Ẹ̀KỌ́ 98
Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa fún wọn pé kí wọ́n wàásù káàkiri ayé. Ní ọdún 47 lẹ́yìn tí Jésù wa sí ayé, àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Áńtíókù rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pé kí wọ́n lọ wàásù. Àwọn ọkùnrin méjì yìí fi ìtara wàásù káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éṣíà Kékeré. Lára àwọn ìlú tí wọ́n ti wàásù ni Déébè, Lísírà àti Íkóníónì.
Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wàásù fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn olówó àti tálákà àti ọmọdé àti àgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì di Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fẹ́ wàásù fún Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ gómìnà ìlú Kípírọ́sì, ọkùnrin kan fẹ́ dí wọn lọ́wọ́. Ọkùnrin náà máa ń pidán, ìyẹn ni pé ó máa ń lo ẹ̀mí èṣù láti tan àwọn èèyàn jẹ. Pọ́ọ̀lù wá sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Kí Jèhófà bá ẹ wí.’ Lójijì ni ojú ọkùnrin náà fọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí gómìnà náà gba Jésù gbọ́.
Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wàásù káàkiri, wọ́n wàásù láti ilé dé ilé àti nínú ọjà àti lójú ọ̀nà àti nínú sínágọ́gù. Ìgbà kan wà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Lísírà láti jẹ́ kí arọ kan rìn. Bí àwọn èèyàn ṣe rí iṣẹ́ ìyanu yìí, wọ́n rò pé òrìṣà ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì fẹ́ jọ́sìn wọn. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ pé kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn, wọ́n ní: ‘Èèyàn lásán ni wá, Ọlọ́run nìkan ni kí ẹ jọ́sìn!’ Nígbà tó yá, àwọn Júù kan wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí àwọn èèyàn kórìíra Pọ́ọ̀lù. Àwọn èèyàn náà sọ Pọ́ọ̀lù ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ jáde ní ìlú, wọ́n rò pé ó ti kú. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù kò kú! Àwọn ará wá gbé e kúrò níbi tí wọ́n wọ́ ọ sí, wọ́n sì mú un pa dà wọ inú ìlú. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù pa dà sí Áńtíókù.
Ní ọdún 49 lẹ́yìn tí Jésù wá sí ayé, Pọ́ọ̀lù tún rin ìrìn àjò míì, ó sì ń wàásù. Lẹ́yìn tó pa dà dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ní Éṣíà Kékeré, ó tún ń wàásù
dé àwọn ibi tó jìnnà gan-an títí kan Yúróòpù. Ó dé Áténì, Éfésù, Fílípì, Tẹsalóníkà àti àwọn ibòmíì. Sílà, Lúùkù, àti ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tímótì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn àjò yìí. Wọ́n sì ṣiṣẹ́ pọ̀ láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀ àti láti mú kí àwọn ìjọ náà lágbára. Pọ́ọ̀lù dúró ní Kọ́ríńtì fún ọdún kan àtààbọ̀ kó lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Ó wàásù, ó kọ́ni, ó tún kọ lẹ́tà sí ọ̀pọ̀ ìjọ. Ó máa ń ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń lò fún àgọ́ ko lè rí owó bójú tó ara rẹ̀. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù pa dà sí Áńtíókù.Ní ọdún 52 lẹ́yìn tí Jésù wá sí ayé, Pọ́ọ̀lù tún rin ìrìn àjò láti lọ wàásù ní ìgbà kẹta, ó sì bẹ̀rẹ̀ ní Éṣíà Kékeré. Ó rin ìrìn àjò láti ìlú Fílípì títí dé Kọ́ríńtì. Pọ́ọ̀lù lo ọ̀pọ̀ ọdún ní Éfésù, ó kọ́ni, ó ń mú àwọn èèyàn lára dá, ó sì ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́. Ó tún ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ níbi tí àwọn èèyàn máa ń kóra jọ sí láti kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn fetí sílẹ̀, wọ́n sì tún ìwà wọn ṣe. Níkẹyìn, lẹ́yìn tó wàásù ìhìn rere ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọjá sí Jerúsálẹ́mù.
“Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:19