Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 21

Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò

Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì

1, 2. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Ọba wa ti ń ṣàkóso láti ọdún 1914? (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú orí yìí?

ÀWỌN ohun tá a ti sọ̀rọ̀ lé lórí pé Ìjọba Ọlọ́run ti gbé ṣe láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lágbára gan-an ni. (Sm. 110:2) Ọba wa ti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn oníwàásù tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú jọ. Ó ti fọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́, ó sì ti yọ́ wọn mọ́ nípa tẹ̀mí àti nínú ìwà wọn. Pẹ̀lú gbogbo ìsapá àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run láti pín wa yẹ́lẹyẹ̀lẹ, a ń gbádùn ìṣọ̀kan kárí ayé lóde òní. Àṣeyọrí yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tí Ìjọba náà ṣe tá a ti gbé yẹ̀ wò jẹ́ ẹ̀rí ńláǹlà tó fi hàn pé Ọba wa ti ń ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá Ìjọba náà láti ọdún 1914.

2 Ìjọba náà yóò tiẹ̀ tún ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó yani lẹ́nu jù bẹ́ẹ̀ lọ láìpẹ́ yìí. Ìjọba náà yóò “dé” láti “fọ́” àwọn ọ̀tá rẹ̀ “túútúú,” “yóò sì fi òpin” sí wọn. (Mát. 6:10; Dán. 2:44) Ṣùgbọ́n kó tó dìgbà yẹn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì míì yóò wáyé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn? Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ló dáhùn ìbéèrè yìí. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ká lè mọ àwọn ohun tó ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Tí “Ìparun Òjijì” Yóò sì Dé

3. Ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò kọ́kọ́ wáyé wo là ń retí?

3 Ìkéde àlàáfíà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn ará Tẹsalóníkà, ó sọ àkọ́kọ́ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí à ń retí náà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.) Nínú lẹ́tà yìí, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan “ọjọ́ Jèhófà,” èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá gbéjà ko “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 17:5) Àmọ́, ní gẹ́rẹ́ ṣáájú kí ọjọ́ Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” Gbólóhùn yìí lè jẹ́ ìkéde kan ṣoṣo tàbí kó jẹ́ àwọn gbólóhùn tó gbàfiyèsí tí yóò má wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ṣé àwọn olórí ẹ̀sìn máa kópa níbẹ̀? Nígbà tó jẹ́ pé apá kan ayé làwọn náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn náà máa bá àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” (Jer. 6:14; 23:16, 17; Ìṣí. 17:1, 2) Ńṣe ni ìkéde àlàáfíà àti ààbò yìí yóò jẹ́ ẹ̀rí pé ọjọ́ Jèhófà ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run kò sì ní “yèbọ́ lọ́nàkọnà.”

4. Kí ni àǹfààní tó wà nínú bá a ṣe lóye àsọtẹ́lẹ̀ Pọ́ọ̀lù nípa ìkéde àlàáfíà àti ààbò?

4 Kí wá ni àǹfààní tó wà nínú bá a ṣe lóye àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìkéde àlàáfíà àti ààbò? Pọ́ọ̀lù sọ ọ́, ó ní: “Ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè.” (1 Tẹs. 5:3, 4) Àwa Kristẹni tòótọ́ kò dà bí àwọn tó kù nínú ayé. À ń fòye mọ bí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ti ṣe pàtàkì tó. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àlàáfíà àti ààbò tí wọ́n á máa sọ yìí ṣe máa ṣẹ ní pàtó? Ṣe ni ká ṣì ní sùúrù o, ká máa wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—1 Tẹs. 5:6; Sef. 3:8.

Ìpọ́njú Ńlá Bẹ̀rẹ̀

5. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ “ìpọ́njú ńlá”?

