APA 13
Ìgbàgbọ́ Òdodo Máa Mú Kí O Ní Ayọ̀ Ayérayé
ÌWÉ MÍMỌ́ sọ pé: “Ẹni tí í ṣe olódodo—nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni yóò yè.” (Róòmù 1:17) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ìlérí kan wà tí Ọlọ́run ṣe, èyí tó kan ìwọ náà. Àwọn ọ̀nà wo ló gbà kàn ọ́?
Lẹ́yìn tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run torí rẹ̀ rán an wá sí ayé, Ọlọ́run gbé e sí òkè sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní ọ̀run. Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ó nígbà tí “a gbé e sókè, àwọsánmà sì gbà á lọ kúrò ní ojúran wọn.” (Ìṣe 1:9) Nígbà tó dé ọ̀run, Ọlọ́run sọ ọ́ di Ọba alágbára ní ọ̀run. Láìpẹ́, Jésù, ẹni tí Ìwé Mímọ́ pè ní “Ọmọ ènìyàn” yóò dé “nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” (Mátíù 25:31, 32) Ìgbà wo ni èyí máa ṣẹlẹ̀?
Ìwé Mímọ́ sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan máa wà tí oríṣiríṣi wàhálà yóò máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé, tó máa jẹ́ ara àmì tó fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Mèsáyà máa ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Jésù ṣàlàyé díẹ̀ nínú àwọn ohun tó máa jẹ́ àmì náà, ó ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.”—Lúùkù 21:7, 10, 11.
À ń rí i kedere lóde òní pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ti ń ṣẹ. Jésù máa tó wá pa àwọn tó ń ṣe láabi run. Níkẹyìn, Ọlọ́run yóò pa Sátánì pàápàá run! Gbogbo ayé yóò wá di Párádísè. Gbogbo èèyàn pátá yóò máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà láàárín ara wọn, títí kan àwọn ẹranko. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí.” (Aísáyà 11:6, 9) “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ . . . Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.” (Aísáyà 33:24; 35:5) Kódà, àwọn òkú yóò jíǹde. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Dájúdájú, Jèhófà . . . yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn,” bẹ́ẹ̀ ni “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:4) Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé yóò wá ṣẹ. Àkókò ìdùnnú gbáà nìyẹn máa jẹ́ o!
Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Túbọ̀ Máa Pọ̀ Sí I
Irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run máa fi ìgbé ayé ìdùnnú nínú Párádísè san lẹ́san? Àwọn tó ní ìgbàgbọ́, ìyẹn ìgbàgbọ́ òdodo, ni o!
Má gbàgbé pé ìgbàgbọ́ òdodo dá lórí kéèyàn ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa Ìwé Mímọ́. Nítorí náà, túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti nípa Jésù kó o lè mọ̀ wọ́n dáadáa!
Ẹni tó ní ìgbàgbọ́ òdodo gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Bó o bá ń ṣe irú àwọn iṣẹ́ rere bẹ́ẹ̀, àwọn ìwà dáadáa tí Ọlọ́run ní yóò máa hàn nínú ìwà tìrẹ náà. Lára àwọn ìwà dáadáa tí Ọlọ́run ní ni pé ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, ó ní ọgbọ́n, ó ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó dára, ó sì ní ìfẹ́. Máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ní àwọn ìwà dáadáa wọ̀nyí.
Tó o bá ní ìgbàgbọ́ òdodo, èrè púpọ̀ ń bẹ fún ọ. Àní sẹ́, ìgbàgbọ́ òdodo ló máa mú kí o ní ayọ̀ láyé ìsinsìnyí àti títí ayérayé!