ORÍ 7
Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Lo Fi Ń Wò Ó?
“Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.”—SÁÀMÙ 36:9.
1, 2. Ẹ̀bùn wo ni Ọlọ́run fún wa tó ṣe pàtàkì gan-an lásìkò tá a wà yìí, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
BÀBÁ wa ọ̀run fún wa ní ẹ̀bùn aláìlẹ́gbẹ́ kan, ìyẹn ẹ̀mí tá a ní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó lọ́gbọ́n lórí, èyí tó ń jẹ́ ká lè máa fàwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Bí kì í bá ṣe ti ẹ̀bùn iyebíye yìí ni, a ò bá má lè ronú lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì. Tá a bá ń fàwọn ìlànà wọ̀nyí ṣèwà hù, òye wa máa jinlẹ̀ tó bá dọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run, a máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ó sì lè “kọ́ agbára ìmòye wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
2 Àsìkò yìí gan-an ló yẹ ká máa ronú lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì, torí ayé ti dojú rú débi pé kò síye òfin tá a lè ṣe tó máa sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní onírúurú ipò tó lè dé bá wa láyé. Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn ti fi hàn pé bí nǹkan ṣe rí gan-an nìyẹn pàápàá tó bá dọ̀ràn lílo oògùn tó ní èròjà ẹ̀jẹ̀ nínú àti fífi ẹ̀jẹ̀ ṣètọ́jú aláìsàn. Pàtàkì lọ̀ràn yìí lójú àwọn tó fẹ́ máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Síbẹ̀ tá a bá mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí ọ̀ràn yìí, kò yẹ kó ṣòro fún wa láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, tí ò ní kó ẹ̀rí ọkàn wa sí yọ́ọ́yọ́ọ́, tó sì máa jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Òwe 2:6-11) Jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn ìlanà wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Ẹ̀MÍ ÀTI Ẹ̀JẸ̀ ṢEYEBÍYE
3, 4. Ìgbà wo ni Ìwé Mímọ́ kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ṣeyebíye tó, orí àwọn ìlànà wo ló sì gbé e kà?
3 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Kéènì pa Ébẹ́lì ni Jèhófà kọ́kọ́ sọ Jẹ́nẹ́sísì 4:10) Lójú Jèhófà ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì ni ẹ̀mí rẹ̀ èyí tí Kéènì fòpin sí. Ká ṣáà sọ pé ńṣe lẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì ké pe Ọlọ́run pé kó gbẹ̀san òun lára ẹni tó ṣekú pa òun.—Hébérù 12:24
ohun tó so ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ pọ̀, tó sì wá ṣàlàyé bí wọ́n ṣe jẹ́ mímọ́ tàbí bí wọ́n ṣe ṣeyebíye tó. Ọlọ́run sọ fún Kéènì pé: “Fetí sílẹ̀! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (4 Lẹ́yìn Ìkun Omi tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà, Ọlọ́run gba ẹ̀dá èèyàn láyè láti máa pa ẹran jẹ, ṣùgbọ́n kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn. Ọlọ́run sọ pé: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ. Àti pé, ní àfikún sí ìyẹn, ẹ̀jẹ̀ yín ti ọkàn yín ni èmi yóò béèrè padà.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:4, 5) Àṣẹ yìí kan gbogbo àtọmọdọ́mọ Nóà títí kan àwa tá a wà láyé lónìí. Èyí tún fìdí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti bá Kéènì sọ tẹ́lẹ̀ múlẹ̀. Ó sọ fún Kéènì pé ẹ̀jẹ̀ gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀mí wọn. Àṣẹ yẹn tún jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà, tó jẹ́ Orísun Ìyè, máa dá gbogbo ẹ̀dá tí kò bá fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ lẹ́jọ́.—Sáàmù 36:9.
5, 6. Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ jẹ́ mímọ́ ó sì ṣeyebíye? (Tún wo “ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Àwọn Ẹranko Jọ Ẹ́ Lójú.”)
5 Òótọ́ tí ò ṣeé já ní koro méjèèjì yìí fara hàn nínú Òfin Mósè. Léfítíkù 17:10, 11 sọ pe: “Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí . . . tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí dájúdájú, èmi yóò dojú mi kọ ọkàn tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀, ní tòótọ́, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀. Nítorí ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀, èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín, nítorí pé ẹ̀jẹ ni ó ń ṣe ètùtù nípasẹ̀ ọkàn tí ń bẹ nínú rẹ̀.” *—Wo àpótí náà “ Bí Ẹ̀jẹ̀ Ṣe Lè Pa Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ́”.
