ÌTÀN 20
Dínà Kó Sínú Ìjàngbọ̀n
ǸJẸ́ o rí àwọn ẹni tí Dínà ń lọ sọ́dọ̀ wọn? Ó ń lọ sọ́dọ̀ díẹ̀ lára àwọn ọmọbìnrin tó ń gbé ilẹ̀ Kénáánì láti lọ kí wọn. Ǹjẹ́ inú Jékọ́bù bàbá rẹ̀ lè dùn sí èyí? Kó o lè dáhùn ìbéèrè yìí, gbìyànjú láti rántí èrò Ábúráhámù àti Ísákì nípa àwọn obìnrin Kénáánì.
Ǹjẹ́ Ábúráhámù fẹ́ kí Ísákì ọmọ rẹ̀ fẹ́yàwó lára àwọn ọmọbìnrin Kénáánì? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ Ísákì àti Rèbékà fẹ́ kí Jékọ́bù ọmọ wọn fẹ́ ọmọbìnrin Kénáánì? Rárá, wọn ò fẹ́. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?
Ó jẹ́ nítorí pé òrìṣà ni àwọn ará Kénáánì wọ̀nyí máa ń sìn. Wọn kì í ṣe ẹni rere téèyàn lè fi ṣe ọkọ tàbí fi ṣe aya, wọn kì í sì í ṣe ẹni rere téèyàn lè máa bá ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Nítorí náà, ó dá wa lójú pé kò lè dùn mọ́ Jékọ́bù nínú pé ọmọbìnrin òun ń bá àwọn ọmọbìnrin Kénáánì wọ̀nyí ṣe ọ̀rẹ́.
Ó dájú pé inú ìjàngbọ̀n ni Dínà kó sí. Ṣó ò ń wo ọkùnrin ará Kénáánì tó ń wo Dínà nínú àwòrán yẹn? Ṣékémù ni orúkọ ẹ̀. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Dínà wá bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wò, Ṣékémù ki Dínà mọ́lẹ̀ ó sì fi agbára bá a dà pọ̀. Èyí jẹ́ ohun tí ó burú nítorí ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó nìkan ni ó lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ara wọn dà pọ̀. Ìwà búburú tí Ṣékémù hù sí Dínà yìí yọrí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàngbọ̀n mìíràn.
Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n Dínà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí wọ́n gidigidi. Méjì nínú wọn, Síméónì àti Léfì bínú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi mú idà tí wọ́n sì wọ ìlú náà lọ tí wọ́n sì yọ sí àwọn èèyàn náà láìròtẹ́lẹ̀. Àwọn ọkùnrin méjì yìí àti àwọn arákùnrin wọn yòókù pa Ṣékémù àti gbogbo àwọn ọkùnrin tó kù. Inú bí Jékọ́bù nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ hu ìwà búburú yìí.
Báwo ni gbogbo ìjàngbọ̀n yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé Dínà yan àwọn èèyàn tí kì í pá òfin Ọlọ́run mọ́ lọ́rẹ̀ẹ́. Àwa ò ní fẹ́ yan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, àbí?