Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 20A

Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Ọlọ́run ṣe nípa àwọn ààlà ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ ṣe pàtó fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n máa gba ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn pa dà. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìran yẹn lónìí? Ẹ jẹ́ ká gbé apá méjì lára ìran náà yẹ̀ wò:

Àyè àti iṣẹ́ tó ṣeyebíye

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó pa dà láti ìgbèkùn ló máa ní ogún tiẹ̀ nínú Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà ló rí lónìí, gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló ní àyè tiẹ̀ nínú párádísè tẹ̀mí. Bó ṣe wù kí ipa tá à ń kó rẹlẹ̀ tó nínú ètò Ọlọ́run, a ní àyè tó fini lọ́kàn balẹ̀, a sì ní iṣẹ́ tó ṣeyebíye láti ṣe lórí ilẹ̀ tẹ̀mí. Lójú Jèhófà, gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ ló ṣeyebíye bákan náà.

Wọ́n pín in lọ́gbọọgba

Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè kọ̀ọ̀kan nínú Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò jọ máa nípìn-ín nínú ọ̀pọ̀ rẹ̀pẹ̀tẹ̀ ohun rere tó wà nílẹ̀ náà. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, Jèhófà ti fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìbùkún tó dọ́gba nínú párádísè tẹ̀mí.