5 Wọ́n gbéjà ko ìsìn. Rántí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Bí àrá ṣe ń sán tẹ̀ lé mànàmáná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìparun òjijì” yóò ṣe dé lọ́gán tí wọ́n bá ti ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” Kí ló máa pa run? Àkọ́kọ́ ni “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tá a tún mọ̀ sí “aṣẹ́wó náà.” (Ìṣí. 17:5, 6, 15) Ìparun àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo ètò ẹ̀sìn èké yòókù yìí ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ “ìpọ́njú ńlá.” (Mát. 24:21; 2 Tẹs. 2:8) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yóò bá ọ̀pọ̀ èèyàn lójijì. Kí nìdí? Ìdí ni pé títí di àkókò yẹn, ńṣe ni aṣẹ́wó náà á máa wo ara rẹ̀ bí “ọbabìnrin” tí ‘kì yóò rí ọ̀fọ̀ láé.’ Àmọ́, òjijì ló máa rí i pé ọ̀nà kò gba ibi tí òun fojú sí rárá. Ńṣe ni wọ́n máa pa á run kíákíá, bíi pé “ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”—Ìṣí. 18:7, 8.

6. Ta ni yóò gbéjà ko “Bábílónì Ńlá” tàbí kí ló máa gbéjà kò ó?

6 Ta ni yóò gbéjà ko “Bábílónì Ńlá” tàbí kí ló máa gbéjà kò ó? “Ẹranko ẹhànnà” kan tó ní “ìwo mẹ́wàá” ni. Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé ẹranko ẹhànnà náà dúró fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (àjọ UN). “Ìwo mẹ́wàá” náà dúró fún gbogbo ìjọba ayé tó ń ti “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” yìí lẹ́yìn ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.” (Ìṣí. 17:3, 5, 11, 12) Báwo ni ìgbéjàkò yìí ṣe máa burú tó? Ṣe ni àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè máa fipá gba gbogbo dúkìá aṣẹ́wó yìí, wọ́n á jẹ ẹ́ run, wọ́n á sì “fi iná sun ún pátápátá.”—Ka Ìṣípayá 17:16. *

7. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Mátíù 24:21, 22 ṣe ṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni? Báwo ni yóò ṣe ṣẹ lọ́jọ́ iwájú?

7 Bí a ó ṣe ké àwọn ọjọ́ náà kúrú. Ọba wa sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn gan-an nígbà ìpọ́njú ńlá. Jésù sọ pé: “Ní tìtorí àwọn àyànfẹ́, a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Ka Mátíù 24:21, 22.) Ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ ráńpẹ́ lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà “ké” àkókò tí àwọn ọmọ ogun Róòmù fi gbéjà kò Jerúsálẹ́mù “kúrú.” (Máàkù 13:20) Ìyẹn ló jẹ́ kí a lè gba àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà là. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ kárí ayé nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀? Jèhófà yóò lo Ọba wa láti “ké” àkókò tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè fi máa gbéjà ko ìsìn “kúrú,” kí wọ́n má bàa pa ìsìn tòótọ́ run pọ̀ mọ́ ìsìn èké. Torí náà, nígbà tí wọ́n bá pa gbogbo ètò ìsìn èké run pátá, ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà yóò là á já. (Sm. 96:5) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé lẹ́yìn tí apá yìí nínú ìpọ́njú ńlá bá ti parí.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Máa Yọrí sí Amágẹ́dọ́nì

8, 9. Àwọn ohun àrà mériyìírí wo ló lè jẹ́ pé Jésù ń tọ́ka sí? Kí ni àwọn èèyàn máa ṣe nípa ohun tí wọ́n rí?

8 Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì mélòó kan máa wáyé láàárín àkókò tó máa parí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù àti Lúùkù mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Ka Mátíù 24:29-31; Máàkù 13:23-27; Lúùkù 21:25-28.

9 Àwọn ohun àrà mérìíyìírí lójú ọ̀run. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run.” Ó dájú pé àwọn èèyàn kò ní lọ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn mọ́, torí wọn kò ní ka àwọn aṣáájú ìsìn sí ìmọ́lẹ̀ mọ́. Ṣé ohun tí Jésù sì tún ń sọ ni pé àwọn nǹkan àràmàǹdà á máa ṣẹlẹ̀ látojú ọ̀run? Bóyá ohun tó ń sọ náà nìyẹn. (Aísá. 13:9-11; Jóẹ́lì 2:1, 30, 31) Kí làwọn èèyàn máa ṣe nípa ohun tí wọ́n rí? Ńṣe ni wọn yóò wà nínú “làásìgbò” torí pé wọn kò mọ “ọ̀nà àbájáde.” (Lúùkù 21:25; Sef. 1:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run, látorí àwọn ọba wọn tó fi dórí àwọn ẹrú wọn ni yóò “kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá,” wọ́n á sì sáré láti wá ibi fara pa mọ́ sí. Síbẹ̀, wọn ò ní ríbi ààbò kankan fi ara wọn pa mọ́ sí tí wọ́n á fi lè bọ́ lọ́wọ́ ìrunú Ọba wa.—Lúùkù 21:26; 23:30; Ìṣí. 6:15-17.