6 Ohun tí ò bá ti mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n bá dú sórí pẹpẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ dà á sílẹ̀. Tá a bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà Diutarónómì 12:16; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Àmọ́, ó yẹ kó ye wa pé ìyẹn ò ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá tàṣejù bọ̀ ọ́, kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí yọ gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó bá lẹ̀ mọ́ ara ẹran tí wọ́n bá fẹ́ jẹ o. Wọ́n lè jẹ ẹran èyíkéyìí tó bá wù wọ́n, tí wọ́n bá ṣáà ti dú u tí wọ́n sì tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sílẹ̀ torí ohun tí Ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí ń fẹ́ kí wọ́n ṣe nìyẹn.
ìṣàpẹẹrẹ, èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ti dá ẹ̀mí yẹn padà sọ́dọ̀ Ẹni tó dá a nìyẹn. (7. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé òun ka ẹ̀jẹ̀ sí pàtàkì?
Ìṣe 13:22) Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ ẹ́ gan-an, mẹ́ta lára àwọn ọkùnrin tó ń tẹ̀lé e fi ògbójú wọ àgọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti fa omi látinú kànga wá fún un. Kí ni Dáfídì ṣe? Ó béèrè pé: “Èmi yóò ha mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n lọ ní fífi ọkàn wọn wewu?” Lójú Dáfídì, mímu omi yẹn fẹ́ dà bí ìgbà téèyàn ń mu ẹ̀jẹ̀ àwọn tó fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè rí omi yẹn bù wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òùngbẹ ń gbẹ ẹ́ gan-an, ó “dà á jáde fún Jèhófà.”—2 Sámúẹ́lì 23:15-17.
7 Dáfídì, “ọkùnrin tí ó tẹ́ ọkàn àyà [Ọlọ́run] lọ́rùn,” lóye àwọn ìlànà tó kín òfin Ọlọ́run lórí ẹ̀jẹ̀ lẹ́yìn. (8, 9. Ǹjẹ́ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ ti yí padà lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀? Ṣàlàyé.
8 Ní nǹkan bí egbèjìlá [2,400] ọdún lẹ́yìn tí Jèhófà fún Nóà àtàwọn ọmọ ẹ̀ láṣẹ lórí ẹ̀jẹ̀ àti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn tí Jèhófà bá àwọn èèyàn ẹ̀ dá Májẹ̀mú òfin, ó mí sí ìgbìmọ̀ olùdarí ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti kọ̀wé pé: “Ẹ̀mi mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi nǹkan pípọndandan wọ̀nyí, láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa àti sí àgbèrè.”—Ìṣe 15:28, 29.
9 Ó hàn kedere pé ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà yẹn lọ́hùn-ún lóye pé ẹ̀jẹ̀ jẹ́ mímọ́, wọ́n sì gbà pé ẹni tó bá lò ó lọnà tí kò tọ́ kò yàtọ̀ sí abọ̀rìṣà tàbí ẹni tó ń ṣàgbèrè. Báwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lóye ẹ̀ lónìí gan-an nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n máa ń ronú lé, àwọn ìpinnu tí wọ́n máa ń ṣe tó bá dọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ máa ń dùn mọ́ Jèhófà nínú.
LÍLO Ẹ̀JẸ̀ FÚN ÌTỌ́JÚ ALÁÌSÀN
10, 11. (a) Ojú wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo gbígba ẹ̀jẹ̀ àtàwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ sára? (b) Irú ìtọ́jú míì tó la ẹ̀jẹ̀ lọ wo ló lè fà á pé káwọn Kristẹni ṣèpinnu tó yàtọ̀ síra?
