Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 8

Àwọn Ohun Èlò Iṣẹ́ Ìwàásù​—À Ń Tẹ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ fún Lílò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé

Àwọn Ohun Èlò Iṣẹ́ Ìwàásù​—À Ń Tẹ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ fún Lílò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Jèhófà ń bá a nìṣó láti pèsè àwọn ohun èlò tí a ó máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ahọ́n

1, 2. (a) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n fi lè tàn ìhìn rere ká gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù pátá? (b) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn ní àkókò wa yìí? (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “ Ìhìn Rere Lédè Tó Ju Ẹgbẹ̀ta Lé Àádọ́rin.”)

OHUN tí àwọn àlejò kan tó wá sí Jerúsálẹ́mù láti ilẹ̀ òkèèrè nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ń gbọ́ yìí yà wọ́n lẹ́nu gidigidi. Àwọn ará Gálílì ń sọ àwọn èdè ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà tó yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu, ó sì jẹ́ èdè àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn yìí. Ohun tí wọ́n ń sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Ẹ̀mí mímọ́ ló mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn náà lè sọ̀rọ̀ ní onírúurú èdè lọ́nà ìyanu, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn wọn. (Ka Ìṣe 2:1-8, 12, 15-17.) Ìhìn rere tí wọ́n wàásù wẹ́rẹ́ lọ́jọ́ yẹn dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn lóríṣiríṣi ibi káàkiri, lẹ́yìn náà ó sì tàn dé gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù pátá.—Kól. 1:23.

2 Lónìí, ẹ̀mí mímọ́ kì í mú kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sọ onírúurú èdè lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, wọ́n ń mú kí ìhìn rere tàn kálẹ̀ ní èdè tó ju ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ fíìfíì, torí pé wọ́n ń túmọ̀ ìhìn rere Ìjọba náà sí èdè tó lé ní àádọ́rin lé lẹ́gbẹ̀ta [670]. (Ìṣe 2:9-11) Àwọn ìtẹ̀jáde tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, wọ́n sì wà ní èdè tó pọ̀ gàn-an débi pé ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ti dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. * Èyí náà tún jẹ́ ẹ̀rí tó dájú gan-an, pé Jèhófà ń lo Jésù Kristi Ọba láti darí iṣẹ́ ìwàásù wa. (Mát. 28:19, 20) A fẹ́ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun èlò tí a ti fi ń ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí bọ̀ láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí. Bí a ṣe ń ṣàyẹ̀wò yìí, máa kíyè sí bí Ọba wa ṣe ti ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ká lè mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ olúkúlùkù èèyàn àti bó ṣe ti ń gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Tím. 2:2.

Ọba Fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Lóhun Èlò Tí Wọ́n Á Fi Fúnrúgbìn Òtítọ́

3. Kí nìdí tá a fi ń lò onírúurú ohun èlò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

3 Jésù fi ‘ọ̀rọ̀ Ìjọba náà’ wé irúgbìn, ó sì fi ọkàn èèyàn wé ilẹ̀. (Mát. 13:18, 19) Bí àgbẹ̀ kan ṣe lè lo onírúurú ohun èlò láti fi túlẹ̀ kó tó gbin irúgbìn sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn Jèhófà ṣe ti lo onírúurú ohun èlò tí wọ́n fi ń múra ọkàn ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sílẹ̀ kí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà lè dúró níbẹ̀. Ìgbà díẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ohun èlò náà kàn wúlò mọ. Àmọ́ àwọn míì, bí ìwé àti ìwé ìròyìn ṣì ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu. Gbogbo ohun èlò tí a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní orí yìí yàtọ̀ sí àwọn ọ̀nà tí a gbà ń mú ìsọfúnni dé ọ̀dọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tá a sọ ní orí keje ìwé yìí, torí pé ṣe ni àwọn ohun èlò tí a ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní orí yìí ń jẹ́ kí àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú.—Ìṣe 5:42; 17:2, 3.