10. Ìdájọ́ wo ni Jésù máa ṣe? Kí ni àwọn alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe tí wọ́n bá gba ìdájọ́, kí ni àwọn alátakò Ìjọba náà yóò sì ṣe?

10 Ṣíṣe ìdájọ́. Gbogbo ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run pátá yóò wá fi tipátipá rí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa pa kún ìrora gógó wọn. Jésù sọ pé: “Wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Máàkù 13:26) Bí Jésù yóò ṣe fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tó ju ti ẹ̀dá lọ yìí yóò jẹ́ àmì pé ó ti dé láti ṣe ìdájọ́. Ní apá míì nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí kan náà tí Jésù sọ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan sí i nípa ìdájọ́ tó máa ṣe lákòókò náà. Inú àkàwé rẹ̀ nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ la ti rí èyí. (Ka Mátíù 25:31-33, 46.) Àwọn adúróṣinṣin alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run yóò gba ìdájọ́ pé wọ́n jẹ́ “àgùntàn,” wọ́n yóò sì “gbé orí [wọn] sókè,” torí wọ́n mọ̀ pé “ìdáǹdè [àwọn] ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Àmọ́, àwọn alátakò Ìjọba náà yóò gba ìdájọ́ pé wọ́n jẹ́ “ewúrẹ́,” wọ́n yóò sì “lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn,” torí wọ́n rí i pé “ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ló máa bá àwọn.—Mát. 24:30; Ìṣí. 1:7.

11. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bí a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ láìpẹ́?

11 Lẹ́yìn tí Jésù bá ṣèdájọ́ “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì mélòó kan ṣì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. (Mát. 25:32) A máa sọ̀rọ̀ nípa méjì lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Àkọ́kọ́: Gọ́ọ̀gù yóò gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìkejì sì ni pé a ó kó àwọn ẹni àmì òróró jọ. Bí a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ àkókò pàtó tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé. Kódà, ó jọ pé déwọ̀n àyè kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan máa dé bá ìkejì bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́.

12. Ìgbéjàkò wo ni Sátánì yóò fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe sí Ìjọba náà?

12 Ó fi gbogbo agbára gbéjà kò wọ́n. Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yóò gbéjà ko àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:2, 11.) Bí Sátánì ṣe gbéjà ko Ìjọba Ọlọ́run tí ìṣàkóso rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ yìí, ìyẹn ni yóò jẹ́ ìkẹyìn nínú ogun tó ti ń bá àwọn ẹni àmì òróró jà látìgbà tí a ti lé e jáde kúrò lọ́run. (Ìṣí. 12:7-9, 17) Ní pàtàkì, láti ìgbà tí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹni àmì òróró jọ pọ̀ sínú ìjọ Kristẹni tó mú pa dà bọ̀ sípò ni Sátánì ti ń gbìyànjú láti ba aásìkí wọn nípa tẹ̀mí jẹ́, ìyẹn ìṣọ̀kan, ìfẹ́ ará kárí ayé àti ìjìnlẹ̀ òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Ọlọ́run fi ń jíǹkí wọn àti bí iye àwọn tó ń sìn Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n pàbó ni ìsapá rẹ̀ ń já sí. (Mát. 13:30) Àmọ́, nígbà tí gbogbo ètò ìsìn èké pátá bá ti pa rẹ́, tó sì dà bíi pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbé “láìsí ògiri, tí wọn kò sì ní ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn,” Sátánì yóò fẹ́ lo ohun tó rí bí àǹfààní ńlá yẹn. Ó máa sún àwọn olubi ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ kí wọ́n wá fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwọn alátìlẹyìn Ìjọba náà.

13. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀?

