Ẹ̀KỌ́ 20
Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwùjọ kékeré kan, ìyẹn “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù,” ló jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Ìṣe 15:2) Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa ń jíròrò àti bí wọ́n ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wọn, ló ń mú kí wọ́n lè máa fohùn ṣọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu. (Ìṣe 15:25) Àpẹẹrẹ yẹn là ń tẹ̀ lé lóde òní.
Ọlọ́run ń lo ìgbìmọ̀ náà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, àwọn arákùnrin yìí sì ní ìrírí tó pọ̀ nínú bá a ṣe ń bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àti ìjọsìn wa. Wọ́n máa ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nílò. Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, à ń rí àwọn ìtọ́ni tá a gbé ka Bíbélì gbà nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí nípasẹ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn míì. Èyí ń jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa ṣe ohun kan náà. (Ìṣe 16:4, 5) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó bá a ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, wọ́n ń rọ àwọn ará láti fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń bójú tó bá a ṣe ń yan àwọn arákùnrin sípò.
Ìgbìmọ̀ náà ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun. Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbára lé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ, ó sì ń tẹ̀ lé bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọ sọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí kì í wo ara wọn bí aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àti gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] lọ síbikíbi tó bá ń lọ.” (Ìfihàn 14:4) Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọyì àdúrà tí à ń gbà nítorí wọn.
-
Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
-
Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lóde òní?