Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 4A

‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’

‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’

Ó dájú pé Ìsíkíẹ́lì á ti máa rí àwọn ère akọ màlúù àti ti kìnnìún tó rí gìrìwò, tó sì ní orí èèyàn àti ìyẹ́, èyí tí wọ́n máa ń gbé dúró bí ẹ̀ṣọ́ ní ẹnu ọ̀nà ààfin àtàwọn tẹ́ńpìlì. Àwọn ère yìí sábà máa ń wà káàkiri ilẹ̀ Ásíríà àti Babilóníà àtijọ́. Bíi ti àwọn ẹlòmíì tó ń rí àwọn ère yìí, àwọn ẹ̀dá tó rí fàkìàfakia yìí á ti máa ya Ìsíkíẹ́lì lẹ́nu. Àwọn míì tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ogún (20) ẹsẹ̀ bàtà. Síbẹ̀, kò sí bó ṣe lè jọ pé àwọn ẹ̀dá náà lágbára tó, wọn kì í ṣe nǹkan ẹlẹ́mìí, òkúta ni wọ́n fi gbẹ́ wọn.

Àmọ́ “ẹ̀dá alààyè” ni Ìsíkíẹ́lì pe ẹ̀dá mẹ́rin tó rí nínú ìran. Ẹ ò rí i pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí ère tí wọ́n fi òkúta lásánlàsàn gbẹ́! Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó tó ìgbà mọ́kànlá (11) tó mẹ́nu ba “ẹ̀dá alààyè” níbẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Ìsík. 1:​5-22) Ìran ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí wọ́n jọ ń gbéra lẹ́ẹ̀kan náà nísàlẹ̀ ìtẹ́ Jèhófà ti máa gbìn ín sí Ìsíkíẹ́lì lọ́kàn pé gbogbo ìṣẹ̀dá wà níkàáwọ́ Jèhófà. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ìran yẹn máa ń gbìn ín sí wa lọ́kàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba, agbára rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ògo rẹ̀ ò sì láfiwé.​—1 Kíró. 29:11.