Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 11
Apá yìí dá lórí ìtàn tó bẹ̀rẹ̀ láti Mátíù dé Ìṣípayá. Inú ìdílé kan tí kò lówó ni wọ́n bí Jésù sí. Inú abúlé kékeré kan sì ni wọ́n ń gbé. Ó bá bàbá rẹ̀ ṣe iṣẹ́ káfíńtà. Jésù lẹ́ni tó máa gba aráyé là. Jèhófà ti yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run. Tí o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọyì bí Jèhófà ṣe fara balẹ̀ yan irú ìdílé àti àyíká tí Jésù máa dàgbà sí. Tún ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Jésù lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù tó fẹ́ pa á àti bí kò ṣe sí ohunkóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe yan Jòhánù láti múra ọ̀nà sílẹ̀ fún Jésù. Tẹnu mọ́ bí Jésù ṣe fi hàn pé àti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà.
NÍ APÁ YÌÍ
Ẹ̀KỌ́ 68
Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan
Kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi sọ fún ọkọ Èlísábẹ́tì pé kò ní lè sọ̀rọ̀ títí wọ́n á fi bí ọmọ náà?
Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
Jòhánù sì dàgbà di wòlí ì. Ó kọ́ àwọn èèyàn pé Mèsáyà ń bọ̀. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?