Ẹ̀KỌ́ 4
Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?
Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lo oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì, tí a tẹ̀ wọ́n jáde tí a sì pín wọn káàkiri. Àmọ́ nígbà tó yá, a rí i pé ó yẹ ká ṣe ìtumọ̀ míì tó máa túbọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́” bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní in. (1 Tímótì 2:3, 4) Torí náà, ní ọdún 1950 a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lápá kọ̀ọ̀kan ní èdè tó bóde mu. A ti túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye tí kò sì lábùkù sí èdè tó lé ní àádóje (130).
A nílò Bíbélì kan tó máa tètè yé àwọn èèyàn. Èdè máa ń yí pa dà, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló sì ṣòro láti lóye torí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ye àwọn èèyàn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́. Bákan náà, a ti ṣàwárí àwọn Ìwé Mímọ́ àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, èyí tó túbọ̀ péye, tó sì sún mọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Èyí ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye èdè Hébérù, Árámáíkì àti èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì.
A nílò ìtumọ̀ Bíbélì tí kò bomi la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kò gbọ́dọ̀ yí ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí pa dà, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe ìtumọ̀ tí kò lábùkù tó sì bá Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀ mu. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ni kò lo Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run.
A nílò Bíbélì kan tó fi ògo fún Ẹni tó ni ín. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Bó ṣe wà nínú àwòrán ìsàlẹ̀ yìí, a ti dá orúkọ náà, Jèhófà pa dà sínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, bó ṣe wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ. (Sáàmù 83:18) Nítorí a ti fara balẹ̀ ṣe ìwádìí fún ọ̀pọ̀ ọdún ká tó mú Bíbélì yìí jáde, ó dùn-ún kà, ó sì jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe kedere. Bóyá Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà ní èdè rẹ tàbí kò sí, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Ọ̀rọ̀ Jèhófà lójoojúmọ́.—Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2, 3.
-
Kí nìdí tá a fi pinnu pé a nílò ìtumọ̀ Bíbélì míì?
-
Kí ló yẹ kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ mọ ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe lójoojúmọ́?