Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹda Ẹmi
Bibeli sọ fun wa pe ọpọlọpọ awọn ẹda ẹmi ni nbẹ. Jehofa funraarẹ jẹ ẹmi kan.—Johanu 4:24; 2 Kọrinti 3:17, 18.
Ni akoko kan Jehofa nikanṣoṣo ni o wa ni agbaye. Nigba ti o yá oun bẹrẹsii ṣẹ̀dá awọn ẹda ẹmi ti a npe ni angẹli. Wọn lagbara wọn sì loye ju awọn eniyan lọ. Jehofa da ọpọlọpọ awọn angẹli; Daniẹli iranṣẹ Ọlọrun, ninu iran, ri ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn angẹli.—Daniẹli 7:10; Heberu 1:7.
Ọlọrun da awọn angẹli wọnyi ani ṣaaju ki o to da ilẹ-aye paapaa. (Joobu 38:4-7) Ko si ọkankan ninu wọn ti o jẹ eniyan tí ó ti gbe tí o sì ti ku lori ilẹ-aye ri.