10 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ohun tí ‘títakété sí ẹ̀jẹ̀’ túmọ̀
sí ni pé a kò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ sára, a kò gbọ́dọ̀ fẹ̀jẹ̀ tọrẹ, a kò sì gbọ́dọ̀ máa fẹ̀jẹ̀ tiwa alára pa mọ́ dìgbà tá a bá máa nílò ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé a fẹ́ pa òfin Ọlọ́run mọ́, a kì í gba èyíkéyìí lára àwọn èròjà mẹ́rìn tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, bíi sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì àti omi inú ẹ̀jẹ̀.11 Lóde òní, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti túbọ̀ pín ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èròjà mẹrin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí wọ́n lè máa lò wọ́n lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ṣé Kristẹni kan lè gbà kí wọ́n fi èyíkéyìí lára ìpín tó wá látara àwọn èròjà tí wọ́n ti pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí tọ́jú òun tàbí kó lò ó? Ṣé ojú tó fi ń wo “ẹ̀jẹ̀” kọ́ ló máa fi wò ó báyìí? Ìpinnu ara ẹni lèyí. Irú ìpinnu ara ẹni bẹ́ẹ̀ náà la máa ṣe tó bá dọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn tó kan lílo ẹ̀rọ tó ń sẹ́ ẹ̀jẹ̀ láti sẹ́ ẹ̀jẹ̀ wa kí wọ́n tó dá a padà sí wa lára, dída oògùn tó ń mẹ́jẹ̀ pọ̀ sí i mọ́ ẹ̀jẹ̀ wa àti gbígbe ẹ̀jẹ̀ aláìsàn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún kí wọ́n lè dá a padà sí i lára lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ abẹ, Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ.”
kìkì tí wọn ò bá ṣáà ti tọ́jú ẹ̀jẹ̀ onítọ̀hún pa mọ́ fún àkókò kan kí wọ́n tó lò ó fún un.—Wo “12. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn?
12 Ṣé ojú kékeré ni Jèhófà fi ń wo àwọn ọ̀ràn tó yẹ kéèyàn dá pinnu? Rárá o, ó máa ń fẹ́ mọ èrò wa àti ohun tó wà lẹ́yìn ìwà tá à ń hù. (Ka Òwe 17:3; 24:12) Nítorí náà, tá a bá ti gbàdúrà sí Jèhófà tá a sì ti ṣàwọn ìwádìí tó pọn dandan lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn kan, ẹ jẹ́ ká tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́. (Róòmù 14:2, 22, 23) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fagídí mú wa ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn tiwọn fàyè gbà, bẹ́ẹ̀ làwa náà ò gbọ́dọ̀ máa béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé, “Tó bá jẹ́ pé ìwọ lọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ sí, kí lo máa ṣe?” Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa “ru ẹ̀rù . . . ara rẹ̀.” *—Gálátíà 6:5; Róòmù 14:12; wo àpótí náà, “ Ṣé Mo Ka Ẹ̀jẹ̀ sí Ohun Mímọ́?”
ÀWỌN ÒFIN JÈHÓFÀ FI HÀN PÉ Ó NÍFẸ̀Ẹ́ WA BÍI BÀBÁ SỌ́MỌ
13. Kí làwọn òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà fi hàn nípa irú ẹni tó jẹ́? Ṣàkàwé.
13 Àwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Aṣòfin Àgbà àti Bàbá onífẹ̀ẹ́ tó níre àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kàn ni Jèhófà. (Sáàmù 19:7-11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣẹ tó fún wa pé ká “ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀” kì í ṣe òfin lórí ọ̀ràn ìlera, síbẹ̀ ó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn àìsàn àti ààrùn tí ìfàjẹsínilára ń fà. (Ìṣe 15:20) Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn dókítà ló ti gbà pé ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ni ìlànà tó dáa jù lọ tó yẹ káwọn máa tẹ̀lé fún títọ́jú aláìsàn lóde òní. Ní tàwọn Kristẹni, irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ń fìdí òye Jèhófà tí kò láfiwé àti ìfẹ́ bàbá sọ́mọ tó ní sí wa múlẹ̀ ni.—Ka Aísáyà 55:9; Jòhánù 14:21, 23.
14, 15. (a) Òfin wo ló fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe lè fàwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ àwọn òfin tó ń dáàbò boni wọ̀nyí sílò?
Diutarónómì 22:8; 1 Sámúẹ́lì 9:25, 26; Nehemáyà 8:16; Ìṣe 10:9) Ọlọ́run tún pa á láṣẹ pé kí wọ́n máa so àwọn akọ màlúù wọn tó bá ya ẹhànnà mọ́lẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:28, 29) Ẹnikẹ́ni tí kò bá pa àwọn àṣẹ wọ̀nyí mọ́ kò ní ire àwọn ẹlòmíì lọ́kàn, ó sì lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.