Wọ́n ń ṣe ẹ̀rọ giramafóònù àti ẹ̀rọ gbohùngbohùn, ní Toronto, ilẹ̀ Kánádà

4, 5. Báwo ni wọ́n ṣe lo ẹ̀rọ giramafóònù, ṣùgbọ́n kí ni kò lè ṣe?

4 Àsọyé tí a gbà sórí àwo. Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1949, àwọn akéde máa ń fi ẹ̀rọ giramafóònù gbé àwọn àsọyé Bíbélì tí a ṣe sórí àwo sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn. Kì í tó ìṣẹ́jú márùn-ún kí àwo àsọyé kọ̀ọ̀kan tó parí. Nígbà míì, wọ́n máa ń kọ àkọlé pélébé kan sára àwo náà, irú bíi “Mẹ́talọ́kan,” “Pọ́gátórì” àti “Ìjọba.” Báwo ni wọ́n ṣe ń lo àwo wọ̀nyẹn? Arákùnrin Clayton Woodworth Kékeré, tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1930 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo máa ń gbé ẹ̀rọ giramafóònù tó rí mọ́ńbé bí àpò kékeré dání. Tí a bá fẹ́ lò ó, ṣe ni a máa yí okùn rẹ̀ bírí-bírí láti fún un lókùn bí aago olókùn, kó lè ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣe ọwọ́ abẹ́rẹ́ rẹ̀ lọ́tọ̀ ni, mo sì ní láti gbé e síbi tó yẹ gẹ́lẹ́ létí àwo náà kó tó lè gbóhùn jáde dáadáa. Tí mo bá ti dé ẹnu ọ̀nà ilé kan, màá ṣí àpótí ẹ̀rọ giramafóònù náà, màá gbé ọwọ́ abẹ́rẹ́ rẹ̀ síbi tó tọ́ gẹ́lẹ́ létí àwo náà, màá wá tẹ aago ẹnu ìlẹ̀kùn. Tí onílé bá ti ṣílẹ̀kùn, màá sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà tí mo fẹ́ kẹ́ ẹ gbọ́.’” Kí wá làwọn onílé máa ń ṣe? Arákùnrin Woodworth sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà onílé máa ń tẹ́tí gbọ́ wa dáadáa. Láwọn ìgbà míì, ṣe làwọn èèyàn á kàn tún pa ilẹ̀kùn wọn dé. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn míì máa ń rò pé ẹ̀rọ giramafóònù ni mò ń tà.”

Nígbà tó fi máa di ọdún 1940, oríṣiríṣi àwo àsọyé tó wà ti ju àádọ́rùn-ún [90] lọ, ètò Ọlọ́run sì ti ṣe àwo tó ju mílíọ̀nù kan lọ jáde

5 Nígbà tó fi máa di ọdún 1940, oríṣiríṣi àwo àsọyé tó wà ti ju àádọ́rùn-ún [90] lọ, ètò Ọlọ́run sì ti ṣe àwo tó ju mílíọ̀nù kan lọ jáde. Arákùnrin John E. Barr, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn, tó sì wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, sọ pé: “Láàárín ọdún 1936 sí 1945, tèmi ti ẹ̀rọ giramafóònù ni mo ń rìn. Láyé ìgbà yẹn, tí mi ò bá rí ẹ̀rọ giramafóònù gbé dání, ọkàn mi kì í balẹ̀ rárá. Ìṣírí gidi ló máa ń jẹ́ fún mi láti gbọ́ ohùn Arákùnrin Rutherford tí mo bá wà lẹ́nu ọ̀nà àwọn onílé; ṣe ló máa ń dà bíi pé òun fúnra rẹ̀ gan-an wà níbẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tó bá kan tí kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lóde ẹ̀rí, ẹ̀rọ giramafóònù kò lè ṣe ìyẹn, torí kò lè rí i dájú pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ dénú ọkàn àwọn èèyàn.”

6, 7. (a) Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú lílo káàdì ìjẹ́rìí? Kí ló fi hàn pé ó níbi tó wúlò mọ? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ọ̀rọ̀ sí wa lẹ́nu?