13 Ìsíkíẹ́lì wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa Gọ́ọ̀gù ni pé: “Ìwọ yóò sì wá láti àyè rẹ, láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn gun ẹṣin, ìjọ ńlá, àní ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ níye. Ó dájú pé ìwọ yóò gòkè wá gbéjà ko àwọn ènìyàn mi . . . bí àwọsánmà láti bo ilẹ̀ náà.” (Ìsík. 38:15, 16) Kí ni Jèhófà máa ṣe nípa ìgbéjàkò Sátánì tó dà bíi pé kò sẹ́ni tó lè dá a dúró yìí? Jèhófà sọ pé: “Ìhónú mi yóò gòkè wá.” Ó sì ní: “Èmi yóò sì pe idà kan jáde.” (Ìsík. 38:18, 21; ka Sekaráyà 2:8.) Jèhófà yóò dá sí ọ̀rọ̀ náà láti gbèjà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà láyé. Ogun Amágẹ́dọ́nì sì ni yóò fi dá sí ọ̀rọ̀ náà.

14, 15. Ìṣẹ̀lẹ̀ míì wo ni yóò wáyé lákòókò kan láàárín ìgbà tí Sátánì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo agbára rẹ̀ gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?

14 Ká tó tẹ̀ síwájú láti wo bí Jèhófà yóò ṣe gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ẹ jẹ́ ká sáré wo ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì míì ná. Èyí yóò wáyé lákòókò kan láàárín ìgbà tí Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run àti ìgbà tí Jèhófà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í dá sí ọ̀rọ̀ náà ní Amágẹ́dọ́nì. Bí a ṣe sọ ní ìpínrọ̀ kọkànlá, ìṣẹ̀lẹ̀ kejì yìí ni kíkó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró jọ.

15 Kíkó àwọn ẹni àmì òróró jọ. Mátíù àti Máàkù kọ ohun tí Jésù sọ nípa “àwọn àyànfẹ́,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, mọ́ ara ọ̀wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé ṣáájú kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ́ sílẹ̀. (Wo ìpínrọ̀ 7.) Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó tọ́ka sì ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó ní: “Nígbà náà ni òun yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì jáde, yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀ ayé títí dé ìkángun ọ̀run.” (Máàkù 13:27; Mát. 24:31) Ìkójọpọ̀ wo ni Jésù ń sọ níbí? Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fífi èdìdì ìkẹyìn di àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jésù ń sọ, torí ìyẹn yóò ti wáyé ní gẹ́rẹ́ ṣáájú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 7:1-3) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa wáyé nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ ni Jésù ń tọ́ka sí. Nítorí náà, ó jọ pé lákòókò kan lẹ́yìn tí Sátánì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo agbára rẹ̀ gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, a ó kó àwọn ẹni àmì òróró tó bá ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé lọ sí ọ̀run.

16. Ipa wo ni àwọn ẹni àmì òróró tá a jí dìde yóò kó nínú ogun Amágẹ́dọ́nì?

16 Ṣé ìkójọpọ̀ àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù yìí yóò parí kó tó kan ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé tẹ̀ lé e, ìyẹn Amágẹ́dọ́nì? Àkókò tí ìkójọpọ̀ wọn yìí yóò wáyé fi hàn pé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró yóò ti wà lọ́run ṣáájú kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. Ní ọ̀run, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá Kristi jọba yóò gba àṣẹ láti bá Jésù kópa nínú lílo “ọ̀pá irin” láti fi pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run run pátá. (Ìṣí. 2:26, 27) Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì alágbára àti àwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde sọ́run yóò tẹ̀ lé Kristi Ọba Ajagunṣẹ́gun, bó ṣe gbéra láti dojú ìjà kọ “ẹgbẹ́ ológun” àwọn ọ̀tá “tí ó pọ̀ níye,” tí wọ́n ti fẹ́ ya bo àwọn èèyàn Jèhófà, láti pa wọ́n rẹ́. (Ìsík. 38:15) Tí Kristi bá ti dojú ìjà kọ wọ́n, ogun Amágẹ́dọ́nì ń jà lọ nìyẹn!—Ìṣí. 16:16.

Bí Ìpọ́njú Ńlá Ṣe Parí Pátápátá

Ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀!

17. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “àwọn ewúrẹ́” nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì?

