí wọ́n pa onítọ̀hún. (Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23; Sáàmù 127:3) Ìyẹn kọ́ wa pé kò dáa kéèyàn ṣẹ́yún.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 28.

6, 7. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ojú iyebíye la fi ń wo ẹ̀mí?

6 Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ojú iyebíye la fi ń wo ẹ̀mí wa àti tàwọn ẹlòmíì? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá ṣe ohunkóhun tó máa fi ẹ̀mí àwa àti tàwọn míì sínú ewu. Torí náà, a ò ní máa mu sìgá, igbó, tàbí tábà, a ò sì ní máa fín aáṣà tàbí ká máa lo oògùn nílòkulò, torí pé wọ́n lè ṣe ìpalára fún wa tàbí kí wọ́n pa wá.

7 Ọlọ́run ló dá ẹ̀mí àti ara wa, ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa lò ó bó ṣe fẹ́. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣe ohun tó máa kó ẹ̀gbin bá ara wa. Tá a bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, a máa di aláìmọ́ lójú Ọlọ́run. (Róòmù 6:19; 12:1; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Tá ò bá fojú tó ṣeyebíye wo ẹ̀mí, a ò lè sin Jèhófà, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa, àmọ́ tá a bá gbà pé ẹ̀mí ṣeyebíye, tá a sì ń sa gbogbo ipá wa láti jáwọ́, ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́.

8. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé a ò fi ẹ̀mí wa àti tàwọn ẹlòmíì sínú ewu?

8 A ti wá mọ̀ pé ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye. Jèhófà mọ̀ pé a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa fi ẹ̀mí wa àti tàwọn míì sínú ewu. À ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ọ̀nà tá à ń gbà wa ọkọ̀ wa, ọ̀kadà wa, tàbí ohun ìrìnnà míì tá a ní. Kò yẹ ká máa ṣe àwọn eré ìdárayá tó léwu, tàbí tó ní ìwà ipá nínú. (Sáàmù 11:5) Ó tún yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kó má bàa sí ohun tó lè fa jàǹbá nínú ilé wa. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Tí o bá kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ, kí o má bàa mú kí ilé rẹ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹnì kan já bọ́ látorí rẹ̀.”​—Diutarónómì 22:8.

9. Kí ló yẹ ká ṣe sáwọn ẹranko, kí sì ni kò yẹ ká máa ṣe sí wọn?

9 Kódà, ohun tá à ń ṣe sáwọn ẹranko ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Ó fàyè gbà wá láti pa àwọn ẹranko jẹ tàbí ká lò wọ́n fún aṣọ, ó sì tún gbà wá láyè láti pa wọ́n tí wọ́n bá fẹ́ pa wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:21; 9:3; Ẹ́kísódù 21:28) Ṣùgbọ́n kò yẹ ká máa hùwà ìkà sí àwọn ẹranko tàbí ká kàn máa pa wọ́n ṣeré.​—Òwe 12:10.

BỌ̀WỌ̀ FÚN Ẹ̀MÍ TORÍ PÉ Ó JẸ́ MÍMỌ́

10. Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí?

10 Lójú Jèhófà, ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí. Lẹ́yìn tí Kéènì pa Ébẹ̀lì, Jèhófà sọ fún Kéènì pé: “Ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:10) Ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì ni ẹ̀mí rẹ̀, Jèhófà sì fìyà jẹ Kéènì torí pé ó pa Ébẹ̀lì. Lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Jèhófà tún fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí. Jèhófà gba Nóà àti ìdílé rẹ̀ láyè láti máa pa ẹran jẹ. Ó sọ pé: “Gbogbo ẹran tó ń rìn tó sì wà láàyè lè jẹ́ oúnjẹ fún yín. Mo fún yín ní gbogbo wọn bí mo ṣe fún yín ní ewéko tútù.” Àmọ́, ohun kan wà tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ, ó ní: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ni ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ.”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:29; 9:3, 4.

11. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

11 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún lẹ́yìn ti Jèhófà sọ fún Nóà pe kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ó tún pàṣẹ náà fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde, kó sì fi erùpẹ̀ bò ó.” Ó tún sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.” (Léfítíkù 17:13, 14) Jèhófà ṣì fẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun mímọ́. Wọ́n lè jẹ ẹran, ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ pa ẹran jẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.

12. Kí ni àwọn Kristẹni ka ẹ̀jẹ̀ sí?

12 Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù pàdé láti pinnu apá wo nínú àwọn Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ṣì wúlò fún àwọn Kristẹni. (Ka Ìṣe 15:28, 29; 21:25.) Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye pé ẹ̀jẹ̀ ṣì ṣeyebíye lójú òun àti pé wọ́n ṣì ní láti kà á sí ohun mímọ́. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ kò jẹ ẹ̀jẹ̀, wọn ò mu ẹ̀jẹ̀, wọn ò sì jẹ ẹran tí wọn kò ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù nígbà tí wọ́n dú u. Tí wọ́n bá ṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó máa burú jáì nítorí pé ohun kan náà ni pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe. Látìgbà yẹn, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí kí wọ́n mu ẹ̀jẹ̀. Lóde òní ńkọ́? Jèhófà ṣì fẹ́ ká máa ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun mímọ́.