6 Káàdì ìjẹ́rìí. Láti ọdún 1933 ni wọ́n ti ń gba àwọn akéde níyànjú pé kí wọ́n máa lo káàdì ìjẹ́rìí tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Káàdì ìjẹ́rìí rí pélébé bíi bébà tí a fi ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa. Ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣókí àti àlàyé nípa ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí onílé lè rí gbà ló wà nínú rẹ̀. Ṣe ni akéde á kàn fún onílé ní káàdì náà pé kó kà á. Arábìnrin Lilian Kammerud tó ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Puerto Rico àti Ajẹntínà nígbà tó yá, sọ pé: “Mo fẹ́ràn lílo káàdì ìjẹ́rìí gan-an ni.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Gbogbo wa kọ́ ló mọ béèyàn ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí. Torí náà, lílo káàdì ìjẹ́rìí ló jẹ́ kó mọ́ mi lára láti máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí.”

Káàdì ìjẹ́rìí (ní èdè Italian)

7 Arákùnrin David Reusch, tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1918 sọ pé: “Káàdì ìjẹ́rìí ran àwọn ará lọ́wọ́ gan-an, torí àwọn díẹ̀ ló dá lójú pé wọ́n mọ bí wọ́n ṣe máa wàásù lóde ẹ̀rí.” Àmọ́ ó nibi tí káàdì náà wúlò mọ. Arákùnrin Reusch sọ pé “Nígbà míì, a máa ń rí àwọn èèyàn tó rò pé odi ni wá. Bíi pé ọ̀pọ̀ nínú wa kò lè sọ̀rọ̀ náà ló sì rí. Ṣùgbọ́n bí a ṣe ń lo káàdì yẹn, ṣe ni Jèhófà ń múra àwa òjíṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ká lè mọ bí a ó ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Kò pẹ́ sígbà náà ló fi ọ̀rọ̀ sí wa lẹ́nu ní ti pé ó kọ́ wa pé ká máa lo Ìwé Mímọ́ láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tí a bá ń wàásù láti ilé délé. Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1943 ló lò láti fi kọ́ wa.”—Ka Jeremáyà 1:6-9.

8. Báwo ni wàá ṣe jẹ́ kí Kristi dá ọ lẹ́kọ̀ọ́?

8 Ìwé. Láti ọdún 1914, àwa èèyàn Jèhófà ti ṣe oríṣiríṣi ìwé ńlá tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100], tó ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì nínú Bíbélì. A dìídì ṣe àwọn kan lára àwọn ìwé ńlá yìí ká lè fi dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè dí òjíṣẹ́ tó múná dóko. Arábìnrin Anna Larsen, ní ilẹ̀ Denmark, tó ti jẹ́ akéde láti nǹkan bí àádọ́rin [70] ọdún báyìí sọ pé: “Jèhófà fi Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìwé ilé ẹ̀kọ́ yẹn tí à ń lò, sọ wá di akéde tó gbó ṣáṣá. Mo rántí pé ọdún 1945 ni wọ́n tẹ ìwé Theocratic Aid to Kingdom Publishers [Ìrànlọ́wọ́ Ètò Ìjọba Ọlọ́run fún Àwọn Akéde Ìjọba], tá a kọ́kọ́ lò ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tẹ ìwé “Equipped for Every Good Work” [Mímúrasílẹ̀ fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo], jáde lọ́dún 1946. Ní báyìí, a ní ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, tá a tẹ̀ lọ́dún 2001.” Dájúdájú, Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìwé míì tí à ń lò nílé ẹ̀kọ́ náà ti kó ipa pàtàkì nínú bí Jèhófà ṣe mú wa “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn . . . láti jẹ́ òjíṣẹ́.” (2 Kọ́r. 3:5, 6) Ṣé ìwọ náà ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o máa ń mú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run dání lọ sípàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tí o sì ń fojú bá a lọ nínú ìwé tìrẹ bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ṣe ń tọ́ka sí i? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń jẹ́ kí Kristi dá ọ lẹ́kọ̀ọ́ kó o lè di olùkọ́ tó túbọ̀ jáfáfá.—2 Kọ́r. 9:6; 2 Tím. 2:15.

