ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 2B
Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ayé Ìsíkíẹ́lì
Ìsíkíẹ́lì túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ló Ń Fúnni Lókun.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìkìlọ̀ pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lé lápapọ̀ bá ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mu, ó sì ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tó fẹ́ ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Ọlọ́run túbọ̀ lágbára.
ÀWỌN WÒLÍÌ TÍ WỌ́N JỌ GBÉ AYÉ
-
JEREMÁYÀ,
ìdílé àlùfáà ló ti wá, Jerúsálẹ́mù ló sì ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ (647 sí 580 Ṣ.S.K.)
-
HÚLÍDÀ,
ìgbà tí wọ́n rí ìwé Òfin nínú tẹ́ńpìlì ló ń ṣiṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn nǹkan bí ọdún 642 Ṣ.S.K.
-
DÁNÍẸ́LÌ,
ó wá látinú ẹ̀yà Júdà tó ń jọba, wọ́n mú un lọ sí Bábílónì lọ́dún 617 Ṣ.S.K.
-
HÁBÁKÚKÙ,
ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Júdà ló ti ṣiṣẹ́ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àkóso ọba Jèhóákímù
-
ỌBADÁYÀ,
ó kéde àsọtẹ́lẹ̀ sórí Édómù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run
ÌGBÀ WO NI WỌ́N SỌ ÀSỌTẸ́LẸ̀? (GBOGBO DÉÈTÌ JẸ́ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI)
ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ WÁYÉ NÍGBÀ AYÉ ÌSÍKÍẸ́LÌ (GBOGBO DÉÈTÌ JẸ́ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI)
-
n.643: Wọ́n bí Ìsíkíẹ́lì
-
617: Wọ́n mú un lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì
-
613: Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀; ó rí ìran látọ̀dọ̀ Jèhófà
-
612: Ó rí ìran àwọn apẹ̀yìndà nínú tẹ́ńpìlì
-
611: Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ìdájọ́ sórí Jerúsálẹ́mù
-
609: Ìyàwó rẹ̀ kú, wọ́n gbógun ìkẹyìn ti Jerúsálẹ́mù
-
607: Wọ́n sọ fún un pé Jerúsálẹ́mù ti pa run
-
593: Ó rí ìran nípa tẹ́ńpìlì
-
591: Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì máa gbógun ja Íjíbítì; ó kọ̀wé rẹ̀ tán
ÀWỌN ỌBA JÚDÀ ÀTI BÁBÍLÓNÌ
-
659 sí 629: Jòsáyà gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ àmọ́ ó kú sójú ogun nígbà tó lọ bá Fáráò Nékò jà
-
628: Jèhóáhásì ṣàkóso fún oṣù mẹ́ta, ìjọba rẹ̀ ò sì dáa rárá, Fáráò Nékò mú un nígbà tó yá
-
628 sí 618: Jèhóákímù kì í ṣe ọba rere, Fáráò Nékò mú un sábẹ́ àkóso rẹ̀
-
625: Nebukadinésárì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Íjíbítì
-
620: Nebukadinésárì gbógun ja Júdà fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sì fi Jèhóákímù sábẹ́ àkóso rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù
-
618: Jèhóákímù ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí àwọn ará Bábílónì gbógun ja Ilẹ̀ Ìlérí nígbà kejì ló kú
-
617: Jèhóákínì, tí wọ́n tún ń pè ní Jekonáyà, kì í ṣe ọba rere, oṣù mẹ́ta ló fi ṣàkóso, ó fi ara rẹ̀ sábẹ́ Nebukadinésárì nígbà tó yá
-
617 sí 607: Sedekáyà jẹ́ ọba tó burú, kò sì lè dá ìpinnu ṣe, Nebukadinésárì fi sábẹ́ àkóso rẹ̀ nígbà tó yá
-
609: Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì, torí náà Nebukadinésárì tún gbógun ja Júdà nígbà kẹta
-
607: Nebukadinésárì pa Jerúsálẹ́mù run, ó mú Sedekáyà, ó fọ́ ọ lójú, ó sì mú un lọ sí Bábílónì