Ẹ̀KỌ́ 84
Jésù Rìn Lórí Omi
Yàtọ̀ sí pé Jésù lè wo àwọn aláìsàn, ó sì lè jí òkú dìde, ó tún lágbára lórí ìjì ìyẹn atẹ́gùn tó lágbára àti òjò. Lọ́jọ́ kan, Jésù lọ gbàdúrà lórí òkè, lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ó rí ìjì kan tó ń jà lórí Òkun Gálílì. Inú ọkọ̀ ojú omi ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà nígbà yẹn, wọ́n ń gbìyànjú láti wa ọkọ̀ náà kí ìjì má bàa dà á nù. Jésù wá sọ̀ kalẹ̀, ó sì ń rìn lórí omi lọ sọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n rí ẹnì kan tó ń rìn lórí omi, àyà wọn já, àmọ́, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Emi ni, ẹ má bẹ̀rù.’
Pétérù wá sọ pé: ‘Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni lóòótọ́, sọ pé kí n wá bá ẹ lórí omi.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Máa bọ̀.’ Bí ìjì yẹn ṣe ń jà, Pétérù jáde nínú ọkọ̀, ó sì rìn lọ bá Jésù lórí omi. Àmọ́, bó ṣe ń sún mọ́ Jésù, ó wo ìjì náà, àyà rẹ̀ sì já, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú omi nìyẹn. Pétérù wá pariwo pé: ‘Olúwa, gbà mí là!’ Jésù di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó sì sọ fún un pé: ‘Kí ló dé tí o fi ń jáyà? Ibo ni ìgbàgbọ́ rẹ wà?’
Jésù àti Pétérù wá jọ pa dà sínú ọkọ̀ náà, ìjì náà sì dáwọ́ dúró. Ǹjẹ́ o mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀? Ohun tí wọ́n sọ ni pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.”
Kì í ṣe àsìkò yìí nìkan ni Jésù lo agbára lórí ìjì. Nígbà kan tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà nínú ọkọ̀ ojú omi, Jésù sùn sí ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. Bí Jésù ṣe ń sùn lọ́wọ́, ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, omi sì kún inú ọkọ̀ wọn. Àwọn àpọ́sítélì wá sáré jí Jésù, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Olùkọ́, a ti fẹ́ kú o! Ràn wá lọ́wọ́!’ Jésù bá dìde, ó sì sọ fún òkun náà pé: “Dákẹ́!” Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀, ìjì àti òkun náà sì ṣe wọ̀ọ̀. Jésù wá bi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ìgbàgbọ́ yín dà?” Àwọn àpọ́sítélì náà bá ń sọ láàárín ara wọn pé: “Ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i.” Àwọn àpọ́sítélì náà kẹ́kọ̀ọ́ pé tí wọ́n bá fọkàn tán Jésù pátápátá, wọn ò ní bẹ̀rù ohunkóhun.
“Where would I be if I did not have faith that I would see Jehovah’s goodness in the land of the living?”—Psalm 27:13