Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 60

Ìjọba kan Tó Máa Wà Títí Láé

Ìjọba kan Tó Máa Wà Títí Láé

Lóru ọjọ́ kan, Ọba Nebukadinésárì lá àlá kan tó bani lẹ́rù. Àlá yìí dà á láàmú gan-an débi pé kò lè sùn. Ó wá pe àwọn pidánpidán rẹ̀, ó sì sọ fún wọ́n pé: ‘Ẹ ṣàlàyé àlá yìí fún mi.’ Wọ́n dá a lóhùn pé: ‘Kábíyèsí, ẹ jọ̀ ọ́ ẹ kọ́kọ́ sọ àlá náà fún wa.’ Àmọ́ Nebukadinésárì sọ fún wọn pé: ‘Rárá! Ẹ̀yin lẹ gbọ́dọ̀ sọ àlá tí mó lá fún mi, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá pa yín.’ Ni wọn bá tún sọ pé: ‘Kábíyèsí, ẹ sọ àlá náà fún wa ká lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún yín.’ Inú bí ọba, ó ní: ‘Ṣé ẹ fẹ́ máa tàn mí ni, àbí? Mo ní kí ẹ sọ àlá náà fún mi!’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Kò sí ẹnì kankan láyé yìí tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kò ṣeé ṣe rárá.’

Inú bí Nebukadinésárì gan-an, ló bá ní kí wọ́n lọ pa àwọn ọlọgbọ́n tó wà nílẹ̀ náà. Èyí sì máa kan Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò. Àmọ́ nígbà tí Dáníẹ́lì gbọ́, ó ní kí ọba fún àwọn láyè díẹ̀. Òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà wọn?

Nínú ìran, Jèhófà fi àlá Nebukadinésárì àti ìtumọ̀ rẹ̀ han Dáníẹ́lì. Lọ́jọ́ kejì, Dáníẹ́lì lọ bá ìránṣẹ́ ọba, ó sọ fún un pé: ‘Má ṣe pa ẹnikẹ́ni. Mo lè sọ àlá tí ọba lá.’ Ìránṣẹ́ náà wá mú Dáníẹ́lì lọ sọ́dọ̀ Nebukadinésárì. Dáníẹ́lì sọ fún ọba pé: ‘Ọlọ́run ti sọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún un yín. Nínú àlá náà, ẹ rí ère ńlá kan tí orí rẹ̀ jẹ́ wúrà, àyà rẹ̀ jẹ́ fàdákà, ikùn àti itan rẹ̀ jẹ́ bàbà, ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ amọ̀ àti irin. Ẹ tún wá rí òkúta ńlá tí wọ́n gé láti orí òkè ńlà kan tí wọ́n sì jù ú ba ẹsẹ̀ ère náà. Ère náà sì fọ́ ṣí wẹ́wẹ́, ó rún wómúwómú, afẹ́fẹ́ sì fẹ́ ẹ dànù. Òkúta náà sì di òkè ńlá tó bo gbogbo ayé.’

Dáníẹ́lì wá sọ pé: ‘Ìtumọ̀ àlá náà rèé: Ìjọba yín ni orí ère wúrà náà ṣàpẹẹrẹ. Fàdákà yẹn dúró fún ọba tó máa jẹ lẹ́yìn yín. Ìjọba míì tún ń bọ̀ tó dà bíi bàbà, ìyẹn máa ṣàkóso gbogbo ayé. Ìjọba tó máa tẹ̀ lé e máa lágbára bí irin. Ìjọba to gbẹ̀yìn máa dà bí àpòpọ̀ irin àti amọ̀, tó fi hàn pé apá kan máa lágbára bí irin, apá kan máa dà bí amọ̀ tí kò lágbára. Òkútá tó wá di òkè ńlá yẹn dúró fún Ìjọba Ọlọ́run. Ó máa pa gbogbo ìjọba tó ti wà ṣáájú run, òun á sì wà títí láé.’

Bí Nebukadinésárì ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó dojú bolẹ̀ níwájú Dáníẹ́lì. Ó ní: ‘Ọlọ́run rẹ ló fi àlá yìí hàn ẹ́ lóòótọ́. Kò sí Ọlọ́run tó dà bíi rẹ̀.’ Nebukadinésárì wá fi Dáníẹ́lì ṣe olórí àwọn ọlọgbọ́n àti alákòóso gbogbo ìlú tó wà ní Bábílónì. Ǹjẹ́ o rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Dáníẹ́lì?

“Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”​—Ìṣípayá 16:16