14 Ọ̀pọ̀ lára àwọn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbaanì fi hàn pé ó níre wọn lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mọ ògiri yí òrùlé wọn ká kéèyàn má bàa rébọ́ látibẹ̀ nítorí wọ́n sábà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan níbẹ̀. (15 Báwo la wá ṣe lè fàwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ àwọn òfin wọ̀nyí sílò? O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ipò tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ wà, bíwọ alára ṣe máa ń wakọ̀, ipò táwọn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ wà, bí ilé tó ò ń gbé ṣe rí, bí ibi iṣẹ́ rẹ ṣe rí àti irú eré ìnàjú tó o fẹ́ràn láti máa ṣe? Láwọn orílẹ̀-èdè kan, jàǹbá ló sábà máa ń ṣokùnfà ikú àwọn ọmọdé torí ńṣe ni wọ́n máa ń fẹ̀mí ara wọn wewu lórí ohun tí ò tó nǹkan. Àmọ́, àwọn ọmọdé tó fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run kì í fẹ̀mí ara wọn ṣeré, wọn kì í sì í yayọ̀ pọ̀rọ́ lórí ohun tó lè mú ẹ̀mí lọ. Wọn ò gọ̀ débi pé kí wọ́n máa ronú pé àwọn ọ̀dọ́ ò lè ṣèṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ wọn nípa sísá fún ohunkóhun tó lè kó wọn sínú pákáǹleke.—Oníwàásù 11:9, 10.
16. Ìlànà inú Bíbélì wo ló jẹ mọ́ oyún ṣíṣẹ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
16 Ẹ̀mí àwọn ọmọ inú oyún pàápàá ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Láyé ọjọ́un, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni tó bá ta lu aláboyún tí aláboyún náà tàbí ọmọ rẹ̀ sì kú ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, ó ti di apààyàn, ẹ̀mí ara ẹ̀ ló sì máa fi dí i, ìyẹn ló túmọ̀ sí “ọkàn fún ọkàn.” * (Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23) O lè wá fojú yàwòrán bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá rí báwọn èèyàn ṣe ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye oyún dà nù lọ́dọọdún, bóyá nítorí pé wọn ò tíì nílò wọn báyìí tàbí bóyá nítorí ìwà ìṣekúṣe tó ti jàrábà wọn.
17. Báwo lo ṣe lè tu ẹni tó ti ṣẹ́yún kó tó wá mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú?
Sáàmù 103:8-14; Éfésù 1:7) Kristi alára sọ pé: “Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”—Lúùkù 5:32.
17 Ó dáa ná, obìnrin tó ti ṣẹ́yún kó tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú Bíbélì ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run ò ní fojú àánú hàn sí i ni? Rárá o! Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, kò sẹ́ni tó ronú pìwà dà látọkàn wá tí Jèhófà ò ní ro tẹ̀jẹ̀ Jésù mọ́ lára, kó sì wá dárí ji onítọ̀hún. (MÁ RÒRÒKURÒ!
18. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ohun kan tó ti rán ọ̀pọ̀ èèyàn lọ sínú sàárè láìrò tẹ́lẹ̀?
18 Bá a bá yọwọ́ ti pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ẹnikẹ́ni léṣe, Jèhófà ò tún fẹ́ ká máa ṣe ohun tó ti rán ọ̀pọ̀ lọ sínú sàárè láìrò tẹ́lẹ̀, ìyẹn ni ìkórìíra. Àpọ̀sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Olúkúlúkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn.” (1 Jòhánù 3:15) Kì í wulẹ̀ ṣe pé ẹni yìí kórìíra arákùnrin rẹ̀, àmọ́ ikú ẹ̀ gan-an ló ń wá. Irú ẹni yìí lè ti máa fọ̀rọ̀ èké ba arákùnrin rẹ̀ lórúkọ jẹ́ tàbí kó máa fẹ̀sùn èké tó lè yọrí sí ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Jèhófà kàn án. (Léfítíkù 19:16; Diutarónómì 19:18-21; Mátíù 5:22) Ẹ ò rí i pó ṣe pàtàkí nígbà náà pé ká fa gbogbo èròkérò tó lè ta gbòǹgbò sọ́kàn wa tu ní kíákíá!—Jákọ́bù 1:14, 15; 4:1-3.
19. Ojú wo lẹni táwọn ìlànà inú Bíbélì ń tọ́ sọ́nà fi máa wo àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 11:5 àti Fílípì 4:8, 9?