13. Kí nìdí táwọn Kristẹni kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ sára?

13 Ṣé èyí túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ sára? Bẹ́ẹ̀ ni. Jèhófà pàṣẹ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí ká mu ẹ̀jẹ̀. Tí dókítà kan bá sọ fún ẹ pé o kò gbọ́dọ̀ mu ọtí, ṣé wàá gbà kí wọ́n fa ọtí sí ẹ lára? Rárá o! Lọ́nà kan náà, àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí ká mu ẹ̀jẹ̀ túmọ̀ sí pé a ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ sára.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 29.

14, 15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkí pé kí Kristẹni kan bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí kó sì ṣègbọràn sí Jèhófà?

14 Kí la máa ṣe tí dókítà kan bá sọ fún wa pé tá ò bá gba ẹ̀jẹ̀ sára, a máa kú? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu bóyá òun á ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀. Àwa Kristẹni bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí gan-an torí pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ká lè máa wà láàyè nìṣó, a máa ń gba àwọn ìtọ́jú míì nígbà tá a bá ṣàìsàn; àmọ́ a ò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára.

15 A máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ní ìlera tó dáa, àmọ́ torí pé ẹ̀mí ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, a kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣègbọràn sí Jèhófà dípò ká ṣàìgbọràn sí i torí pé a fẹ́ jẹ́ kí ẹ̀mí wa gùn. Jésù sọ pé: “Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi máa rí i.” (Mátíù 16:25) Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà la ṣe ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Jèhófà mọ ohun tó dáa jù lọ fún wa, torí náà ojú tó fi ń wo ẹ̀mí làwa náà fi ń wò ó, pé ó ṣeyebíye ó sì jẹ́ mímọ́.​—Hébérù 11:6.

16. Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?

16 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe tán láti ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀. Wọn kì í jẹ ẹ̀jẹ̀, wọn kì í mu ẹ̀jẹ̀, wọn kì í sì í gba ẹ̀jẹ̀ sára láti lè tọ́jú ara wọn. * Àmọ́ ṣá o, wọ́n máa ń gba àwọn ìtọ́jú míì tí kò ní gba pé kí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ sára láti fi gba ẹ̀mí wọn là. Ó dá wọn lójú pé ẹni tó dá ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ mọ ohun tó dáa jù lọ fún wọn. Ṣé o gbà pé ó mọ ohun tó dáa jù lọ fún ìwọ náà?

Ọ̀NÀ KAN ṢOṢO TÍ JÈHÓFÀ FÀYÈ GBA ÈÈYÀN LÁTI LO Ẹ̀JẸ̀

17. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni Jèhófà fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lo ẹ̀jẹ̀?

17 Nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Torí inú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹran wà, èmi fúnra mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín kí ẹ lè ṣe ètùtù [tàbí, tọrọ ìdáríjì] fún ara yín, torí ẹ̀jẹ̀ ló ń ṣe ètùtù.” (Léfítíkù 17:11) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ láti tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n á sì sọ fún àlùfáà pé kó da díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sórí pẹpẹ tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Èyí ní ọ̀nà kan ṣoṣo tí Jèhófà fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lo ẹ̀jẹ̀.

18. Àǹfààní wo la ní torí pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ?

18 Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rọ́pò fífi ẹran rúbọ̀ bí òfin ṣe sọ, ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Mátíù 20:28; Hébérù 10:1) Ẹ̀mí Jésù ṣeyebíye gan-an débi pé lẹ́yìn tí Jèhófà jí Jésù dìde sí ọ̀run, Jèhófà wá fún gbogbo èèyàn ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé.​—Jòhánù 3:16; Hébérù 9:11, 12; 1 Pétérù 1:18, 19.

Kí lo máa ṣe táá fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀?

19. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí ‘ọrùn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn’?

19 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí ẹ̀bùn àgbàyanu tó fun wa, ìyẹn ẹ̀mí wa! Ó sì wù wá láti máa sọ fún àwọn èèyàn pé tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, wọ́n lè wà láàyè títí láé. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a ó máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa rí ìyè. (Ìsíkíẹ́lì 3:17-21) Nígbà náà, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a máa lè sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn, nítorí mi ò fà sẹ́yìn nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún yín.” (Ìṣe 20:26, 27) Tá a bá ń sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà àti bí ẹ̀mí ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 16 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìfàjẹ̀sínilára, wo ojú ìwé 77 sí 79 nínú ìwé “Ẹ dúró nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.