Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 1

“Èyí Ni Ohun Tí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Túmọ̀ Sí”

“Èyí Ni Ohun Tí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Túmọ̀ Sí”

“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 JÒHÁNÙ 5:3.

1, 2. Kí ló mú kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run?

ṢÓ O nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Bó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, ó dájú pé wàá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, bó sì ṣe yẹ kí ìdáhùn rẹ rí náà nìyẹn! Ta là bá tún nífẹ̀ẹ́ bí kò ṣe Jèhófà. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló fà á táwa pẹ̀lú fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ yìí pé: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Jèhófà] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 Jòhánù 4:19.

2 Jèhófà ló kọ́kọ́ fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dá wa sórí ilẹ̀ ayé tó lẹ́wà. Ó pèsè jíjẹ, mímu àti ibùgbé fún wa. (Mátíù 5:43-48) Pabanbarì ẹ̀ wá ni pé ó ń fún wa láwọn ohun tó lè mú ká ní àjọṣe rere pẹ̀lú rẹ̀. Ó fi Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jíǹkí wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kó dá wa lójú pé bá a bá ń gbàdúrà sí òun, òun á gbọ́ àdúrà wa, òun á sì máa fi ẹ̀mí mímọ́ òun ràn wá lọ́wọ́. (Sáàmù 65:2; Lúùkù 11:13) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé láti rà wá padà, ká lè rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìfẹ́ ńlá gbáà mà ni Jèhófà ní sí wa yìí o!—Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8.

3. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? (b) Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò, ibo la sì ti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà?

3 Ó wu Jèhófà pé ká máa jọlá ìfẹ́ tóun ní sí wa títí lọ gbére. Àmọ́ ṣá, ọwọ́ wa ló kù sí yálà a máa jọlá ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí a ò ní jọlá ẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run” kẹ́ ẹ bàa lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Júúdà 21) Gbólóhùn náà, “ẹ pa ara yín mọ́,” túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ribiribi wà fún wa láti ṣe ká tó lè pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ máa fi hàn láwọn ọ̀nà tó ṣe gúnmọ́ pé inú wa dùn sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa. Nítorí náà, ìbéèrè pàtàkì kan tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?’ Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ sílẹ̀ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Ó máa dáa ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun táwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí, torí pé a máa fẹ́ láti fi han Ọlọ́run pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.

“ÈYÍ NI OHUN TÍ ÌFẸ́ FÚN ỌLỌ́RUN TÚMỌ̀ SÍ”

4, 5. Ṣàlàyé bó o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

4 Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó lo gbólóhùn náà, “ìfẹ́ fún Ọlọ́run”? Ó ń sọ nípa ìfẹ́ àtọkànwá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní sí Ọlọ́run. Ṣó o lè rántí ìgbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú ìfẹ́ yìí sí Jèhófà?

Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun, ti fífi ìfẹ́ ṣègbọràn sí Jèhófà

5 Ronú díẹ̀ ná lórí bí nǹkan ṣe rí nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé, tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú àwọn nǹkan tó ò ń kọ́. Ó wá yé ẹ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí ẹ sí, tó o sì jẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run, Jèhófà tipasẹ̀ Kristi ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹ láti di ẹni pípé, kó o sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ádámù pàdánù rẹ̀. (Mátíù 20:28; Róòmù 5:12, 18) O bẹ̀rẹ̀ sí mọrírì bó ti ṣeyebíye tó, pé Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ nígbà tó ràn án wá sáyé láti kú fún ẹ. Inú rẹ dùn, o sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó fi irú ìfẹ́ ńláǹlà bẹ́ẹ̀ hàn sí ẹ.—Ka 1 Jòhánù 4:9, 10.

6. Báwo la ṣe lè mọ̀ béèyàn bá ní ojúlówó ìfẹ́, kí sì ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run mú kó o ṣe?

6 Bí nǹkan ṣe rí lára ẹ yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ ojúlówó ìfẹ́ tó o ṣì máa ní sí Jèhófà. Àmọ́ o, ìfẹ́ kì í wulẹ̀ ṣe bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Kéèyàn nífẹ̀ẹ́ gidi sí Ọlọ́run kọjá kéèyàn wulẹ̀ sọ pé, “Mó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Bí ìgbàgbọ́ ni ojúlówó ìfẹ́ ṣe rí, ńṣe ló máa ń mú kéèyàn ṣe ohun tó máa fi hàn pé lóòótọ́ lèèyàn nífẹ̀ẹ́. (Jákọ́bù 2:26) Pàápàá jù lọ, ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn ṣe ohun tó wu ẹni téèyàn nífẹ̀ẹ́. Nítorí náà, gbàrà tó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ló ti ń wù ẹ́ pé kó o máa gbé ìgbé ayé ẹ lọ́nà tó dùn mọ́ Baba rẹ ọ̀run nínú. Ṣé Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi ni ẹ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ alọ́májàá tó tọkàn wá yìí ló mú kó o ṣe ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ. O ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o bàa lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, o sì ṣèrìbọmi, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́. (Ka Róòmù 14:7, 8) Bó o ṣe lè máa ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ wà lára ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù tún mẹ́nu kàn bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ.