19 Gbogbo àwọn tó fẹ́ fìwà jọ Jèhófà ní ti fífojú pàtàkì wo ẹ̀mí tí wọ́n sì fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ gbọ́dọ̀ kórìíra onírúurú ìwà ipá. Sáàmù 11:5 sọ pé: “Ọkàn [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Èyí kì í wulẹ̀ ṣe ànímọ́ kan tí Ọlọ́run ní; ìlànà tó yẹ kó máa tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ni. Ìlànà yìí ló ń jẹ́ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa sá fún àwọn eré ìnàjú tó lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá. Ọ̀rọ̀ náà pé “Ọlọ́run àlàáfíà” ni Jèhófà tún jẹ́ kó di dandan fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ láti máa fàwọn ohun tó lè mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì, tá á jẹ́ ká máa gbóríyìn fún wọn kún ọkàn wa, ká sì níwà rere torí àwọn nǹkan wọ̀nyí ló lè mú àlàáfíà wá.—Ka Fílípì 4:8, 9.
TA KÉTÉ SÁWỌN ÈTÒ TÍ Ń FẸ̀JẸ̀ WẸ̀
20-22. Kí làwọn Kristẹni máa ń ṣe tó bá dọ̀ràn bíbá ayé yìí ṣọ̀rẹ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
20 Lójú Ọlọ́run, ètò Sátánì lápapọ̀ ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ètò òṣèlú rẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ pè ní ẹranko ẹhànnà ti fikú pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn títí kan àwọn èèyàn Jèhófà. (Dáníẹ́lì 8:3, 4, 20-22; Ìṣípayá 13:1, 2, 7, 8) Ètò ọrọ̀ ajé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbára ayé tó ń hùwà bí ẹranko ẹhànnà yìí láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kó ọrọ̀ jọ látinú ṣíṣe àwọn ohun èlò ogun gìrìwò tá ò tíì rírú ẹ̀ rí. Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà”!—1 Jòhánù 5:19.
21 Torí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kì í ṣe “apa kan ayé,” wọn kì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í lọ́wọ́ sí ogun jíjà, kí wọ́n lè tipa báyìí sá fún jíjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tàbí pípín nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlòmíì. * (Jòhánù 15:19; 17:16) Bí i ti Kristi, wọn kì í fìjà pẹẹ́ta táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n sì máa ń gbàdúrà fún wọn.—Mátíù 5:44; Róòmù 12:17-21.
22 Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yẹra fún níní àjọṣe èyíkéyìí pẹ̀lú “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé tó jẹ́ apá tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ jù lọ lára ètò Sátánì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” Nítorí náà, Ọlọ́run kì wá nílọ̀ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.”—Ìṣípayá 17:6; 18:2, 4, 24.
23. Kí ló túmọ̀ sí láti jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá?
23 Jíjáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá kọjá kéèyàn kan fìwé sọ pé òun kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wọn mọ́. Ó tún túmọ̀ sí pé kéèyàn kórìíra ìwà ibi tí ìsìn èké gbà láàyè láàárín àwọn ọmọ ìjọ wọn tàbí táwọn fúnra wọn ń gbé lárugẹ, irú bí ìṣekúṣe, lílọ́wọ́ sí ètò òṣèlú àti fífi gbogbo ayé wọn lépa ọrọ̀. (Ka Sáàmù 97:10; Ìṣípayá 18:7, 9, 11-17) Ọ̀pọ̀ ìgbà sì làwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń yọrí sí ìpànìyàn.
24, 25. Kí ló lè mú kí Ọlọ́run fàánú hàn sí ẹnì kan tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àmọ́ tó ti ronú pìwà dà, ètò wo ló sì fi irú àánú bẹ́ẹ̀ hàn lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
24 Kó tó di pé a dara pọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́, gbogbo wa la ti kín ètò Sátánì lẹ́yìn láwọn ọ̀nà kan, èyí sì ti jẹ́ káwa náà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Àmọ́ nítorí pé a ti yí ìwà wa padà, tá a nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi tá a sì ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, à ń rí àánú Ọlọ́run gbà ó sì ń dáàbò bò wá. (Ìṣe 3:19) Irú ààbò yìí làwọn ìlú ààbò tó wà lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì ṣàpẹẹrẹ.—Númérì 35:11-15; Diutarónómì 21:1-9.
