APA 8
Mèsáyà Dé
LẸ́YÌN ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún tí Dáníẹ́lì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, áńgẹ́lì tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì fara han wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà (Mọriamọ), tó jẹ́ ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba. Áńgẹ́lì yìí kí Màríà pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” (Lúùkù 1:28) Àmọ́, ẹ̀rù ba Màríà. Kí nìdí tí áńgẹ́lì yìí fi kí i bẹ́ẹ̀?
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣàlàyé fún Màríà pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, nítorí ìwọ ti rí ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run; sì wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. . . . Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un . . . kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:30-33) Ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ o! Ìyẹn ni pé Màríà máa bí Mèsáyà, tó jẹ́ “irú-ọmọ” tí wọ́n ti ń retí tipẹ́!
Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, Màríà bí Jésù ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ní òru ọjọ́ tó bí i, áńgẹ́lì kan sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà ní ìtòsí ibẹ̀ pé: “Wò ó! Èmi ń polongo fún yín ìhìn rere ti ìdùnnú ńlá kan . . . nítorí pé a bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa, ní ìlú ńlá Dáfídì.” (Lúùkù 2:10, 11) Nígbà tó yá, Jésù àti àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Násárétì, ibẹ̀ sì ni Jésù dàgbà sí.
Ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò dé, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ wòlíì, ó ń jíṣẹ́ Ọlọ́run. Jésù jẹ́ “ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún” nígbà yẹn. (Lúùkù 3:23) Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán an wá. Wọ́n sọ pé: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa.” (Lúùkù 7:16, 17) Àmọ́, kí ni Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn?
Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa jọ́sìn Ọlọ́run: Ó sọ ọ́ gbangba pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo, kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:29, 30) Ó tún sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”—Lúùkù 4:8.
Jésù sọ̀rọ̀ ìṣítí fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n fẹ́ràn ọmọnìkejì wọn: Ó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Máàkù 12:31) Ó sì tún sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn; ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.”—Mátíù 7:12.
Jésù máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà: Ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run . . . nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tó wà ní ọ̀run àmọ́ tí yóò máa ṣàkóso ayé. Jésù tó jẹ́ Mèsáyà ni Ọlọ́run fi jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run yìí. Tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti mú kí wòlíì Dáníẹ́lì rí i lójú ìran pé ní ọ̀run, Ọlọ́run fún Mèsáyà yìí ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” (Dáníẹ́lì 7:14) Ìjọba Ọlọ́run yìí ni yóò sọ gbogbo ayé di Párádísè, yóò sì fi ìyè ayérayé san àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́san. O ò rí i pé kò sí ìròyìn ayọ̀ tí ó tó èyí!