“KÍ A PA ÀWỌN ÀṢẸ RẸ̀ MỌ́”

7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣẹ Ọlọ́run, kí ló sì túmọ̀ sí láti máa pa wọ́n mọ́?

7 Jòhánù ṣàlàyé pé ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí ni pé: “Kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Kí làwọn àṣẹ Ọlọ́run? Àwọn àṣẹ pàtó kan wà tí Jèhófà fún wa nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn àṣà bí ìmutípara, àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà àti irọ́ pípa kò dára. (1 Kọ́ríńtì 5:11; 6:18; 10:14; Éfésù 4:28; Kólósè 3:9) Bá a bá fẹ́ máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, àwọn ìlànà ṣíṣe kedere tó wà nínú Bíbélì la gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa darí gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe.

8, 9. Bí Bíbélì ò bá tiẹ̀ sọ ohun kan pàtó nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, báwo la ṣe lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

8 Àmọ́, ká bàa lè máa mú inú Jèhófà dùn, kì í ṣe àwọn òfin pàtó wọ̀nyí nìkan la ó máa ṣègbọràn sí. Ó ṣe tán, Jèhófà ò fi àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀, ṣe-tibí má-ṣe-tọ̀hún ra ọgbà yí wa ká. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè máa dojú kọ wá lójoojúmọ́ tí Bíbélì ò sọ ohun pàtó tó yẹ ká ṣe nípa wọn. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè mọ ohun tó máa wu Jèhófà pé ká ṣe? A lè rí àlàyé tó ṣe kedere nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ronú nínú Bíbélì. Bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ là ń lóye àwọn nǹkan tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn nǹkan tó kórìíra. (Ka Sáàmù 97:10; Òwe 6:16-19) A bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ irú ìwà àti ìṣe tí Ọlọ́run kà sí pàtàkì. Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrònú rẹ̀ á túbọ̀ máa ṣamọ̀nà wa nínú ìpinnu tá a bá ń ṣe àti nínú ìwà tá a bá ń hù. Nítorí náà, bí Bíbélì ò bá tiẹ̀ sọ ohun tó yẹ ká ṣe lórí ọ̀ràn kan, a lè máa fòye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfésù 5:17.

9 Bí àpẹẹrẹ, kò sí àṣẹ pàtó kankan nínú Bíbélì tó dá lórí wíwo àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń gbé ìwà ipá tó lékenkà tàbí ìṣekúṣe sáfẹ́fẹ́. Àmọ́, ṣé lóòótọ́ la nílò òfin pàtó tá máa sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ wò àtèyí tá ò gbọ́dọ̀ wò fún wa? A mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo irú àwọn nǹkan báwọ̀nyẹn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kó yé wa kedere pé: “Ọkàn [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Ó tún sọ pé: “Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Bá a bá ń ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run yìí, ó dájú pé a ó lè fòye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́. Nítorí náà, a ò ní fẹ́ láti máa fàwọn tó ń ṣe nǹkan tí Ọlọ́run wa kórìíra, yálà lórí tẹlifíṣọ̀n, sinimá tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì dá ara wa lára yá. A mọ̀ pé inú Jèhófà máa dùn tá a bá sá fún àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí aráyé fi ń ṣayọ̀, tí wọ́n sì kà sí eré ìnàjú tí kò léwu. *

10, 11. Kí nìdí tá a fi yàn láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa ṣègbọràn sí i?

10 Kí nìdí pàtàkì tá a fi ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́? Kí nìdí tá a fi fẹ́ láti máa gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ lọ́nà tá a mọ̀ pó bá èrò Ọlọ́run mu? Kì í wulẹ̀ ṣe nítorí ká má bàa jìyà tàbí nítorí ká lè kòòré àbájáde tó lè pani lára, èyí tó máa ń dé bá àwọn tí kò bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, la ṣe yàn láti máa tọ ọ̀nà tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Gálátíà 6:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń wo ṣíṣègbọràn sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bó ṣe máa ń wu ọmọ kan pé kí inú bàbá òun yọ́ sí òun, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá pé ká rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. (Sáàmù 5:12) Òun ni Bàbá wa, a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kò sóhun tó lè mú wa láyọ̀ tàbí ohun tó lè tẹ́ wa lọ́rùn bíi ká mọ̀ pé à ń ṣe ohun tá a ó fi máa “rí ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.”—Òwe 12:2.

