ÌTÀN 25
Ìdílé Náà Ṣí Lọ sí Íjíbítì
ARA Jósẹ́fù ò gbà á mọ́. Ó sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà nínú yàrá náà pé kí wọ́n jáde. Nígbà tó ku òun àtàwọn arákùnrin rẹ̀, Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. O ò rí i pé èyí á ya àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu gan-an, nítorí wọn ò mọ ìdí tó fi ń sunkún! Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni Jósẹ́fù. Ṣé bàbá mi ṣì ń bẹ láàyè?’
Ẹnu ya àwọn arákùnrin rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ò fi lè sọ̀rọ̀. Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù wí fún wọn pé: ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sún mọ́ mi.’ Nígbà tí wọ́n sún mọ́ ọn, ó wí pé: ‘Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tẹ́ ẹ tà sí Íjíbítì.’
Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í fi àánú bá wọn sọ̀rọ̀ pé: ‘Ẹ má ṣe dá ara yín lẹ́bi pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọ́run gan-an ló rán mi wá sí Íjíbítì láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Fáráò ti fi mí ṣe alákòóso gbogbo orílẹ̀-èdè yìí. Nítorí náà, ẹ tètè wá máa lọ sọ́dọ̀ bàbá mi kẹ́ ẹ sì sọ bẹ́ẹ̀ fún un. Kẹ́ ẹ sì sọ fún un pé kó wá máa gbé níbí.’
Ìgbà náà ni Jósẹ́fù fi ọwọ́ gbá àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ́ra, ó rọ̀ mọ́ wọn lọ́rùn ó sì fi ẹnu ko gbogbo wọn lẹ́nu. Nígbà tí Fáráò gbọ́ pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù dé, ó wí fún Jósẹ́fù pé: ‘Ní kí wọ́n kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin kí wọ́n lọ gbé bàbá wọn àti ìdílé wọn kí wọ́n sì máa bọ̀ níbí. Màá fún wọn ní ilẹ̀ tó dára jù lọ ní gbogbo Íjíbítì.’
Ohun tí wọ́n ṣe gan-an nìyẹn. O lè rí i tí Jósẹ́fù ń kí bàbá rẹ̀ káàbọ̀ nígbà tí òun àti gbogbo ìdílé rẹ̀ dé sí Íjíbítì.
Ìdílé Jékọ́bù ti di ńlá gan-an. Bá a bá ka Jékọ́bù àtàwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ àádọ́rin [70] nígbà tí wọ́n kó wá sí Íjíbítì. Ṣùgbọ́n àwọn aya wọn tún wà níbẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó ní ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ pẹ̀lú. Gbogbo wọn ló tẹ̀ dó sí Íjíbítì. A máa ń pè wọ́n ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí Ọlọ́run ti yí orúkọ Jékọ́bù padà sí Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di èèyàn pàtàkì fún Ọlọ́run, bá a ṣe máa rí bó bá yá.