APA 11
Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní
LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́. Àmọ́ Jésù sọ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló máa ní ìgbàgbọ́ tó jẹ́ ìgbàgbọ́ òdodo. Ó sọ pé: “Fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.
Báwo la ṣe lè mọ àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo lóde òní? Jésù sọ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀ . . . Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:16, 17) Èyí fi hàn pé “èso àtàtà” ni ìgbàgbọ́ òdodo máa ń so. Ìyẹn ni pé ó ń mú kéèyàn máa hu àwọn ìwà tí Ọlọ́run fẹ́. Bí irú àwọn ìwà wo?
Wọn Kì Í Ṣi Agbára Lò
Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń lo agbára àti àṣẹ tí wọ́n bá ní láti fi gbé Ọlọ́run ga, wọ́n sì máa fi ń ṣe ọmọnìkejì wọn lóore. Jésù kọ́ wa pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Máàkù 10:43) Bákan náà, àwọn ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́ òdodo kì í hùwà ìkà sí àwọn tó wà ní abẹ́ àṣẹ wọn, yálà nínú ilé wọn tàbí níbòmíràn. Wọ́n máa ń ṣìkẹ́ aya wọn, wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì máa ń fi ìfẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.”—1 Pétérù 3:7.
Bákan náà, aya tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo gbọ́dọ̀ “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Àwọn aya gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn” kí wọ́n sì “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.” (Títù 2:4) Àwọn bàbá àti ìyá tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo máa rí i dájú pé àwọn ń rí àyè gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa ń kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣe àpọ́nlé àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, yálà ní ilé tàbí ibi iṣẹ́ tàbí ní ibikíbi. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí, pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣítí tí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kí o má [ṣe] gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Ẹ́kísódù 23:8) Wọn kì í hùwà àbòsí tàbí ìwà ìrẹ́jẹ ní ipòkípò tí wọ́n bá wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Torí náà, wọ́n máa ń rí ẹ̀san tí Jésù sọ pé ó wà fún irú èèyàn bíi tiwọn, ó ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Wọ́n Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bí Ọlọ́run Ṣe Là Á Kalẹ̀
Àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń fínnúfíndọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run, lójú tiwọn 1 Jòhánù 5:3) Wọ́n mọ̀ dájú pé “òfin Jèhófà pé . . . Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 19:7, 8.
sì rèé, “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (Nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo, wọ́n kórìíra gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ṣíṣe ẹ̀tanú. Wọn kì í gbé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan tàbí àwọn èèyàn kan ga ju àwọn míì lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Ọlọ́run ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Nítorí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ìgbàgbọ́ òdodo ń mú kéèyàn máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo kì í bani jẹ́ tàbí kó máa sọ̀rọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀ láìdáa. Ìwé Sáàmù kan tí Dáfídì kọ sọ irú èèyàn tí Ọlọ́run máa ń dunnú sí, ó ní ẹni náà: “Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́, kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 15:3.
Wọ́n Ń Ṣe Ohun Tó Bá Ọgbọ́n Ọlọ́run Mu
Ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nìkan ṣoṣo ni àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń tẹ̀ lé nínú ẹ̀sìn wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Wọ́n máa ń rí i dájú pé ìwà tó bá “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” mu nìkan ni àwọn ń hù sí ọmọnìkejì wọn, torí “ọgbọ́n” yìí máa ń “mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.” (Jákọ́bù 3:17) Wọ́n máa ń kórìíra àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti àṣà ẹ̀sìn tí Ọlọ́run kò dunnú sí, wọn kì í lọ́wọ́ sí ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀mí òkùnkùn, wọ́n sì máa ń “ṣọ́ra fún [bíbọ] òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.
Wọ́n Ní Ojúlówó Ìfẹ́
Mósè tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Bí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo sì ṣe máa ń fẹ́ràn Ọlọ́run nìyẹn. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Wọ́n máa ń “fi ọpẹ́ fún Jèhófà,” wọ́n sì máa ń “ké pe orúkọ rẹ̀,” torí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé ó ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn. (Sáàmù 105:1) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún máa ń tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Wọ́n kórìíra ìwà jàgídíjàgan, wọ́n sì máa ń rí i pé àwọn “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Wọn kò “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́,” torí náà a lè ṣe àkàwé ìwà wọn lọ́nà báyìí pé, wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” wọ́n sì “fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” (Aísáyà 2:4) Nítorí èyí, wọ́n “ní ìfẹ́ láàárín ara” wọn, wọ́n sì ń hùwà bí ọmọ ìyá sí ara wọn ní gbogbo ibi tí wọ́n bá wà kárí ayé. (Jòhánù 13:35) Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ àwọn èèyàn kan tó ní irú ìwà wọ̀nyí lóde òní?