11 Nítorí náà, ìgbọràn wa kì í ṣe àfipáṣe, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tó bá wù wá tàbí èyí tó bá tẹ́ wa lọ́rùn lára àwọn òfin Ọlọ́run nìkan là ń ṣègbọràn sí. * Kàkà bẹ́ẹ̀, a jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà.” (Róòmù 6:17) Bíi ti onísáàmù lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wa. Ó kọ̀wé pé: “Èmi yóò sì fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn àṣẹ rẹ, tí mo ti nífẹ̀ẹ́.” (Sáàmù 119:47) Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn, ó wá pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà. A mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, kì í wulẹ̀ ṣe nígbà tó bá wù wá nìkan, ohun tí Ọlọ́run sì ń béèrè lọ́wọ́ wa náà nìyẹn. (Diutarónómì 12:32) Ohun tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà sọ nípa Nóà la fẹ́ kí Jèhófà sọ nípa tiwa náà. Nóà ọkùnrin olóòótọ́, tó jẹ́ baba ńlá wa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nípa jíjẹ́ onígbọràn fún ọ̀pọ̀ ọdún débi tí Bíbélì fi sọ pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:22.

12. Irú ìgbọràn wo ló ń mú kí Jèhófà láyọ̀?

12 Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà bá a bá fi tinútinú ṣègbọràn sí i? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé a máa tipa bẹ́ẹ̀ mú “ọkàn-àyà [rẹ̀] yọ̀.” (Òwe 27:11) Ǹjẹ́ inú Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run máa ń dùn bá a bá ṣègbọràn sí i? Dájúdájú, inú rẹ̀ máa ń dùn, bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn! Jèhófà ló dá wa, ó sì fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó bá wù wá. Ìyẹn fi hàn pé a lómìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́; a lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run, tàbí ká yàn láti ṣàìgbọràn. (Diutarónómì 30:15, 16, 19, 20) Bá a bá fínnú fíndọ̀ yàn láti ṣègbọràn sí Jèhófà, tó sì jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run tó kún inú ọkàn wa fọ́fọ́ ló mú ká pinnu láti ṣègbọràn sí i, inú Baba wa ọ̀run máa ń dùn gan-an ni, ó sì máa ń láyọ̀. (Òwe 11:20) Á tún wá já sí pé ọ̀nà tó dára jù láti máa gbé la yàn yẹn.

“ÀWỌN ÀṢẸ RẸ̀ KÌ Í ṢE ẸRÙ ÌNIRA”

13, 14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé “àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] kì í ṣe ẹrù ìnira,” ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣàpèjúwe èyí?

13 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun kan tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa, ó ní: “Àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹrù ìnira” nínú 1 Jòhánù 5:3 túmọ̀ lóréfèé sí “wúwo.” * Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa kì í ṣe àwọn nǹkan tó nira. Àwọn òfin rẹ̀ ò kọjá ohun táwa ẹ̀dá aláìpé lè ṣègbọràn sí.

14 A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí. Ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ní kó o bá òun kẹ́rù lọ sí ilé tuntun. Ó ní àpótí tó pọ̀ láti kó. Ẹnì kan lè dá àwọn kan lára wọn gbé nítorí pé wọ́n fúyẹ́, àmọ́ àwọn míì wúwo jù fẹ́nì kan láti dá gbé. Ọ̀rẹ́ ẹ ló máa sọ èyí tó fẹ́ kó o gbé lára àwọn àpótí náà fún ẹ. Ǹjẹ́ ó máa ní kó o gbé èyí tó mọ̀ pó wúwo jù fún ẹ lára àwọn àpótí náà? Rárá o. Kò ní fẹ́ kó o ṣera ẹ léṣe níbi tó o ti ń dù láti dá àwọn àpótí náà gbé. Bákan náà, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti onínúure ò ní sọ pé ká pa àwọn òfin tó mọ̀ pó ṣòro jù fún wa mọ́. (Diutarónómì 30:11-14) Kò jẹ́ di ẹrù òfin tó nira rù wá. Jèhófà mọ ibi tí agbára wá mọ, torí pé “òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:14.

15. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé àǹfààní wa làwọn àṣẹ Jèhófà wà fún?

