APÁ KẸJỌ
Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
“Ẹ̀yin ń yọ̀ gidigidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín.”
Bí o bá tiẹ̀ ń sa gbogbo ipá rẹ kí ìdílé rẹ lè láyọ̀, kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ sì lè wà ní ìṣọ̀kan, àwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ lè wáyé tó lè ba ayọ̀ yín jẹ́. (Oníwàásù 9:
1 GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí tí òun n ṣe ìtọ́jú yín.” (1 Pétérù 5:
O tún máa rí ìtùnú tí o bá ń ka Bíbélì rẹ tí o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́. Èyí á jẹ́ kí o rí bí Jèhófà ṣe máa ń “tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí o lè fọkàn balẹ̀, kí o sì lè ronú bó ṣe tọ́
-
Ronú nípa gbogbo ohun tí o lè ṣe, kí o sì yan èyí tí o bá rí i pé ó dára jù, tí ọwọ́ rẹ sì lè tẹ̀
2 TỌ́JÚ ARA RẸ ÀTI ÌDÍLÉ RẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ọkàn-àyà olóye ń jèrè ìmọ̀, etí àwọn ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti rí ìmọ̀.” (Òwe 18:15) Gbìyànjú láti mọ gbogbo ohun tó yẹ. Rí i pé o mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé rẹ nílò. Máa bá wọn sọ̀rọ̀. Kí o sì máa tẹ́tí sí wọn.
Bí èèyàn rẹ kan tí o fẹ́ràn bá ṣaláìsí ńkọ́? Má ṣe bẹ̀rù láti fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ hàn. Rántí pé Jésù pẹ̀lú “da omijé.” (Jòhánù 11:35; Oníwàásù 3:4) Ó tún ṣe pàtàkì pé kí o máa sinmi kí o sì máa sùn dáadáa. (Oníwàásù 4:6) Èyí á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti fara da ìṣòro.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Kí àjálù tó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ sọ̀rọ̀. Èyí máa jẹ́ kó rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nígbà tí ìṣòro bá dé
-
Bá àwọn míì tó ṣeé ṣe kó ti ní irú ìṣòro yìí rí sọ̀rọ̀
3 WÁ ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ YẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n lè má mọ ohun tí wọ́n lè ṣe. Má ṣe tijú láti sọ ohun tí o bá fẹ́ kí wọ́n ṣe fún ọ. (Òwe 12:25) Bákan náà, ní kí àwọn tó lóye Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ìtọ́sọ́nà tí wọ́n bá fún ẹ látinú Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
O máa rí ìrànlọ́wọ́ tó o nílò tí o bá ń pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí rẹ̀. O tún máa rí ìtùnú púpọ̀ tí o bá ń ran àwọn tó nílò ìṣírí lọ́wọ́. Máa sọ bí ìgbàgbọ́ tí o ní nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Tẹra mọ́ ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, kí o sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ, tí ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ lọ́kàn.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan, sì jẹ́ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́
-
Sọ ohun tí o fẹ́ gan-an, má sì fi ọ̀rọ̀ pa mọ́