9, 10. Ipa wo ni ìwé kó nínú fífúnrúgbìn ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti bíbomi rin ín?

9 Jèhófà tún ti ràn wá lọ́wọ́ ní ti pé ó mú kí ètò rẹ̀ pèsè àwọn ìwé ńlá tó ń ran àwọn akéde lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàlàyé àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ní pàtàkì, ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, wúlò gan-an. Ọdún 1968 ní wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ ẹ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì jáde ní Yorùbá ní 1969. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì mọyì rẹ̀. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1968 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn tó fẹ́ gba ìwé Otitọ pọ̀ débi pé ní oṣù September, wọ́n ṣe àfikún iṣẹ́ alẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé Society ní Brooklyn.” Àpilẹ̀kọ yẹn ń bá a lọ pé: “Nígbà kan lóṣù August, iye ìwé Otitọ táwọn èèyàn fẹ́ gbà fi mílíọ̀nù kan àtààbọ̀ ju iye tá a ní lọ́wọ́ lọ!” Nígbà tó fi máa di ọdún 1982, ó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] mílíọ̀nù ẹ̀dà ìwé náà tí a ti tẹ̀ jáde ní èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116]. Láàárín ọdún 1968 sí 1982, ìyẹn ọdún mẹ́rìnlá, ìwé Otitọ ti jẹ́ kí àwọn tó ju mílíọ̀nù kan tún kún iye akéde Ìjọba Ọlọ́run tí a ní. *

10 Lọ́dún 2005, a tún mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àrà ọ̀tọ̀ míì jáde, ìyẹn Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? A ti tẹ nǹkan bí igba [200] mílíọ̀nù ẹ̀dà rẹ̀ jáde ní igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [256] èdè! Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Nǹkan bí mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá èèyàn ló di akéde láàárín ọdún méje péré, ìyẹn láti ọdún 2005 sí 2012. Láàárín àkókò yìí kan náà, iye èèyàn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti pọ̀ sí i láti nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́fà tẹ́lẹ̀, sí èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án báyìí. Ó dájú pé Jèhófà ń bù kún ìsapá wa láti gbìn àti láti bomi rin irúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà.—Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.

11, 12. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, onírúurú èèyàn wo la dìídì ṣe àwọn ìwé ìròyìn wa fún?

11 Ìwé ìròyìn. Ní ìbẹ̀rẹ̀, torí àwọn “agbo kékeré” tó ní “ìpè ti ọ̀run” ni wọ́n ṣe dìídì ń ṣe Ilé Ìṣọ́. (Lúùkù 12:32; Héb. 3:1) Ní October 1, 1919, ètò Jèhófà mú ìwé ìròyìn míì jáde, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà tí yóò máa wu àwọn ará ìta láti kà. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ará ìta fẹ́ràn ìwé ìròyìn náà gan-an débi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé, iye ẹ̀dà rẹ̀ tí à ń tẹ̀ jáde lẹ́ẹ̀kan pọ̀ ju ti Ilé Ìṣọ́ lọ fíìfíì. The Golden Age la kọ́kọ́ pe orúkọ ìwé ìròyìn yẹn. Lọ́dún 1937, a yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Consolation. Nígbà tó di ọdún 1946, a wá pè é ní Awake!, ìyẹn Jí! lédè Yorùbá.

12 Láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yẹn wá, ìrísí Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àti ọ̀nà tí a gbà ń gbé e jáde ń yí pa dà, ṣùgbọ́n ète tí a fi ń kọ wọ́n kò yí pa dà. Ète yẹn sì ni pé ká fi máa kéde Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa fi mú kí àwọn èèyàn gba Bíbélì gbọ́. Lónìí, à ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ẹ̀dà tí a máa ń fi sóde. “Àwọn ará ilé,” ìyẹn “agbo kékeré” àti “àwọn àgùntàn mìíràn,” * la dìídì ń ṣe ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ fún. (Mát. 24:45; Jòh. 10:16) Ní pàtàkì, àwọn tí kò tíì mọ òtítọ́ àmọ́ tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì àti Ọlọ́run la dìídì ń kọ ẹ̀dà tí a máa ń fi sóde fún. (Ìṣe 13:16) Àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì àti Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ ni à ń ṣe Jí! fún ní pàtàkì.—Ìṣe 17:22, 23.