15 Àwọn àṣẹ Jèhófà kì í ṣe ẹrù ìnira rárá àti rárá; àǹfààní wa ni wọ́n wà fún. (Ka Aísáyà 48:17) Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Jèhófà pàṣẹ fún wa, láti máa pa gbogbo ìlànà wọ̀nyí mọ́, láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa, fún ire wa nígbà gbogbo, kí a lè máa wà láàyè nìṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.” (Diutarónómì 6:24) Ó yẹ kó dá àwa pẹ̀lú lójú pé àǹfààní wa làwọn òfin Jèhófà wà fún; ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni pé káwọn òfin náà máa ṣàǹfààní fún wa títí lọ. Àbí, báwo ni ì bá tún ṣe jẹ́? Àwámáàrídìí ni ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run. (Róòmù 11:33) Nítorí náà, ó mọ òun tó dára jù lọ fún wa. Jèhófà tún jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ga jù lọ. (1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an yìí máa ń fara hàn nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń sọ àti ohun tó ń ṣe. Orí rẹ̀ ló ń gbé gbogbo àṣẹ tó ń pa fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kà.

16. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé burúkú bùrùjà yìí àti ẹran ara wa aláìpé máa ń fẹ́ ká máa ṣe ohun tí kò tọ́, báwo la ṣe lè máa jẹ́ onígbọràn?

16 Èyí ò túmọ̀ sí pé ó rọrùn láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kí ayé burúkú bùrùjà tó wà “lábẹ́ agbára ẹni burúkú” yìí máa bàa máa darí wa. (1 Jòhánù 5:19) Ó tún di dandan ká má ṣe gbà fún ẹran ara wa aláìpé tó máa ń fẹ́ ká rú òfin Ọlọ́run. (Róòmù 7:21-25) Àmọ́, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè kẹ́sẹ járí. Àwọn tó bá ń sapá láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, máa ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Ó máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún “àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.” (Ìṣe 5:32) Ẹ̀mí yẹn máa ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó dára, ìyẹn ni àwọn ànímọ́ ṣíṣeyebíye tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígbọràn.—Gálátíà 5:22, 23.

17, 18. (a) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú ìwé yìí, bá a bá sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó tẹ̀ lé èyí?

17 Nínú ìwé yìí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Jèhófà àti ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ nípa ìwà tó yẹ ká máa hù àti ọ̀pọ̀ nǹkan míì tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ohun pàtàkì mélòó kan wà tá a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn. Ẹ jẹ́ ká rántí pé Jèhófà kò fipá mú wa láti máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀; ńṣe ló fẹ́ ká máa fínnú fíndọ̀ ṣègbọràn sí òun látọkàn wá. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé ńṣe ni Jèhófà ń fẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tá a fi máa rí ìbùkún rẹ̀ gbà lọ́pọ̀ yanturu nísinsìnyí, ká sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Ǹjẹ́ ká má ṣe ṣi ohun tí ìgbọràn látọkànwá túmọ̀ sí lóye, ìyẹn ni pé ó jẹ́ àǹfààní ṣíṣeyebíye tá a ní láti fi hàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó.

18 Ká bàa lè máa fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ti mú kó dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ wa. Síbẹ̀, kí ẹ̀rí ọkàn yìí tó lè máa darí wa síbi tó dáa, a gbọ́dọ̀ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa jíròrò rẹ̀ nínú orí tó tẹ̀ lé èyí.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo ìjíròrò tó dá lórí bó o ṣe lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé, èyí tó wà ní Orí 6 nínú ìwé yìí.

^ ìpínrọ̀ 11 Àwọn ẹ̀mí búburú pàápàá lè fipá ṣègbọràn. Nígbà tí Jésù pàṣẹ fáwọn ẹ̀mí èṣù pé kí wọ́n jáde kúrò lára àwọn kan tó lẹ́mìí èṣù, kò sí ohun táwọn ẹ̀mí èṣù náà lè ṣe ju pé kí wọ́n tẹrí ba kí wọ́n sì ṣègbọràn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tinú wọn wá.—Máàkù 1:27; 5:7-13.

^ ìpínrọ̀ 13 Mátíù 23:4 lo ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe “àwọn ẹrù wíwúwo,” ìyẹn àwọn òfin jáǹtìrẹrẹ àtàwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ táwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí gbé ka àwọn èèyàn lórí. Ọ̀rọ̀ kan náà yìí la tú sí “aninilára” nínú Ìṣe 20:29, 30, ó sì ń tọ́ka sí àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń ni àwọn èèyàn lára, tí wọ́n ń “sọ àwọn ohun àyídáyidà,” tí wọ́n sì ń wọ́nà láti ṣi àwọn ẹlòmíì lọ́nà.