Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 49

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?​—Apá Kìíní

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?​—Apá Kìíní

Ó máa ń wu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó pé kí ayọ̀ tí wọ́n ní lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn bá wọn kalẹ́. Ó sì lè rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tọkọtaya Kristẹni tí wọ́n ti ṣègbéyàwó fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ mọ̀ pé ó lè rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́.

1. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún àwọn ọkọ?

Jèhófà ti fi ọkùnrin ṣe olórí ìdílé. (Ka Éfésù 5:23.) Ó sì retí pé kí ọkùnrin máa ṣe àwọn ìpinnu táá ṣe ìdílé ẹ̀ láǹfààní. Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín.” (Éfésù 5:25) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ á máa ṣìkẹ́ ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ilé àti nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn míì. Á máa dáàbò bo ìyàwó ẹ̀, á máa múnú ẹ̀ dùn, á sì máa pèsè ohun tó nílò. (1 Tímótì 5:8) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó ran ìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Mátíù 4:4) Bí àpẹẹrẹ, á máa gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀, wọ́n á sì jọ máa ka Bíbélì pa pọ̀. Tí ọkọ kan bá ń ṣìkẹ́ ìyàwó ẹ̀, tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, inú Jèhófà á dùn sí i.​—Ka 1 Pétérù 3:7.

2. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún àwọn aya?

Bíbélì sọ pé kí aya “ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Báwo ló ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ń ronú nípa àwọn ìwà dáadáa tí ọkọ ẹ̀ ní àti gbogbo ohun tí ọkọ ẹ̀ ń ṣe kó lè máa bójú tó òun àtàwọn ọmọ wọn. Ó tún máa fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ọkọ òun tó bá ń gbìyànjú láti kọ́wọ́ ti àwọn ìpinnu tí ọkọ ẹ̀ ń ṣe, tó ń fi ohùn jẹ́jẹ́ bá ọkọ ẹ̀ sọ̀rọ̀, tó sì ń sọ ohun tó dáa nípa ẹ̀, kódà tí ọkọ náà ò bá tiẹ̀ sin Jèhófà.

3. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè mú kí ìfẹ́ àárín wọn jinlẹ̀ sí i?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó ṣègbéyàwó ni pé: “Àwọn méjèèjì á sì di ara kan.” (Mátíù 19:5) Èyí túmọ̀ sí pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbà kí ohunkóhun mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín wọn tutù. Ìyẹn máa ṣeé ṣe tí wọ́n bá ń wáyè láti wà pa pọ̀ déédéé, tí wọ́n ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, tí wọ́n ń fi ohùn jẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀, tí wọn ò sì fi nǹkan kan pa mọ́ fúnra wọn. Wọn ò ní jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ṣe pàtàkì sí wọn ju ẹnì kejì wọn lọ, wọ́n sì máa fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́. Bákan náà, wọn ò ní máa lo àkókò tó pọ̀ jù pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó lè mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jinlẹ̀ sí i.

4. Ó yẹ káwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó wọn, kí wọ́n sì máa ṣìkẹ́ wọn

Bíbélì sọ pé “kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn.” (Éfésù 5:28, 29) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Àwọn nǹkan wo ni ọkọ kan lè máa ṣe láti fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, ó sì ń ṣìkẹ́ ẹ̀?

Ka Kólósè 3:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ni ọkọ kan ṣe lè máa ṣe ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?

5. Ó yẹ káwọn aya nífẹ̀ẹ́ ọkọ wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn

Bíbélì sọ pé ó yẹ kí àwọn aya máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, kódà tí ọkọ náà ò bá tiẹ̀ sin Jèhófà. Ka 1 Pétérù 3:1, 2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Tí ọkọ ẹ kò bá sin Jèhófà, ó dájú pé wàá fẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Kí lo rò pé ó máa dáa jù pé kó o ṣe? Ṣé kó o máa wàásù fún un ní gbogbo ìgbà ni, àbí kó o máa hùwà tó dáa, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún un? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Tí tọkọtaya bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n máa lè ṣèpinnu tó dáa. Àmọ́ nígbà míì, ìyàwó lè má fara mọ́ ìpinnu tọ́kọ ẹ̀ ṣe. Ó lè sọ èrò ẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó máa fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ọkọ òun ni Jèhófà retí pé kó máa pinnu ohun tó máa ṣe ìdílé wọn láǹfààní. Torí náà, ó yẹ kí ìyàwó máa kọ́wọ́ ti ìpinnu tí ọkọ ẹ̀ bá ṣe. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìdílé wọn á láyọ̀. Ka 1 Pétérù 3:3-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí aya kan bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀?

6. O lè borí ìṣòro nínú ìdílé rẹ

Kò sí ìdílé tí kò níṣòro. Torí náà, tọkọtaya gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè máa yanjú ìṣòro tí wọ́n bá ní. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya yìí ti ń tutù?

  • Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe kí ìfẹ́ àárín wọn lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i?

Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24 àti Kólósè 3:13. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú ìdílé yín tẹ́ ẹ bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?

Bíbélì sọ pé ó yẹ ká máa bọlá fún ara wa. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà máa bọlá fáwọn míì ni pé ká jẹ́ onínúure sí wọn, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ka Róòmù 12:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé ó yẹ kẹ́nì kan máa retí pé ó yẹ kí ọkọ tàbí aya òun kọ́kọ́ bọlá fún òun kóun tó lè bọlá fún un? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Èmi àti ọkọ tàbí aya mi ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

  • Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tọkọtaya máa láyọ̀ tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn, tí wọ́n sì ń fi ìlànà Bíbélì sílò.

Kí lo rí kọ́?

  • Àwọn nǹkan wo ni ọkọ kan lè ṣe kí ìdílé ẹ̀ lè láyọ̀?

  • Àwọn nǹkan wo ni aya kan lè ṣe kí ìdílé ẹ̀ lè láyọ̀?

  • Tó o bá ti ní ọkọ tàbí aya, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn yín lọ́wọ́ kí ìdílé yín lè túbọ̀ láyọ̀?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìwé yìí kó o lè rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ kí ìdílé rẹ láyọ̀.

Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

Wo fídíò orin yìí kó o lè mọ àwọn àǹfààní tí wàá rí tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ìdílé rẹ.

Ìfẹ́ Tòótọ́ (4:26)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kí obìnrin kan máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀.

“Ẹ̀yin Obìnrin, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Tẹrí Ba Fún Ipò Orí?” (Ilé Ìṣọ́, May 15, 2010)

Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún tọkọtaya kan láti yanjú ìṣòro tó lágbára tí wọ́n ní, èyí tó le débi tí wọ́n fi kọ ara wọn sílẹ̀?

Jèhófà Ló Bá Wa Tún Ìdílé Wa Tò (5:14)