13. Kí ló wú ọ lórí nípa àwọn ìwé ìròyìn wa? (Jíròrò àtẹ ìsọfúnni tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “ Àtẹ Àwọn Ìwé Tí Wọ́n Ń Tẹ̀ Jáde Jù Láyé.”)

13 Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2014, ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì [44] ẹ̀dà Jí! àti nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ni à ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù. À ń túmọ̀ Jí! sí èdè tó tó ọgọ́rùn-ún [100], a sì ń túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí èdè tó ju igba [200] lọ, tó fi jẹ́ pé ìwé ìròyìn méjèèjì yìí ni ìwé ìròyìn tí wọ́n ń túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù tí wọ́n sì ń pín kiri jù nínú àwọn ìwé ìròyìn tó wà láyé! Àmọ́ kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé a ṣe àṣeyọrí tó pabanbarì wọ̀nyí. Ṣebí ìhìn tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé náà ló wà nínú àwọn ìwé ìròyìn yìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—Mát. 24:14.

14. Kí ni à ń fìtara ṣe, kí sì nìdí?

14 Bíbélì. Ní ọdún 1896, Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ yí orúkọ àjọ tí wọ́n ń lò láti fi tẹ àwọn ìtẹ̀jáde wa pa dà láti lè fi ọ̀rọ̀ náà Bíbélì kún orúkọ náà. Wọ́n wá ń pe orúkọ àjọ náà ní Watch Tower Bible and Tract Society. Orúkọ tí wọ́n yí i pa dà sí yẹn bá a mu gan-an torí pé Bíbélì náà ni olórí ohun tí wọ́n kúkú ń lò láti fi tan ìhìn rere nípa Ìjọba náà kálẹ̀. (Lúùkù 24:27) Orúkọ tí àjọ wa ń jẹ́ lábẹ́ òfin yìí sì ro àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, torí ṣe ni à ń fìtara kópa nínú pínpín Bíbélì kiri àti rírọ àwọn èèyàn kí wọ́n máa kà á. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1926, a fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tiwa tẹ Bíbélì Emphatic Diaglott, tó jẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì láti ọwọ́ Benjamin Wilson. Láti 1942 wá, a ti tẹ nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000] Bíbélì King James Version lódindi, a sì pín in kiri. Ní ọdún méjì péré lẹ́yìn 1942, a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì American Standard Version, tí ó lo orúkọ Jèhófà ní ibi ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́tàlélógún [6,823]. Nígbà tó fi máa di 1950, a ti pín ohun tó lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] ẹ̀dà rẹ̀ kiri.

15, 16. (a) Kí ló wù ọ́ jù nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun? (Jíròrò àpótí tó ní àkọlé náà, “ A Mú Kí Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Bíbélì Yára Kánkán.”) (b) Kí ni wàá ṣe kí Jèhófà lè máa darí ọkàn rẹ?

15 Ọdún 1950 la mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́dún 1961, a mú àpapọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì jáde ní Yorùbá ní 1997. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí bọlá fún Jèhófà ní ti pé ó dá orúkọ rẹ̀ pa dà sáwọn ibi tó wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì lédè Hébérù. Tá a bá ka iye ìgbà tí orúkọ Ọlọ́run tún fara hàn níbẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó jẹ́ òjìlérúgba ó dín mẹ́ta [237]. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti tún Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe láti lè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ péye, ó sì dùn-ún kà, èyí tí a sì ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí lédè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ lọ́dún 2013. Ìṣirò ti ọdún 2013 fi hàn pé ó ti ju mílíọ̀nù mọ́kànlénígba [201] ẹ̀dà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a ti tẹ̀ jáde lódindi tàbí ní apá kan ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́fà [121].