25 Báwo ni ètò yẹn ṣe wúlò tó nígbà yẹn? Bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ṣèèṣì pààyàn, ó ní lati sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ààbò wọ̀nyí. Lẹ́yìn táwọn adájọ́ tó tóótun bá ti yẹ ọ̀ràn ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà wò dáadáa, wọ́n á gbà á láyè láti máa gbé nílùú ààbò náà títí dìgbà tí àlùfáà àgbà bá kú. Ìgbà yẹn ni wọ́n á tó dá a sílẹ̀ láti máa gbé níbikíbi tó bá wù ú. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ńlá lèyí jẹ́ ní ti bí Ọlọ́run ṣe ń fàánú hàn àti béèyàn Mátíù 24:21; 2 Kọ́ríńtì 6:1, 2.
ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀! Bí Ọlọ́run ṣe fún wọn láwọn ìlú ààbò nígbà yẹn náà ló ṣe ń tipasẹ ẹbọ ìràpadà Kristi dáàbò bò wá ká má bàa kú bá a bá ṣèèṣì rú àwọn òfin rẹ̀ tó dá lé fífi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀. Ṣó o mọrírì àǹfààní yìí? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì rẹ̀? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o pe àwọn ẹlòmíì wá sínú ìlú ààbò ìṣàpẹẹrẹ yìí, pàápàá lásìkò tí “ìpọ́njú ńlá” ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé yìí.—FI HÀN PÉ Ẹ̀MÍ ÀWỌN ÈÈYÀN JỌ Ẹ́ LÓJÚ NÍPA WÍWÀÁSÙ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
26-28. Báwo lohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lónìí ṣe jọ tọjọ́ wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ọ̀nà wo la sì lè gbà máa bá a lọ ní dídúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
26 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ẹni tí Jèhófà fún ní ojúṣe gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì tó bá dọ̀ràn ìjọsìn. Ọlọ́run sọ fún un pé: “Ìwọ́ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìwọ yóò sì fún wọn ní ìkìlọ̀.” Tó bá lọ jẹ́ pé Ìsíkíẹ́lì ò ṣe ojúṣe ẹ̀ ni, ọwọ́ ẹ̀ ni Jèhófà ò bá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn tó kú nígbà tí Jèhófà dá àwọn ará Jẹrúsálẹ́mù lẹ́jọ́. (Ìsíkíẹ́lì 33:7-9) Àmọ́ Ìsíkíẹ́lì ṣègbọràn, kò sì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.
27 Lónìí, òpin ayé Sátánì lápapọ̀ ti sún mọ́lé. Nítorí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí ojúṣe, àǹfààní ló sì jẹ́ fún wa láti máa pòkìkí “ọjọ́ ẹ̀sàn” Ọlọ́run papọ̀ pẹ̀lú wíwàásù Ìjọba náà. (Aísáyà 61:2; Mátíù 24:14) Ṣé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe tó ní láti wàásù. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo nítorí pé èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún yín.” (Ìṣe 20:26, 27) Àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká tẹ̀ lé mà lèyí o!
28 Ká sòótọ́, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ wa bí i bàbá sọ́mọ, a gbọ́dọ̀ ṣe ju wíwulẹ̀ fojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ wò ó lọ. A tún gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní mímọ́ tónítóní tàbí ká jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀ bí orí tó tẹ̀ lé e ṣe máa ṣàlàyé.
^ ìpínrọ̀ 5 Nígbà tí ìwé ìròyìn Scientific American máa sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé “ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀,” ó sọ pé: “Tá a bá yọwọ́ ọ̀rọ̀ àfiwé tí Ọlọ́run lò níhìn-ín, kò sírọ́ nínú ohun tó sọ, torí pé gbogbo onírúurú sẹ́ẹ̀lì ló gbọ́dọ̀ wà nínú ẹ̀jẹ̀ kéèyàn tó lè wà láàyè.”
^ ìpínrọ̀ 12 Wo Jí! August 2006 ojú ìwé 3 sí 12 (Gẹ̀ẹ́sì). Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
^ ìpínrọ̀ 16 Àwọn tó ń ṣèwádìí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù yìí “jẹ́ kó hàn kedere pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣíṣé aláboyún léṣe nìkan lọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.” Ẹ máà tún gbàgbé pé Bíbélì ò sọ bí oyún náà ṣe gbọ́dọ̀ dàgbà tó kẹ́ni tó jẹ́ kó wálẹ̀ tó lè rí ìdájọ́ mímúná Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 70 Wo Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ fún àlàyé síwájú sí i.