Ẹ̀KỌ́ 75
Èṣù Dán Jésù Wò
Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ lọ sí aginjù. Jésù ò jẹ ohunkóhun fún ogójí [40] ọjọ́, ebí wá ń pa á gan-an. Bí Èṣù ṣe wá dán Jésù wò níyẹn, ó sọ fún Jésù pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.’ Àmọ́, Jésù fi ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ló máa jẹ́ ká wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa fetí sí gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù tún sọ fún un pé: ‘Tí ìwọ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́, fò láti ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì yìí sí ìsàlẹ̀. Torí a ti kọ ọ́ pé Ọlọ́run á rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti gbé ọ, kí o má bàa ṣubú.’ Jésù tún fi Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì tún fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù, àti gbogbo ọrọ̀ àti ògo tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wá sọ fún un pé: ‘Màá fún ẹ ní gbogbo nǹkan yìí tí o bá jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’ Jésù wá sọ fún Sátánì pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn.’
Èṣù kúrò lọ́dọ̀ Jésù, lẹ́yìn náà àwọn áńgẹ̀lì wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ. Láti ìgbà yẹn ni Jésù ti ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Iṣẹ́ tí Jèhófà ní kí Jésù wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn, torí náà ibi gbogbo tí Jésù bá ń lọ ni àwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ.
“Nígbà tí [Èṣù] bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.”—Jòhánù 8:44