16 Báwo ló ṣe rí lára àwọn kan nígbà tí wọ́n ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè àbínibí wọn? Ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Nepal sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ló rí i pé Bíbélì tí wọ́n fi èdè ilẹ̀ Nepal àtijọ́ kọ kò yéni dáadáa, torí èdè ìwé tó yàtọ̀ sí èdè àjùmọ̀lò ni wọ́n fi kọ ọ́. Ṣùgbọ́n ní báyìí, Bíbélì ti wá ń yé wa dáadáa, torí èdè àjùmọ̀lò tí à ń sọ lójoojúmọ́ ni wọ́n fi túmọ̀ rẹ̀.” Nígbà tí obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Central African Republic bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì tí a túmọ̀ sí èdè Sango, ṣe ló ń da omijé lójú. Ó ní: “Èdè tó ń wọ̀ mí lọ́kàn gan-an nìyí.” Olúkúlùkù wa lè ṣe bí obìnrin yẹn, ká máa ka Ọ̀rọ̀ Jèhófà lójoojúmọ́ kí Jèhófà lè máa darí ọkàn wa.—Sm. 1:2; Mát. 22:36, 37.

A Dúpẹ́ fún Àwọn Ohun Èlò àti Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tí A Rí Gbà

17. Kí lo máa ṣe tí yóò fi hàn pé o mọyì àwọn ohun èlò tó o gbà àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o gbà? Kí ló máa yọrí sí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀?

17 Ǹjẹ́ o mọyì àwọn ohun èlò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ń tẹ̀ síwájú tí a rí gbà lọ́dọ̀ Jésù Kristi Ọba? Ǹjẹ́ o máa ń wáyè ka àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń mú jáde, ṣé o sì ń lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé wàá gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Arábìnrin Opal Betler tó ṣèrìbọmi ní October 4, 1914. Ó ní: “Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, èmi àti ọkọ mi [Edward], máa ń fi ẹ̀rọ giramafóònù àti káàdì ìjẹ́rìí wàásù. À ń fi àwọn ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn wàásù láti ilé dé ilé. A máa ń ṣe ìwàásù àkànṣe, à ń gbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro, a sì máa ń pín àṣàrò kúkúrú. Nígbà tó yá, wọ́n kọ́ wa pé ká máa lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Ọwọ́ wa máa ń dí dáadáa, a sì láyọ̀ gan-an.” Jésù ṣèlérí pé àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba òun yóò máa bá iṣẹ́ fífúnrúgbìn àti kíkórè lọ ní pẹrẹu, wọ́n á sì máa yọ̀ pa pọ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn bíi ti Opal ló máa gbà pé ìlérí yìí ń ṣẹ lóòótọ́.—Ka Jòhánù 4:35, 36.

18. Àǹfààní wo la ní?

18 Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò tíì di ìránṣẹ́ Ọba náà lè máa wo àwa èèyàn Ọlọ́run pé a jẹ́ “ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Àmọ́ ìwọ rò ó wò ná! Ọba wa ti mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ gbáàtúù yìí di àràbà nídìí ìwé títẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu, débi pé àwọn ìwé wọn jẹ́ ara àwọn ìwé tí wọ́n ń túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù tí wọ́n sì ń pín kiri jù láyé ńbí! Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ó ti dá wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti fún wa níṣìírí láti máa lo àwọn ohun èlò yìí láti máa fi tan ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa bá Kristi ṣiṣẹ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ fífúnrúgbìn ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti kíkórè àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọlé!

^ ìpínrọ̀ 2 Láàárín ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn nìkan, àwa èèyàn Jèhófà ti mú àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tó ju ogún bílíọ̀nù lọ jáde. Láfikún sí i, ní báyìí, ìkànnì wa jw.org, ti wà fún àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta tó ń lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kárí ayé.

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn ìwé ńlá míì tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó ti ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni Duru Ọlọrun (ọdún 1921 la tẹ̀ ẹ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì), Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ (ọdún 1946 la tẹ̀ ẹ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó jáde ní Yorùbá ní 1962), Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ọdún 1982 la tẹ̀ ẹ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó jáde ní Yorùbá ní 1983) àti Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun (ọdún 1995 la tẹ̀ ẹ́).