Ìtàn 42
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kan Sọ̀rọ̀
ǸJẸ́ o ti gbọ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ̀rọ̀ rí? O lè sọ pé o ò gbọ́ ọ rí. Àwọn ẹranko ò lè sọ̀rọ̀.’ Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ nípa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tó sọ̀rọ̀. Jẹ́ ká gbọ́ bó ṣe ṣẹlẹ̀.
Ó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì. Bálákì, ọba Móábù ń bẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ló bá ránṣẹ́ sí ọkùnrin kan tó gbọ́n féfé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Báláámù láti wá ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bálákì ṣèlérí pé òun á fún Báláámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, nítorí náà, Báláámù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì forí lé ọ̀dọ̀ Bálákì.
Jèhófà kò fẹ́ kí Báláámù ṣépè fáwọn èèyàn Òun. Nítorí náà, ó rán áńgẹ́lì kan pẹ̀lú idà gígùn lọ́wọ́ pé kó lọ dúró sójú ọ̀nà láti dá Báláámù dúró. Báláámù ò rí áńgẹ́lì náà, ṣùgbọ́n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ rí i. Nítorí náà, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti yàgò fún áńgẹ́lì náà, nígbà tó sì yá, ló bá kúkú dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà. Inú bí Báláámù gidigidi, ló bá kó ọ̀pá bo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
Ni Jèhófà bá mú kí Báláámù gbọ́ tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà béèrè pé: ‘Kí ni mo ṣe fún ọ tó o fi ń lù mí?’
Báláámù fèsì pé: ‘O ti jẹ́ kí n dà bí òmùgọ̀. Tí idà bá wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá pa ọ́ ni!’
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo ti ṣe báyìí sí ọ rí bí?’
Báláámù dáhùn pé: ‘Rárá.’
Ìgbà náà ni Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ wá jẹ́ kí Báláámù rí áńgẹ́lì tó mú idà dání tó dúró sójú ọ̀nà. Áńgẹ́lì náà wí pé: ‘Kí ló dé tó o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ? Mo wá láti dí ọ lọ́nà ni, nítorí pé kò yẹ kó o lọ ṣépè fún Ísírẹ́lì. Bí kì í bá ṣe pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yàgò fún mi ni, èmi ì bá ti ṣá ọ pa tí mi ò sì ní fọwọ́ kan kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ.’
Báláámù sọ pé: ‘Mo ti ṣẹ̀. Èmi ò mọ̀ pé ìwọ lo dúró sójú ọ̀nà.’ Áńgẹ́lì náà jẹ́ kí Báláámù kọjá, Báláámù sì lọ rí Bálákì. Síbẹ̀, ó gbìyànjú láti ṣépè fún Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n, ìgbà mẹ́ta ni Jèhófà jẹ́ kó súre fún Ísírẹ́lì.