Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 40

Mósè Lu Àpáta

Mósè Lu Àpáta

ỌDÚN ń gorí ọdún. Ọdún mẹ́wàá kọjá, ogún ọdún kọjá, ọgbọ̀n ọdún kọjá, ọdún mọ́kàndínlógójì kọjá! Síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì wà nínú aginjù. Ṣùgbọ́n ní gbogbo ọdún wọ̀nyí, Jèhófà ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. Ó ń fi mánà bọ́ wọn. Ó ń fi ọwọ̀n ìkùukùu ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán, àti ọwọ̀n iná ní òru. Ní gbogbo ọdún wọ̀nyí sì rèé, aṣọ wọn ò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ ò dùn wọ́n.

Oṣù kìíní nínú ogójì ọdún tí wọ́n ti fi Íjíbítì sílẹ̀ ni wọ́n wà yìí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún pàgọ́ sí Kádéṣì. Ibí yìí ni wọ́n wà nígbà tí Mósè rán àwọn amí méjìlá náà jáde lọ sí ilẹ̀ Kénáánì ní ìwọ̀n ogójì ọdún sẹ́yìn. Kádéṣì yìí ni Míríámù arábìnrin Mósè kú sí. Bíi ti tẹ́lẹ̀, ìjàngbọ̀n tún ṣẹlẹ̀ ní ibí yìí.

Àwọn èèyàn náà kò rí omi mu. Nítorí náà wọ́n ráhùn sí Mósè pé: ‘Ì bá sàn ká lá a ti kú. Kí ló dé tó o fi mú wa kúrò ní Íjíbítì wá sí ibi burúkú tí nǹkan kan ò ti lè hù yìí? Kò sí ọkà, kò sí ọ̀pọ̀tọ́, kò sí èso àjàrà, kò sí pómégíránétì. A ò tiẹ̀ rí omi mu pàápàá.’

Nígbà tí Mósè àti Áárónì lọ sínú àgọ́ ìjọsìn láti gbàdúrà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Kó àwọn èèyàn náà jọ pọ̀. Wá sọ̀rọ̀ sí àpáta tó wà lọ́hùn-ún yẹn lójú gbogbo wọn. Omi púpọ̀ yóò tú jáde láti inú rẹ̀ wá fún àwọn èèyàn náà àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn láti mu.’

Nítorí náà, Mósè kó àwọn èèyàn náà jọ, ó sì wí pé: ‘Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run! Ṣé kí èmi àti Áárónì mú omi jáde wá láti inú àpáta yìí fún yín ni?’ Ni Mósè bá fi ọ̀pá lu àpáta náà ní ìgbà méjì, ibú omi sì bẹ̀rẹ̀ sí í tú jáde láti inú àpáta náà. Omi tó pọ̀ tó wà fún gbogbo àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn wọn láti mu.

Ṣùgbọ́n Jèhófà bínú sí Mósè àti Áárónì. Ǹjẹ́ o mọ̀dí rẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé Mósè àti Áárónì sọ pé àwọn ni yóò mú omi jáde wá láti inú àpáta. Nígbà tó sì jẹ́ pé Jèhófà gan-an ló ṣe é. Nítorí pé Mósè àti Áárónì kò sì sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, Jèhófà sọ pé òun á fi ìyà jẹ wọ́n. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ò ní sin àwọn èèyàn mi wọ ilẹ̀ Kénáánì.’

Láìpẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Kádéṣì. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ wọ́n dé Òkè Hórì. Ní orí òkè yìí ni Áárónì kú sí. Ó jẹ́ ẹni ọgọ́fà lé mẹ́tà [123] ọdún nígbà tó kú. Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bà jẹ́ gidigidi, nítorí èyí, odidi ọgbọ̀n [30] ọjọ́ ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sunkún nítorí Áárónì. Élíásárì ọmọ rẹ̀ ló di àlùfáà àgbà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́yìn rẹ̀.