17 Mímú ìdájọ́ ṣẹ. Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa parí ìpọ́njú ńlá pátápátá. Ní àkókò yẹn, Jésù yóò tún ṣe àfikún iṣẹ́ kan. Yàtọ̀ sí pé ó máa jẹ́ Onídàájọ́ “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” yóò tún di Amúdàájọ́ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn gbogbo èèyàn tó ti ṣèdájọ́ fún níṣàájú pé wọ́n jẹ́ “ewúrẹ́.” (Mát. 25:32, 33) Ọba wa yóò fi “idà gígùn mímú . . . ṣá àwọn orílẹ̀-èdè.” Láìsí àní-àní, gbogbo àwọn ẹni bí ewúrẹ́, látorí “àwọn ọba” títí dórí àwọn “ẹrú” ni “yóò . . . lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.”—Ìṣí. 19:15, 18; Mát. 25:46.

18. (a) Báwo ni nǹkan ṣe máa yí pa dà fáwọn “àgùntàn”? (b) Báwo ni Jésù yóò ṣe parí ìṣẹ́gun rẹ̀?

18 Ẹ ò rí bí nǹkan ṣe máa wá yí pa dà fáwọn tí Jésù kà sí “àgùntàn”! Kàkà tí ẹgbẹ́ ológun tó pọ̀ níye ti “àwọn ewúrẹ́” tó jẹ́ ti Sátánì yóò fi rí “àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó dà bí “àwọn àgùntàn” tí kò lè dáàbò bo ara wọn pa rẹ́, ṣe ni wọn yóò la ìgbéjàkò ọ̀tá yẹn já, wọn yóò sì “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” (Ìṣí. 7:9, 14) Nígbà náà, lẹ́yìn tí Jésù bá ti ṣẹ́gun, tó sì ti mú gbogbo èèyàn tó jẹ́ ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run kúrò, yóò wá ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ pátá sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Wọ́n á wà níbẹ̀ bí aláìsí, bíi pé wọ́n kú, tí wọn ò ní lè ta pútú fún ẹgbẹ̀rún ọdún.—Ka Ìṣípayá 6:2; 20:1-3.

Bí A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀

19, 20. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó wà ní Aísáyà 26:20 àti Aísáyà 30:21?

19 Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani lẹ́rù tí yóò wáyé yìí? Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn pé: “Lílàájá [wa] yóò sinmi lé ìgbọràn” wa. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? A rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ìgbàanì. Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun Bábílónì, àmọ́ kí ni kí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe láti múra ara wọn sílẹ̀ de ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Jèhófà sọ pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” (Aísá. 26:20) Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe inú gbólóhùn náà. Àwọn ni: “lọ,” “wọnú,” “ti,” “fi . . . pa mọ́,” gbogbo wọn ló jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a fi pàṣẹ; àṣẹ ni wọ́n jẹ́. Àwọn Júù tó ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ yìí á jókòó sílé wọn, láì yọjú sí àwọn ọmọ ogun ajagunṣẹ́gun tó wà nígboro. Torí náà, lílàájá wọn sinmi lé ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Jèhófà. *

20 Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Bíi tàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé ìgbàanì, lílàájá wa nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ bá wáyé yóò sinmi lórí ìgbọràn wa sí àwọn ìtọ́ni Jèhófà. (Aísá. 30:21) À ń rí àwọn ìtọ́ni yìí gbà nípasẹ̀ ìjọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣègbọràn látọkàn wá sí àwọn ìtọ́ni tí à ń rí gbà. (1 Jòh. 5:3) Tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, a ó ní máa lọ́ra láti ṣègbọràn tinútinú lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn á sì jẹ́ kí Jèhófà Baba wa ọ̀run, àti Jésù, Ọba wa dáàbò bò wá. (Sef. 2:3) Ààbò Ọlọ́run yìí yóò jẹ́ ká lè wà lára àwọn tó máa rí bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ kúrò pátápátá. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé nìyẹn á mà jẹ́ o!

^ ìpínrọ̀ 6 Ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ìparun àwọn ètò ẹ̀sìn nìkan ni ìparun “Bábílónì Ńlá” jẹ́ ní pàtàkì, kì í ṣe pé wọ́n máa pa gbogbo àwọn èèyàn tó ń ṣe ẹ̀sìn wọ̀nyẹn. Torí náà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá tẹ́lẹ̀ ni yóò la ìparun yẹn, ó sì jọ pé, ó kéré tán wọ́n á fi hàn ní gbangba pé àwọn kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìsìn, bí a ṣe rí i ní Sekaráyà 13:4-6.